Home / Àṣà Oòduà / Ìjọba ti ayédèrú ilé ọmọ aláìlóbìí pa, ọmọdé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n gbòmìnira

Ìjọba ti ayédèrú ilé ọmọ aláìlóbìí pa, ọmọdé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n gbòmìnira

Ìjọba ti ayédèrú ilé ọmọ aláìlóbìí pa, ọmọdé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n gbòmìnira

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn aláṣẹ tọ́rọ̀ kan lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti kó àgádágodo sílẹ̀kùn ilé ọmọ aláìóbìí kan tí kò ní wè é òfin ní ìpínlẹ̀ Kaduna, tí wọ́n sì tú ọmọdé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n sílẹ̀.

Ọjọ́ orí àwọn ọmọ náà wà láàrin ọdún mẹ́ta sí méjìlá.

Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kano, DSP Abdullahi Haruna sọ fún akọ̀ròyìn pé, ó tó ọmọdé mọ́kàndínlógún táwọn tú sílẹ̀ nílé àwọn ọmọ aláìóbìí Du Merci nílùú Kano.

Bákan náà ni Abdullahi sọ pé, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá tún tú àwọn mẹ́jọ mìíràn sílẹ̀ nílé àwọn ọmọ aláìóbìí Du Merci tó wà nílùú Kaduna.

Ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá sọ pé, eléyìí ṣeéṣe pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àjọ NAPTIP tó ń gbógun ti fífi èèyàn ṣe òwò ẹrú lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ní, ayédèrú ilé ọmọ aláìóbìí nibi táwọn ti tú àwọn ọmọdé náà sílẹ̀.

Olùdámọ̀ràn fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Fatima Abdullahi Dala, tó bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé Du Merci ti wà fún bí ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n láì níwèé òfin.

Ó wá rọ àwọn èèyàn Kano láti fi tó Ìjọba létí, tí wọ́n bá ṣàkíyèsí irú ilé ọmọ aláìóbìí bẹ́ẹ̀ lágbègbè wọn.

About ayangalu

x

Check Also

IGP usman

Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá Ìròyìn òkèrè, bí ò lé, a dín.Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣàlàyé bí ìdigunjalè kan tí ìròyìn sọ pé ó gba ẹ̀mí èèyàn kan ṣe wáyé ní ọjà Bódìjà nílùú Ìbàdàn. Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Adéwálé Òṣífẹ̀sọ̀, sọ nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún pé lọ́jọ́ ẹtì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Ó ní arákùnrin kan, Abubakar Ibrahim, ni àwọn adigunjalè kọlù ní nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n sì yìnbọn mọ́ ọ kí wọ́n ...