Home / Àṣà Oòduà / Ṣàgbẹ̀lójú yòyò, ni ọ̀pọ̀ àwọn òṣèré…. òjòpagogo

Ṣàgbẹ̀lójú yòyò, ni ọ̀pọ̀ àwọn òṣèré…. òjòpagogo

Ṣàgbẹ̀lójú yòyò, ni ọ̀pọ̀ àwọn òṣèré…. òjòpagogo

Fẹ́mi Akínṣọlá

Awọn agba bọ,wọn ni purọ n niyi,ẹwu ẹtẹ nii da bolowo ẹ lọrun lo mu
gbajugbaja agba ọjẹ oṣere Yoruba, Razak Ọlayiwọla ti gbogbo eeyan mọ si Ojopagogo bi o se sọrọ lori ohun to n ṣẹlẹ laarin awọn oṣere Yoruba.
O pabi ,o yabidun ọrọ lori awọn oṣere Yoruba ti wọn n gbe ara wọn sori ayelujara ati awọn to n gberaawọn gẹṣin aayan peraawọn ni n ti wọn ko jẹ .
Ojopagogo ni ere ṣiṣe a maa parọ mọ eeyan ni oju aye.
O ni awọn ipa olowo ti awọn n ko ninu ere ko sọ pe olowo ni awọn oṣere tiata loju aye.
AbdulaRazak ni ko si ohun to buru lati gbe oore Ọlọ́run sojutaye ṣugbọn, iwọntunwọnsi ni gbogbo nnkan.
O pakiyesi awọn eeyan si igbe aye awọn agba oṣere bii Ogunde, Baba Salah atawọn eekan mii,pe wọn kii fẹkọ tana fawọn eeyan.
Agba oṣere yii ko sai gba awọn oṣere to ku nimọran lati ṣe jẹjẹ nitori piparọ lori ayelujara kii jẹ ki eeyan ri alaanu.
O ni ki awọn ọdọ iwoyi ṣe pẹlẹ pẹlẹ, ki wọn ma ba a sare mọto kọlu kẹkẹ boruko ẹbi i wọn jẹ.

About ayangalu

x

Check Also

Orun Ire Ooooo

ERIN WOOOOOOO. Iku da Oro iku shei’ika, Iku mu eni rere lo.