Home / Àṣà Oòduà / Kini yoo gbeyin TB Joshua leyin iku awon eniyan 116 to ku ni Synagogue?

Kini yoo gbeyin TB Joshua leyin iku awon eniyan 116 to ku ni Synagogue?

*Igbejo dide leyin odun kan tile wo pa awon olujosin
*Temitope Joshua ko lati yoju si kootu
*Kini Kola Olawuyi so nipa wooli naa ko to lo sorun?
Olayemi Olatilewa

Temitope Babatunde Joshua
Oludari ijo Synagogue, Wooli Temitope Babatunde Joshua, ti ko lati foju han nile ejo lojo Aje to koja yii lori esun to dalori ile-igbe igbalejo ti ile ijosin re to wa ni Ikotun Egbe niluu Eko eleyii to wopa awon olujosin merindinlogofa (116) lojo kejila osu kesan-an odun to koja (12/09/14).

Wooli TB Joshua nikan ko lo kotiikun si iwe ipejo lati farahan nile ejo, awon abanikole meji ti won gba ise ile kiko naa pelu awon eniyan ti won ko lati duro niwaju ile ejo to gaju eleyii to kale siluu Eko nibi ti igbejo naa ti waye.

Ninu ijamba ile-igbe igbalejo to waye naa lo je wi pe pupo awon eniyan ti won padanu emi won ni won je awon alejo omo orileede South Africa ti won wa fun akanse adura ati ise iyanu oju ese lati owo Wooli TB Joshua.

Igba akoko ni yii ti ejo naa yoo ma di gbigbe dide nile ejo lati nnkan bi odun kan o le die ti isele naa ti waye. Alaye Ogbeni Oyetade Komolafe, onimo ijinle nipa ijamba pajawiri, si wa lara itako nla ti n duro de alase ati oludari Emmanuel telifisan ni ile ejo. Gege bi esun iwadii ti Ogbeni Oyetade gbe si iwaju ile ejo se so, ile-igbe igbalejo to wopa awon eniyan naa ni won koko ko nile oloke meji. Sugbon nigba to ya, won tun fi aja merin kun ile naa loke. Eleyii to so apopo ile naa di oloke mefa.

O ni ipile-ile to je fandesan ile naa ni agbara re ko le gbe ju ile oloke meji ti won koko fi ko tele lo. “Aja merin ti won fi kun-un loke lo fa ijamba to sele yii nitori wi pe eru ile naa ti poju ohun ti fandesan le gbe lo,” Oyetade fi kun oro re bee. Bakan naa lo tun so fun ile ejo wi pe, ko si iwe ase kankan lati odo ijoba eleyii to fun won lase lati so ile oloke meji di oloke mefa lori fandesan kan naa.

Oludari ijo Olorun ti won dasile lodun 1987 salaye wi pe, awon se akiyesi baalu, oko ofurufu kan, ti n paara lori ile-igbe igbalejo naa ni awon akoko ti isele buruku naa sele. Won si gba wi pe oseese ki ijamba naa wa lati owo baalu naa eleyii ti won lo tun le je ise owo awon Boko Haram.

Isele to ti sele bi odun kan seyin yii ni awon onwoye nipa igbe aye eda gba wi pe awon alase n kowo idajo ododo bonu aso latari wi pe eniyan to nifon to leekanna ni oro naa simo lori. Oro yii ni Nicholas Ibekwe, oniroyin to rikoodu ohun enu TB Joshua nigba to n pin N50,000 fun awon oniroyin, pada fidi re mule ninu alaye re to se .

Ninu oro enu Wooli Joshua eleyii ti Ogbeni Ibekwe ka sile lori ero agbohunsile, ibe ni TB Joshua ti n seleri egberun lona aadota naira (50, 000) fun awon akoroyin ti won wa foro wa lenu wo leyin igba ti isele naa waye. Bi o tile je wi pe owo irinse lasan ni wooli naa pe e, sibesibe, Ibekwe gba wi pe riba lati fi pa enu awon oniroyin mo ni.

“Mo ko lati gba iru owo eje bee. Awon akoroyin bi ogbon ni enikookan won tewo gba N50, 000 lowo wooli naa. Kii se wi pe mo ni opolopo owo nile lo mu mi ko owo wooli naa, o kan je wi pe emi awon eniyan to sofo kamilara ju owo naa lo ni,” Ogbeni Ibekwe se lalaye bee.

Ogbeni Ibekwe tun so siwaju wi pe ohun to mu ohun gbe oro enu TB Joshua, eleyii ti oun ka sile lojo ti n pin egberun lona aadoogota fun oniroyin kookan, jade ko ju bi ohun se ri lori telifisan nigba ti aare orileede Naijiria nigba naa, Goodluck Jonathan se abewo ibanikedun si okunrin naa. O ni loju toun, o dabi eni wi pe won fi owo tutu mu TB Joshua eleyii ti ko si ye ko ri bee rara.

“Sebi won ni ibi ko jubi, baa se beru naa labomo. Akole iroyin naa lo bi mi ninu, akole naa ka wi pe, ‘Aare kedun pelu TB Joshua’. Eleyii gan-an lo mi mu gbe akasile-ohun re jade fun gbogbo aye. Iwa ti mo wu le je ohun ti o mu laakaye dani, o si le je itura fun gbogbo eni egun n gun lese. Sugbon ohun kan lo damiloju, mi o kabamo igbese ti mo gbe rara,” Ibekwe fun kun oro re bee.

Gege bi alaye MagasininniForbes agbaye, ipo kewaa ni Wooli TB Joshua wa ninu awon ojise Olorun to lowo ati dukia ju lagbaye. Nigba to di ipo keta mu laaarin awon ojise Olorun tile Naijiria. Apapo iye owo ati dukia re ni won lo to nnkan bi milionu meedogun owo dollar ile Amerika. Nigba ti awon eniyan ti won to bi egberun meedogun (15, 000) n joko leekan soso josin ni ile ijosin re lojo Sande.

Orisiirisii asotele ati iriran ni wooli yii ti so jade eleyii to pada wa si imuse. Lara re ni isele ijamba manigbagbe 9/11 tiluu Amerika eleyii to waye ni World Trade Centre lodun 2001, nibi ti awon eniyan bi egberun meta (3000) ti je Olorun nipe nigba ti awon bi egberun mefa (6000) farapa ti won si pada di alaabo ara. Ikolu awon alakatakiti esin Islam, ISIS, to waye niluu Paris laipe yii tun je eyi ti emi Olorun ti fi han wooli, eni odun mejilelaadota (52) saaju ki isele naa to waye.

Lodun 1998 ni ile ise Radio Nigeria to kale siluu Ibadan fi apari isu han Akolawole Olawuyi to je atokun eto Iriri Aye latari afihan ise iwadii re nipa Wooli TB Joshua. Ninu Alaye Oloogbe Olawuyi, sorosoro ori redio naa gba wi pe ki i se agbara Olorun oga ogo ni wooli naa fi n se ise iyanu re. Rabaraba isele yii lo si mu okunrin to fi irunmu se fensi ete di ero Abeokuta. Enikeni ko tun pada tun iwadii naa gbe dide mo titi ti oga Yinka Ayefele fi silebora lojo kerin osu keta odun 2007.

Ninu eto idajo to waye lojo Aje to koja yii, agbejoro ti n soju Synagogue Church Of All Nations(SCOAN), Oluwaseun Abimbola, so niwaju onidaju wi pe, kii se dandan ni ki Wooli TB Joshua yoju sile ejo. Ogbeni Abimbola ni ijo ni won fesun kan, ki i se TB Joshua. Latari eleyii, enikeni lo le soju ijo naa nile ejo. Lopin ohun gbogbo, onidajo Lawal Akapo pase lati se awari adiresi awon abanikole meji, Oladele Ogundeji ati Akinbela Fatiregun ti won sise ile naa nigba to sun ejo naa di ojo kokanla osu kejila odun yii (11/12/15).

 

Orisun

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo