Home / Àṣà Oòduà / Òkan lára Ilé ìgbé àwon akékòó ti Ilé-èkó gíga ifáfitì ti ìlú ilé-ifè tí a mò sí Obafemi Awolowo University gbiná lánàá.

Òkan lára Ilé ìgbé àwon akékòó ti Ilé-èkó gíga ifáfitì ti ìlú ilé-ifè tí a mò sí Obafemi Awolowo University gbiná lánàá.

Òkan lára ilé ìgbé àwon Akékòó ti ilé-èkó gíga ifafitì ti Obafemi Awolowo gbiná ní alé àná. Ilé ìgbé yìí a máa jé Alumni hostel, bí ó ti lè je wípé a kò fi tara tara mo bí ó se selè.
Gégé bí a se gbó, èrònjà tí a fi n dáná tí a mò sí gáàsì ti ó gbiná tí ó sì fa làásìgbò tí ó selè yí, ìròyìn jé kí á mò wípé yàrá bíi mérin ni ó gbinà látàrí àígboràn.
Won jé kí á mò wípé, gáàsì yí tí máa n rùn jáde télè kí ó tó di ojó náà, won sì ti máa n kìlò fún Akékòó tí ó ni gáàsì yí télè sùgbón tí ó kò láti gbó ìkìlò.
A tún ri gbó wípé, Yárá méta òtòtò ni ó gbiná sùgbón eni kankan kò kú níbè. Kí Elédúmarè máa fi ìsó rè só wa ooo.

About Awo

x

Check Also

Orun Ire Ooooo

ERIN WOOOOOOO. Iku da Oro iku shei’ika, Iku mu eni rere lo.