Home / Àṣà Oòduà / Madueke ko ti bo ninu ejo, Ile ejo ko fun Saraki nisimi, Abba Moro tun ko sowo EFCC

Madueke ko ti bo ninu ejo, Ile ejo ko fun Saraki nisimi, Abba Moro tun ko sowo EFCC

Madueke o ti bo ninu ejo, Ile ejo o fun Saraki nisimi, Abba Moro tun ko sowo EFCC
Olayemi Olatilewa

Ile ise ti n risi iwa idaran niluu London, National Crime Agency [NCA] si n ba iwadii won lo ni rebutu nipa minisita epo robi ile Naijiria nigba kan, Arabinrin Diezani Alison-Madueke lori awon esun jegudujera ti won fi kan-an.

Bi o tile je wi pe awon agbofinro ilu London ti pada tu Madueke sile ko maa lo sile, sugbon gbogbo iwe irinna re pata ni won ti gba lowo re.

Eleyii ti ko fun lanfaani lati tirafu jade niluu London titi ti gbogbo iwadii ti won se yoo fi kesejari.

Nibi ti Madueke, obirin akoko ti o je aare egbe awon orileede ti won ti n fo epo-robi lagbaye, Organization of the Petroleum Exporting Countries (OPEC), ti n ronu kini o le je abajade iwadii awon olopaa ilu London, Bukola Saraki ko loju orun mo bi ile ejo tun se sun igbejo re siwaju.

Aare ile igbimo asofin agba l’Abuja, Dokita Bukola Saraki ni ile ejo ti sun igbejo re siwaju di ojo karun-un ati ojo kefa osu kokanla odun ta a wa yii.

Saraki ni won fi esun metala kan eleyii to dale aisododo nipa ijewo dukia eni ati awon iwa jegudujera ni awon akoko to je gomina ipinle Kwara. Nibayii, ile ejo ti sun igbejo naa siwaju latari ki awon iwadii kan to n lo lowo le jinle daada.

Boya eyin gbagbe, losu keta odun 2014, awon eniyan bi ogun, awon odo, ni won doloogbe nibi won ti n lakaka lati rise gba ni eka ile ise ijoba apapo to n risi wiwole-wode, Nigerian Immigration Service. Abba Moro lo je minisita feto abenu nigba naa ti oro naa kan ni awon ara ilu pe fun idaduro re lenu ise. Sugbon aare to wa nipo nigba naa, Goodluck Jonathan, foju fo asise re da.

Asiri to tun tu nigba naa ni wi pe won fi eto igbanisise naa kowo je eleyii ti won ni kan dapada sugbon ti won ko lati se bee.

Awon Yoruba bo, won ni iyan ogun odun a maa jo ni lowo felifeli.

Nibayii, Awon ajo ti n gbogun ti iwa jegudujera, EFCC, ti ra maanu naa mu. Won si ti ni ko bere si ni so tenure re nipa awon esun ti won gbe ka a laya leyin osu marun-un to ti gbe ise ijoba ju sile.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*