Home / Àṣà Oòduà / O̩ló̩run sì máa gbè̩san ikú bàbá mi – O̩mo̩ o̩ko̩ olóyún

O̩ló̩run sì máa gbè̩san ikú bàbá mi – O̩mo̩ o̩ko̩ olóyún

Olorun si maa gbesan iku baba mi – Omo ojo Oloyun
Ojo ketalelogun osu kin-in-ni odun yii ni awon adiha-Moran kan lo yinbon pa Alhaji Fatai Yusuf ti gbogbo eniyan mo si oko oloyun.


Lati igba naa ni awon olopaa ti n se iwadii awon to se ise ibi naa.
Akoroyin iwe iroyin PUNCH lo se alabapade Kehinde Yusuf to je omo oloogbe naa.

Kehinde soro ile kun, o ni ju gbogbo re lo, o da oun loju to ada pe Eledua si maa gbesan iku baba oun lara awon eniyan buruku naa.


O ni baba oun ko ki n ba eniyan ja bee ni ko ki n ba eniyan ta. O ni jeje ni baba yii maa n lo, ti o si maa n mura si bi okowo re se maa gberu sii.
Kehinde ni oun gege bi omo Naijiria ko reti abajade lodo awon olopaa sugbon oun ni igbagbo ninu Olorun.

O tun ni ebi oun gan-an ko gbe awon to pa baba naa sokan bi ko se bi awon se maa te siwaju. Bi awon se maa rii pe eto eko oun ati awon aburo oun ko duro nitori pe awon po die.


O ni ko rorun fun mama oun nikan lati to ono mewaa sugbon awon ni igbagbo ninu Olorun. O ni ipade lorisirisii ti n lo lati le foju to gbogbo idasile baba oun naa. O ni awon ko fe ki okankan parun rara.


O ni ara eko ti baba awon fi ko awon ni ki awon tepa mose nitori pe atelewo eni ko ki n tan ni je. O ni baba naa ni ki awon tun sun mo Olorun, ki awon maa ke pee ni gbogbo igba.


Kehinde ni ko si eni ti iku baba naa ko dun ninu ebi oun, o kan je wi pe o dun oun gan-an ni nitori pe oun ni oun di eru baba naa ti oun si gbe si inu moto won, o ni sadede ni iroyin buruku naa kan oun lara ni ojo keji pe won ti yinbon pa baba naa.

O ni bi ala lo ko ri ki awon ipe to maa wole lorisiirisii ti awon eniyan si tun bere si ni wo wa si ile awon.


Kehinde ni eyi je ki o pe die ki oun to le pada si ile-iwe nitori pe oun kan sare wale ni ireti ati pada kiakia ki isele naa to sele.

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo