Home / Àṣà Oòduà / “Idagbasoke awon akonimoogba gbodo je koko fun NFF” – Amodu

“Idagbasoke awon akonimoogba gbodo je koko fun NFF” – Amodu

Shuaibu Amodu, okan lara awon igbimo oludari ajo NFF ti so wi pe ona kan pataki lati se igbelaruge fun ere boolu alafesegba abele ni nipa sise eto idagbasoke fun awon akonimoogba ere boolu ile Naijiria. Oro yii ni Amodu, eni odun metadinlogota (57) se niluu Minna nigba ti won pate idanileko ita gban-angba fun awon akonimoogba ere boolu ile Naijiria.

“A le yanju isoro ti n koju ikoni awon ojewewe agbaboolu ile wa ti won gba boolu labele nipa sise agbekale awon eto to giriki fun idagbasoke awon akonimoogba wa gbogbo,” Amodu fikun alaye re bee.

Amodu, eni to ti fi igba kan je akonimoogba egbe agbaboolu Orlando Pirates ti ilu South Africa tun so wi pe, aseyori Golden Eaglets ninu idije 2015 FIFA U-17 World Cup ko fi bee wu oun lori nitori wi pe pupo awon omo naa ni ko gba abe itoju boolu abele ile wa koja. O si tun so wi pe ona kan pataki lati da ogo boolu ile Naijiria pada ni pipada si ese aaro fun atunse to munadoko.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo