Home / Àṣà Oòduà / Ààrẹ Buhari dijú lé Ọ̀gá Àjọ NECO àti àwọn mẹ́rin mìíràn tó jàjẹbánu

Ààrẹ Buhari dijú lé Ọ̀gá Àjọ NECO àti àwọn mẹ́rin mìíràn tó jàjẹbánu

Ààrẹ Buhari dijú lé Ọ̀gá Àjọ NECO àti àwọn mẹ́rin mìíràn tó jàjẹbánu

Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari ti fi ọwọ́ òṣì júwe ilé fún adarí àjọ elétò ìdánwò àṣekágbá ti girama, NECO àti àwọn mẹ́rin mìíràn lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ṣe màgòmágó.

Nínú àtẹjáde tí Ààrẹ Buhari fi léde ló ti ní Ọjọ́gbọn Charles Uwakwe, Bamidele Olure, Shina Adetona, Tayo Odukoya àti Babatunde Aina ni wọ́n ti kọkọ fún ní ìwé lọ gbélé rẹ fún ìgbà díẹ̀ kí wọ́n fi ṣe ìwádìí fínífíní ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu tí wọ́n fi kàn wọ́n.

Wọ́n ní Uwakwe jẹ̀bi ẹ̀sùn lílo owó àjọ náà básubàsu gẹ́gẹ́ bí òfin àjọ náà ti ọdún 2007 sẹ tako ìwà àjẹbánu bẹ́ẹ̀.
Ààrẹ wá késí i láti dá gbogbo ẹrù Ìjọba tó wà ní ọwọ́ rẹ̀ padà fún adelé darí àjọ náà tó wà níbẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Bákan náà nínú àtẹjáde ọ̀hún ni wọ́n sọ pé Arákùnrin Bamidele Olure tó jẹ́ adarí ẹ̀ka ìṣúná ní àjọ NECO ló jẹ̀bi ẹ̀sùn ṣíṣe owó àjọ náà tó wà ní ìkáwọ́ rẹ básubàsu, tí kò sì yẹ ní adarí ẹ̀ka náà mọ́.

Ọ̀mọ̀wé Dókítà, Shina Adetona ni wọ́n fẹsun kàn ní tirẹ̀ pé ó ṣe jibiti, tó sì ṣe màgòmágó pẹ̀lú àkọsílẹ̀ àwọn òṣìṣẹ́.

Tayo Odukoya ní wọ́n lé nítorí òun náà ṣẹ màgòmágó tó tako òfin àjọ náà, nígbà tí wọ́n sì lé agbẹjọ́rò Babatunde Aina nítorí ó yí àkọsílẹ̀ ‘pàdé, tí ó sì ṣe màgòmágó nípa títa ilé ìgbé àjọ náà.
Bákan náà ni Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́, Mallam Adamu Adamu wá pàṣẹ fún àwọn adarí àjọ náà láti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti gba gbogbo owó tí wọ́n fi ọ̀nà èrú gbà padà lọ́wọ́ wọn.

Tí a kò bá gbàgbé, Ọjọ́ Kẹwàá, Oṣù Karùn ún ọdún 2018 ni Ìjọba kọ ìwé lọ gbé ilé rẹ fún ìgbà díẹ̀ sí Ọ̀jọ̀gbọ́n Uwakwe fún ìwádìí ẹ̀sùn jẹgúdújẹrá tí wọ́n fi kàn án àti àwọn meji míràn.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

IGP usman

Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá Ìròyìn òkèrè, bí ò lé, a dín.Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣàlàyé bí ìdigunjalè kan tí ìròyìn sọ pé ó gba ẹ̀mí èèyàn kan ṣe wáyé ní ọjà Bódìjà nílùú Ìbàdàn. Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Adéwálé Òṣífẹ̀sọ̀, sọ nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún pé lọ́jọ́ ẹtì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Ó ní arákùnrin kan, Abubakar Ibrahim, ni àwọn adigunjalè kọlù ní nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n sì yìnbọn mọ́ ọ kí wọ́n ...