Home / Àṣà Oòduà / “Ise aye lo mu mi fadi omo odun meji ya”- Okunrin eni aadota odun (50) lo so bee

“Ise aye lo mu mi fadi omo odun meji ya”- Okunrin eni aadota odun (50) lo so bee

“Ise aye lo mu mi fadi omo odun meji ya”- Okunrin eni aadota odun (50) lo so bee
Olayemi OlatilewaOkon Michael, eni aadota odun (50) to fi tipatipa fadi omobrin eni odun meji (2) ya perepere ni ipinle Akwa Ibom ti pada jewo fun awon olopaa wi pe awon aye lo wa nidi oro oun.

Michael, eni to je omo bibi ilu Mbak Ekpe to wa nijoba ibile Ibesikpo Asutan ni ipinle  Akwa Ibom tun alaye re se fun awon oniroyin nigba ti ile ise olopaa ipinle naa se afihan won faye ri.

“Titi di akoko ti mo fi n ba yin soro yii, mi o tile le so ohun pato to mu mi se ohun ti won ni mo se. Oro mi ki n soju lasan o. E dakun, e ma foju lasan wo oro mi, o dabi eni wi awon aye n semi”.

Micheal, eni ti won ni iyawo re ti ko o le fun igba pipe, eleyii ti kosi si omo re kankan ti n ba gbe tun tesiwaju ninu oro re:

“Ohun kan ti mo sakiyesi saaju asemase ti mo se ni bi enikan se riran si mi wi pe ogun nla kan mbe niwaju mi. Eleyii ti mo gbodo mura gidigidi ki ogun naa ma ba bori mi”, Micheal fikun oro re bee.

Omobirin eni odun meji ti won fi oruko bo lasiri yii lagbo wi pe o si wa losibitu leyin ti awon dokita ti fi owu atabere ran oju ara re.Ogbeni Micheal ti n rawo ebe si awon olopaa lati foju fo asise re nitori wi pe awon aye lo wa nidi oro naa.

Micheal ati awon odaran afurasi meloo kan ti won se afihan won lori esun wi pe won ka ibon ati ogun oloro mo won lowo ni komisanna ipinle Akwa Ibom, Murtala Mani, se lalaye fun awon oniroyin wi pe laipe ni awon odaran afurasi naa yoo foju ba ile ejo fun idajo to peye labe ofin.

Gege bi akojopo iwadii ajo UN agbaye, eka to n risi idaran ati ogun oloro fi ye wa wi pe orileede South Africa ni iwa ibaje ifipabanilopo ti wopo julo ni ile Afirika.

Gege bi alaye ti ile ise olopaa orileede ilu Nelson Mandela se, won ni laaarin iseju-aya merindinlogoji (36 seconds) ni ifipabanilopo fi n waye kaariki orileede naa.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo