Home / Àṣà Oòduà / Ẹlẹ́wọ̀n 2600 ni ìjọba tú sílẹ̀ ní Nàìjíríà nítorí àrùn apinni léèmí Coronavirus

Ẹlẹ́wọ̀n 2600 ni ìjọba tú sílẹ̀ ní Nàìjíríà nítorí àrùn apinni léèmí Coronavirus

Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti tú ẹlẹ́wọ́n tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì sílẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Aregbesọla ní Ìjọba gbé ìgbésẹ̀ náà láti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ àrùn Coronavirus ní Nàìjíríà.

Mínísítà fún ọ̀rọ̀ abẹ́lé lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà náà ni àwọn tí yóó jẹ àǹfààní ìtúsílẹ̀ yìí ni àwọn ẹni tó bá ti kọjá ọgọ́ta ọdún, àwọn aláìsàn , àwọn tó ní àrùn ọpọlọ àti àwọn tó sẹ ẹ̀sẹ̀ kéékèké.

Mínísítà fún ọ̀rọ̀ abẹ́lé lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Rauf Aregbesola ló kéde rẹ̀ ní ibi ayẹyẹ tí wọ́n ti ṣe ìtúsílẹ̀ náà.

About ayangalu

x

Check Also

Orun Ire Ooooo

ERIN WOOOOOOO. Iku da Oro iku shei’ika, Iku mu eni rere lo.