Home / Àṣà Oòduà / Ikú agbábó̩ò̩lù: LMC fa ìbínú yo̩

Ikú agbábó̩ò̩lù: LMC fa ìbínú yo̩

Ikú agbábó̩ò̩lù: LMC fa ìbínú yo̩
– Iroyin lati Owo Akinwale Taophic.

Latari iku odo agbaboolu, Chineme Martin’s, eni ti o pade iku ojiji ni abala akoko ifigagbaga ose ketalelogun liigi orileede wa Nigeria, NPFL, ti o waye laarin Nasarawa United ati Kastina United ni Papa isere Lafia, ile ise ti o n se kokaari liigi ni orileede wa Nigeria, LMC, ti gbe igi da arakunrin ti o se amojuto ifigagbaga ti isele buruku naa ti sele leyin, ogbeni Christian Mba, wi pe ki o lo rokun nile fun igba kan nan.

NInu oro ti agbenuso fun LMC fi sita, won je ki o di mimo wi pe aikoju osunwon to ogbeni Mba pelu ki eniyan ma kaju ise ti won gbe le lowo ati fifi ise jafara re ni o fa iku agbaboolu naa, idi re si niyi ti won fi ni ki o lo jokoo sile baba re titi di asiko ti awon yoo pari gbogbo iwadii won.

Won tun kowe si ajo ti o n se kokaari ere idaraya boolu alafesegba ni orileede wa Nigeria, NFF, lati yo owo Mba, eni ti o je okan lara ajo to o n se kokaari boolu alafesegba ni ipinle Enugu, kuro patapata ninu ere idaraya boolu alafesegba ki egungun o si ma se mo rara lawujo boolu alafesegba nitori wi pe o je ki ifigagbaga naa o tesiwaju leyin igba ti o ti ri wi pe gbogbo ohun eto ilera ati abo ti o peye ko si ni papa isere naa. Eyi ti o tun fi ba oro naa je ni wi pe ko fun ajo LMC ni abo esi ifigagbaga naa rara laarin gbedeke akoko ti ofin lakale lati jabo eyikeyi ifigagbaga. Won tun gba ajo NFF ni amoran wi pe ki won o din iye awon alamojuto ifigagbaga liigi ku lati yo owo awon ti musemuse won koda musemuse kuro lawo.

Ajo LMC tun pase wi pe ki egbe agbaboolu Nasarawa United o lo san owo ti o to milionu mefa naira (N6m) laarin ojo ise mewaa pere gege bi owo itanran ati ifanileti wi pe won ko gbodo je ki iru e tun somo lowo won mo, ati wi pe ti iru e ba tun sele ni odo won laarin akoko yi si opin liigi 2020/2021, won yoo fi imu kata ofin ti o gaju ti won yoo si tun yo ami mefa sangiliti kuro ninu ami won. Bee ni ajo naa tun pase wi pe ifigagbaga liigi kankan ko gbodo waye ni Papa isere Lafia mo titi di igba ti won yoo se gbogbo ohun ti o ye ki won o se si papa isere naa fun eto ile ilera ati abo emi fun gbogbo awon ti won ba wa si papa isere naa gege bi ofin ati Ilana NPFL se la kale.

Iwadii ati alaye lati enu awon ti isele naa soju won fi han wi pe agbaboolu naa ko ba ti ma gbemi mi ni ojo naa, ti o ba je wi pe eto ilera ti o peye wa ni papa isere ni ojo buruku esu-gbomi-mu naa ni, nitori wi pe ni kete ti o daku ni awon eniyan ti sare sii lati du emi re sugbon ko si eroja iwosan ti o peye ni papa isere naa rara ati wi pe oko pajawiri (Ambulance) ti o ye ki won o fi gbe lo so ile iwosan fun itoju kiakia ko, ko sise, koda awon eniyan gbiyanju lati fi owo ti oko naa sise, sugbon gbogbo igbiyanju won pabo lo ja si. Won gbe agbaboolu naa de ile iwosan pelu oko okan lara awon ti won tele Gomina ipinle Nasarawa, Abdullahi Sule, wa si papa isere lati wa wo ifigagbaga naa sugbon nigbeyin-gbeyin, epa ko boro mo ! nnkan pada polukumusu ti agbaboolu naa si je Olorun nipe.

Ami ayo meta si odo (3-0) ni ifigagbaga naa pari si ninu eyi ti egbe agbaboolu ti o gbalejo ti bori

About ayangalu

x

Check Also

IGP usman

Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá Ìròyìn òkèrè, bí ò lé, a dín.Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣàlàyé bí ìdigunjalè kan tí ìròyìn sọ pé ó gba ẹ̀mí èèyàn kan ṣe wáyé ní ọjà Bódìjà nílùú Ìbàdàn. Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Adéwálé Òṣífẹ̀sọ̀, sọ nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún pé lọ́jọ́ ẹtì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Ó ní arákùnrin kan, Abubakar Ibrahim, ni àwọn adigunjalè kọlù ní nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n sì yìnbọn mọ́ ọ kí wọ́n ...