Home / Àṣà Oòduà / A kú òsè jàkúta.

A kú òsè jàkúta.

Sango oooo
Olukoso ayanran ina
Ina loju, ina lenu
Sangiri, lagiri
Olagiripapa figba edun bo
Eefin ina la n da laye
Ina nbe lodo oko mi lorun
Abaabe ooooooooo
Abaabe laba Se fun SANGO
Emi Se SANGO labaabe
Agbenajo, Agbenayan
Agbenarababa kari bi Olodumare
Imumuna eledumare itara ni gbaye
Alaramoka ti I deru bojo
Aduloju, Adulenu
Ajo lagbon isale woiwoi
Kee wolu baale ndifa
SANGO koti wolu
Timo fi n gbo bata leyin Odi
SANGO gbemi, ewe gbemi
Awalawulu,ogbojo aseru bote
Akinkanju Akoni ti yona lenu

Kaabiyesi Olukoso!
Kaabiyesi Olukoso!!
Kaabiyesi Olukoso!!!

A kú òsè jàkúta

About Awo

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo