Home / Àṣà Oòduà / Awon akekoo LASU yari, won ni awon alase n ko leta si yanponyanrin

Awon akekoo LASU yari, won ni awon alase n ko leta si yanponyanrin

Lati Ọwọ Olayemi Olatilewa
Awon omo egbe akekoo Ifafiti tilu Eko, Lagos State University Students Union (LASUSU) ti bere si ni fariga pelu ifehonuhan latari bi awon alase ileewe naa se fi owo kun owo igbaniwole awon akekoo tuntun.

Ifehonuhan naa lo buruke lojo Isegun to koja yii nigba ti awon akekoo ni ki awon alase da owo igbaniwole (acceptance fee) pada si egberun mewaa naira (10, 000) to ti wa tele yato si egberun lona ogun naira (20, 000) ti awon alase ni ki awon akekoo tuntun ti won ba fe wole maa san bayii.

Alaga egbe akekoo ti ileewe naa,LASUSU, Ogbeni Adeyemi Onikoro so wi pe ki awon alase yaa tete se bi awon se wi nipa dida owo naa pada si bo se wa tele ti won ko ba fe ki ijangbon, surutu, ruke-rudo, yanponyarin o be sile ninu ogba ile iwe naa.

“Iru aba yii ni awon alase Ifafiti Obafemi Awolowo ti Ile-Ife da ni awon igba kan seyin eleyii to pada yori si wahala nla ti ileewe naa fi di titipa fun osu mefa gbako.

“A ko fe ki iru eleyii sele ni LASU lo mu wa maa fi ohun tutu pelu oro tutu ke si awon alase toro kan bayii wi pe ki won se ohun to ye. Gbogbo ogbon to wu ti won le da lati fi kun owo naa ni yoo pada yori si wahala nla”, alaga egbe akekoo lo so bee.

Gege bi afikun Alaga, o ni N10,000 lowo igbaniwole fun akekoo tuntun nigba ti owo ileewa je N25,000. O ni awon akekoo ti won ti wa nile iwe tele yoo si maa san N25,000 nikan.

“Eleyii tunmo si wi pe akekoo tuntun yoo maa san egberun marunlelogbon owo naira gege bi apapo owo ni sisan,” alaga se lalaye bee.

Gbogbo ilakaka Olayemi Oniroyin lati ba Olugbaniwole si ile iwe naa, Ogbeni
Akin Lewis ati oga agba ti n risi awon oro to jemo ti akekoo, Dean of Students Affairs, Prof. Kabir Akinyemi, lo ja si pabo.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo