Home / Àṣà Oòduà / “Bilionu lona bilionu owo naira ni Mimiko dabaru ni ipinle Ondo” – Alagba egbe APC

“Bilionu lona bilionu owo naira ni Mimiko dabaru ni ipinle Ondo” – Alagba egbe APC

Olayemi Olatilewa

Alaga egbe oselu APC eka ti ipinle Ondo, ogbeni Isaac Kekemeke ti fesun kan Gomina Olusegun Mimiko to je omo egbe oselu PDP nipa wi pe owo bi tirilionu kan naira (N1 trillion) ni gomina ti je mole lati nnkan bi odun mefa wa si akoko taa wayii.
Oro yii ni Siamaanu yii n so fun awon oniroyin nibi ipade idanileko kan eleyii ti awon obirin egbe oselu APC gbe kale niluu Akure. O ni Mimiko n fi ara ni awon ara ilu nipa awon owo ori kan-anpa to gbe le awon omo ipinle Ondo lori. ” Gbogbo bo se n lo lo ye wa. Gomina n fi ara ni awon eniyan nipa awon owo ori dandangbon eleyii ti won on gba lati fi di awon owo ilu ti won ti ko je seyin. Sugbon sa, o seni laanu wi pe ipinle Ondo ni ijoba eleyii to n so awon eniyan di akuse lojoojumo”.

Ogbeni Kekemeke ko sai tenu moo wi pe gbogbo eto ti to fun egbe APC lati gba ijoba ipinle naa pada lodun to n bo. Bakan naa lo tun fi kun un wi pe awon eto ijoba Mimiko to pokurumusu yoo tun je anfaani fun egbe awon lati rona gba koja.

Ninu eto idibo awon omo ile igbimo asofin ipinle naa to koja, Ogbeni Kekemeke so wi pe ohun to fa ijakule fun egbe APC ko ju bi asiri ilana ati eto awon se tu si egbe oselu PDP lowo saaju ki eto idibo naa to waye.  Ati wi pe makaruru po ninu eto idibo naa eleyii to fun egbe PDP laye je.

Bakan naa lo tun fi kun-un wi pe eto ti to fun egbe APC lati dibo abele nibi ti won yoo ti mo taani yoo soju egbe naa ninu eto idibo gomina ti o waye lodun to n bo.  O si salaye wi pe eto idibo naa yoo je eyi ti o gunle ofin ati ilana egbe onigbale lai figba kan bokan ninu.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo