Home / Àṣà Oòduà / Ewi Toni: Toju Iwa Re Ore Mi 

Ewi Toni: Toju Iwa Re Ore Mi 

Toju iwa re, ore mi;
Ola a ma si lo n’ile eni,
Ewa a si ma si l’ara enia,
Olowo oni ‘nd’olosi b’o d’ola.
Okun l’ola; okun n’igbi oro,
Gbogbo won l’o nsi lo n’ile eni;
Sugbon iwa ni m’ba ni de sare’e.
Owo ko je nkan fun ni,
Iwa l’ewa omo enia.
Bi o l’owo bi o ko ni’wa nko?
Tani je f’inu tan e ba s’ohun rere?
Tabi ki o je obirin rogbodo;
Ti o ba jina si’wa ti eda nfe,
Tani je fe o s’ile bi aya?
Tabi ki o je onijibiti enia;
Bi o tile mo iwe amodaju,
Tani je gbe’se aje fun o se?
Toju Iwa re, ore mi,
Iwa ko si, eko d’egbe;
Gbogbo aiye ni ‘nfe ‘ni t’o je rere.
(ENGLISH TRANSLATION)
(ENHANCE YOUR CHARACTER MY FRIEND)
 Continue after the page break

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

ifa

Kùtùkùtù Ìrèní Laó He Erè Nígbódù Oòni

Òní laó roko létí opónÒla laó sákà lágbèrùKùtùkùtù ìrèní laó he erè nígbódù oòniKáyáa múlé pontíKámú òdèdè rokàKáfi agbada dínranÀwèje wèmu nípón omodé wòyí lójúÒrìsà lópabuké tánLódákún sábaro nídìíOmo-ojo húnsáré gíríjo-gíríjoOmo-ojo húnsáré gìrìjo-gìrìjoIlé-ifón kògba obàtáláÈlàgboro kògba òrìsàOjúgboro ni tàfínÈlàgboro ni tòrìsàOmi níti ojú-omi rúwáÈròyà wáàponÈròyà wáàmuRúkú-rùkù-rúkú niwón nse lókè ohùnkòErú kùnrin won nííjé bánakúErú bìnrin won nííjé wòrúkúDimúdimù aleìgbòOkùnrin yàkàwú orí ìgbáÌgbá kòwóOkùnrin yàkàwú kòsòkalèÒní laóko igbó olú-kóókó-bojoÒla laóko igbó olú-kóókó-bojoAkogbó olú-kóókó-bojo tánApa ekùn kan mìnììjò-miniijo tínbe lábé ìtíWónní kí ...