Home / Àṣà Oòduà / Owonrisogbe – Ifá Naa Ki Bayi Wipe: Biijo biijo…

Owonrisogbe – Ifá Naa Ki Bayi Wipe: Biijo biijo…

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, a si tun ku orire osu Ògún tuntun to bawa layo ati alaafia, osu naa yio sanwa sowo, somo, sile kiko, moto rira, ire oko/aya ati aiku baale oro yio je tiwa, Ògún lákayé yio lana funwa o Àse.


E jeki a fi odù mímó Owonrisogbe you se ìwúre ibere osu yi.
Ifá naa ki bayi wipe:
Biijo biijo
Biayo biayo a difa fun agbado lojo ti nroko alere odun, won ni ko karale ebo ni ki o wa se nitori ki o baa le ko ire bo wa sile, obi meji, eru eko, eru akara, igbin, irukere, obuko ati igba ewe ayajo ifa, agbado kabomora o rubo won si se sise ifa fun nigbati agbado doko aloro odun won fi fole nigbati o maa di ojo karun agbado bere sini nwu Omi igbin to fi rubo lojo kini ana esu odara nto Omi naa sidi agbado, agbado wa dagba o yomo irukere to tun fi rubo lojo kini ana esu odara fi le Omo agbado lowo, awon Omo agbado dagba won dogbo won si tobi daradara inu agbado dun o wa njo o nyo o nyin awo awon awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifa wa bami ni jebutu ire nje jebutu ire ni a nba awo lese obarisa, o wa fiyere ohun bonu wipe; nje kini agbado mu toko bo? Igba Omo lagbado mu toko bo igba omo, kini agbado tun mu toko bo? Igba aso lagbado mu toko bo igba aso.


Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi ati ninu osu tuntun yi wipe oro ayo ati idunnu yio je tiwa, ako ni ri oro ibanuje igbesi aye wa yio so eso rere, gbogbo adawole wa yio yori si rere ninu osu yi, ao ni ayo ayeraye aaaseee.
ÀBORÚ ÀBOYÈ OOO.

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo