Home / Àṣà Oòduà / Ìṣẹ parí fún òṣìṣẹ́ tó bá gbé àṣírí Ìjọba jáde lọ́nà àìtọ́—Ìjọba àpapọ̀

Ìṣẹ parí fún òṣìṣẹ́ tó bá gbé àṣírí Ìjọba jáde lọ́nà àìtọ́—Ìjọba àpapọ̀

Ìṣẹ parí fún òṣìṣẹ́ tó bá gbé àṣírí Ìjọba jáde lọ́nà àìtọ́—Ìjọba àpapọ̀

Ṣé àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní, ìlú tí kò sófin, ẹ̀sẹ̀ kò sí níbẹ̀, gẹ́lẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Orílẹ̀ yìí dà báyìí, bí Ìjọba àpapọ̀ se ni ìwé ìdádúró ni òun yóò fún ẹnikẹ́ni tí aje ìwà ìbàjẹ́ gbígbé ìwé àti àṣírí ìjọba síta lórí ayélujára lọ́nà àìtọ́ bá sí mọ́ lórí.

Ó ní ìwé ìjọba kan tó fara hàn lórí ayélujára láìpẹ́ yìí níbi tí o ti fi ìwé wá wí tẹnu ù rẹ sọwọ́ sí akọ̀wé ilé iṣẹ́ àpapọ̀ kan jẹ́ èyí tó tini lójú gidigidi.

Olórí òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ Ọ̀mọ̀wé Folashade Yemi-Esan ló fi ìpè náà síta pé ẹnikẹ́ni tí ìjọba ba mú yóò fẹnu fẹ́ra bí abẹ̀bẹ̀.

Ìkìlọ̀ yìí kò sẹ̀yìn ìwé ìkìlọ̀ tí wọ́n fun akọ̀wé àgbà ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ìmọ̀ sáyẹ́nsì Mohammed Bello Umar fún ríra ilé tí wọn ò kọ́ tán ní bílíọ́nù méje náírà fún ilé iṣẹ́ tó ń rí sí nǹkan ọ̀gbìn bó ṣe lu síta lórí ayélujára.

Olórí òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ ní Umar ló mójú tó ìdúnadúrà náà lásìkò tó jẹ́ akọ̀wé ilé iṣẹ́ nǹkan ọ̀gbìn

Bákan náà ló ní akọ̀wé ọ̀un tún gbé iṣẹ́ ẹ gbígbẹ́ kànga ìgbàlódé méje síta ní bílíọ́nù kan ó lé díẹ̀ lọ́nà àìtọ́.


Ìdáhùn Umar tó fi ṣọwọ́ padà sí olórí òṣìṣẹ́ níbi tó ti fèsì pé irọ́ pọ́nbélé ni gbogbo ọ̀rọ̀ náà tún jẹ jáde lórí ayélujára bákan náà.

Ọ̀rọ̀ tí Ààrẹ Muhammadu Buhari kà sétí ìgbọ́ ọmọ Nàìjíríà ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin lórí àrùn Covid19 ti ṣaájú Ààrẹ dé orí ayélujára wákàtí díẹ̀ kí Ààrẹ tó dórí afẹ́fẹ́.


Ẹ̀wẹ̀ Yemi-Ẹsan ṣàpèjúwe àwọn nǹkan wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bíi nǹkan tó burú jáì lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba tó sì pè fún yíyọ eni tí aje ọ̀rọ̀ náà bá sí mọ́ lórí ní ṣẹ́, gẹ́gẹ́ bí òfin iṣẹ́ ìjọba ṣe gbé e kalẹ̀.

Gbogbo ẹ̀ka ìjọba pátá ní ọ̀rọ̀ náà kàn.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About AbubakarMuhd

x

Check Also

IGP usman

Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá Ìròyìn òkèrè, bí ò lé, a dín.Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣàlàyé bí ìdigunjalè kan tí ìròyìn sọ pé ó gba ẹ̀mí èèyàn kan ṣe wáyé ní ọjà Bódìjà nílùú Ìbàdàn. Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Adéwálé Òṣífẹ̀sọ̀, sọ nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún pé lọ́jọ́ ẹtì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Ó ní arákùnrin kan, Abubakar Ibrahim, ni àwọn adigunjalè kọlù ní nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n sì yìnbọn mọ́ ọ kí wọ́n ...