Home / Àṣà Oòduà / Ẹ kéde iye ọlọ́pàá tó gba rìbá, kí ẹ tó má a yin ra a yín… Aráàlú sọ fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Ẹ kéde iye ọlọ́pàá tó gba rìbá, kí ẹ tó má a yin ra a yín… Aráàlú sọ fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Ẹ kéde iye ọlọ́pàá tó gba rìbá, kí ẹ tó má a yin ra a yín… Aráàlú sọ fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Èsì àwọn ọmọ Nàìjíríà tó tẹ̀lé bí iléèṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe yin ara rẹ̀
Lórí káàdì tí wọ́n fi síta lójú òpó ayélujára Twitter wọn, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ pé káàdì náà jẹ́ àfihàn àkójọpọ̀ àwọn àṣeyọrí wọn láàrin ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Kínní, ọdún 2019 sí ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Kínní, ọdún 2020.

Wọ́n tọ́ka sí àwọn ‘ẹ̀ka’ bí àwọn afurasí, ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkuǹkùn, tí ọwọ́ tẹ̀, tó fi mọ́ iye ọkọ̀ tí wọ́n jígbé, ṣùgbọ́n tí ọlọ́pàá gbà padà, àwọn afurasí ajínigbé àti adigunjalè, tó fi mọ́ iye nǹkan ìjà olóró tí wọ́n rí gbà.

Ṣùgbọ́n ṣá, bí àwọn ọmọ Nàìjíríà kan ṣe ń gbóríyìn fún àwọn ọlọ́pàá ni àwọn kan ń sọ pé àwọn ọmọ Nàìjíríà ló yẹ kó fi irú káàdì ìgbéléwọ̀n náà síta, kìí ṣe iléeṣẹ́ ọlọ́pàá.

Bákan náà ni àwọn kan tún ń sọ, paàpá lábẹ́ Ìkéde iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ọ̀hún pé, ó yẹ kí wọ́n ó kọ iye àṣìta ìbọn ọlọ́pàá tó pa aráàlú, rìbá gbígbà, iye àwọn ọ̀dọ́ tí ọlọ́pàá fìyà jẹ lọ́nà àìtọ́, àti àwọn ẹ̀sùn mìíràn tí aráàlú fi ń kàn àwọn ọlọ́pàá sí orí káàdì náà.

Yàtọ̀ sí èyí, àwọn kan sọ pé ó yẹ kí wọ́n kọ iye afurasí tí ọ̀rọ̀ wọn wà nílé ẹjọ́, àti àwọn tó ti gba ìdájọ́ s’órí káàdì ìgbéléwọ̀n náà.

Àwọn kan tilẹ̀ sọ pé kò dára bí wọ́n ṣe gbé káàdì ìgbéléwọ̀n náà, tó ṣàfíhàn ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù Kínní, ọdún 2019 sí ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù Kínní, ọdún 2020, jáde ní ọjọ́ kẹsàn án, oṣù Kínní, 2020.

Títí di àkókò yìí, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kò tíì f’èsì sí ìkankan.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo