Home / Àṣà Oòduà / Akara Alison-Madueke tu sepo raurau

Akara Alison-Madueke tu sepo raurau

Alison-Madueke
*O ko sowo olopaa nibi o ti fe fi owo eru ra ile ni London.
*Ile ejo gbe ese le owo re mole
*Iya re naa ti foju ba ile ejo.
*Agbejoro re kede wi pe o ni arun jejere
Sebi awon Yoruba lo ni bina o tan laso, eje ki i tan leekanna. Leyin ti awon agbofinro ti won on ri si iwa odaran niluu London se gbe minisita epo robi nigba kan ri, Diezani Alison-Madueke lojo Eti to koja loun (2/10/15).

Ti awon ajo EFCC naa si tun rolu ile re to kale si Asokoro ni ilu Abuja lati gbe agadagodo nla gbangba senu ona ile naa, iroyin mi-in tun ti seyo.

Gege bi a se gbo, awon osise ti won gbogun ti iwa odaran niluu London, National Crime Agency ti fi sita wi pe ati odun 2013 ni awon ti n dode Madueke latari awon owo ilu kan to se basubasu.
Isele yii dabi oro konko: Konko ni ti won ba gbe iyawo tuntun oun ki i lo be lo woran.

O ni tori wi pe oun mo pe bopeboya, iyawo tuntun n bo wa ponmi lodo. Koda, o tun le bora sile fohun nihoho nigba o ba fe bomi lura.

Alison-Madueke ko si panpe nigba ti n gbiyanju lati ra ile ti owo re n lo bi nnkan bi milionu mejila aabo owo poun ile Biritiko (12.5m pounds).

Igba ti won on dunadura, won ko fuu lara rara titi ti Alison-Madueke fi setan lati sanwo ile naa.

Lara akojopo Iwe Iroyin Owuro tun ni wi pe ki i se Madueke nikan lo fi ika abamo senu, okan lara awon oga ile ise epo robi kan naa jeun japo saya.

Eleyii ti owo te oun ati oga re, Madueke nibi won ti n gbiyanju ati ra ile agbaayanu, awosigele, awodamienu kan niluu London.

Awon osise eka ile ise ile Biritiko ti won gbogun ti iwa odaran so wi pe ohun to ta awon nidi kan ko ju nipa owo tabua ti madaamu naa setan lati daale leekan soso fun rira ile naa pa patapata.

Won ni yoo soro fun osise ijoba kan lasan lati ko obitibiti owo poun to po to yun-un kale la se wi pe o fi jibiti kun ise ilu ti won gbe le e lowo.

Lori gbajugbaja ikanni ayelukara www.lindaikejisblog, aimoye awon omo Naijeria jakejado agbaye ni won fi ero won han nipa iriwise abe atejade iroyin to ni i se pelu bi won se gbe Alison Madueke niluu London latari esun jegudujera.

Die lara ero awon eniyan ni yii:

RoyalPristhood: Titi di igba ti ile ejo yoo fi dawon lebi, a ko le ti gba wi pe odaran ni won. Mo gba adura wi pe ori iya won yoo ko won yo ninu fitinati ti won ko si.

Karisson: Ariwo enu lasan leyii. Ubanagun [ede yibo].

Ngene Olivia: E dakun, e je ki won maa tesiwaju lati maa gbe gbogbo won, gbogbo awon odaran pata.

#GbogboNnkanYooPadaDara #OpeLoMaJasi

Olumide David: Eleyii tun pamilerin, bawo ni etaworo awon eniyan kan se ja gbogbo ilu lole ni aimoye owo bi eleyii?

Abdulhammed Idris: Ope pataki lowo Aare Muhammadu Buhari.
Mo tun ni igbagbo sii ninu isejoba re pelu bo se sangi mo Madueke lori. Bawo ni o ba se dun to ko je wi pe idajo iku ni won se fun-un.

Dayo Adetunji: Eleyii dara pupo. Sugbon ko ba san ti ijoba Naijiria ba le maa mu awon asebaje naa nigba ti won ba wa lori erupe ile Naijiria yato si igba ti won ba wa loke okun.
Nitori ati da awon asebaje naa wale pada lati wa koju ina iya ese won maa n pe die.

Lara asiri to tun tu jade ni wi pe aimoye owo ni Madueke ko pamo si aimoye banki orisiirisii kaakiri ni oruko awon ebi ati ojulumo re.

Sugbon gege bi oro awon Yoruba, won ni aaya gbon Ogungbe gbon. Aaya n tiro, Ogungbe n bere ni a le fi we oro Madueke ati eka ti n gbogun ti iwa odaran ile Biritiko.

Eleyii lo fa bi iya to bi Diezani Alison-Madueke, iyen arabirin Beatrice Agama ati arabirin kan ti oruko re n je Melanie Spencer se foju ba ile ejo Majisireeti Westminster to wa ni opopona Marylebone niluu London lojo Aje to koja, ojo karun-un osu kewaa odun taa wa yii lori esun awon owo kan to boha mo won lowo.

Loju ese naa tun ni ile ejo tun pase gbigbesele egberun metadinlogbon owo poun (27, 000 pounds) kan to tun je ti Madueke.

Ni bayii, ogbeni kan ti oruko re n je Kola Aluko ni oruko re tun ti lefo bi kete ti won fi lori omi ninu iwadii awon olopaa ilu London. Aluko to je onisowo epo robi, okan ninu awon agbodegba Madueke ti won ba dabaru awon owo ijoba to ji ko ki asiri re le bo loju omo araye.

Aimyo dukia ni okunrin naa ti fi awon owo naa de mole ni ilu London ati Switzerland eleyii ti asiri gbogbo re ti bere si ni foju han lode. Sebi ti iro ba lo logun odun, ojo kan soso ni otito yoo ba.

Wayio, awon ebi Arabirin Alison-Madueke ti n fara ki bakan naa ni won tun koro oju si awon iroyin to jade nipa bi awon olopaa se gbe Madueke niluu London. Won ni awon olopaa o gbe Madueke, n se ni won fiwe pe lati dahun awon ibeere kan.

A ti wi pe oju ese naa ni won ni ko pada sile lati lo ma jaye ori re.

Ogbeni Oscar Onwudiwe to je agbajero Madueke naa ti bee si n pariwo kiri bayii wi pe, onibara oun ni aisan jejere. A ti wi pe o ni awon itoju kan to n gba lowo ni ile iwosan.

Eleyii ko si ni boju mu ti won ba n fitinati emi re lori awon esun ti ko lese n le lati fida alaafia re laamu.

Ojo to n ro ti ko ti da ni esun jegudujera, sise owo ilu mokumoku ati riba gbigba ti won fi kan Alison-Madueke, Edua oke nikan lo moye eni ti o pa.
Orisun

About oodua

One comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Diezani Alison-Madueke Wo gau! Madaamu Naa Setan Ti O Foju Bale Ejo

Owo awon olopaa ilu London ti te Diezani Alison-Madueke to je minisita fun epo robi nigbakan labe isejoba Goodluck Jonathan. Alison-Madueke ati awon merin kan ni owo te laaro ojo Eti to koja yii pelu esun Jegudujera, riba ati sise owo ilu mokumoku. Ogbeni Joseph Abuku to je alukoro fun ile ise asoju ijoba ile Biritiko ni ile Naijeria jeri si i wi pe lotito ni awon agbofinro ilu London ti gbe awon eniyan marun-un kan ti won je omo ...