Home / Àṣà Oòduà / Màmá àádó̩rin o̩dún ròó pin sí ófíìsì àwo̩n oníná mò̩nàmó̩ná

Màmá àádó̩rin o̩dún ròó pin sí ófíìsì àwo̩n oníná mò̩nàmó̩ná

Màmá àádó̩rin o̩dún ròó pin sí ófíìsì àwo̩n oníná mò̩nàmó̩ná
Lati owo
Yinka Alabi
Iya agbalagba ti ko din ni aadorin odun lo lo roo pin si ofiisi ajo apina-ka (IBEDC) Ibadan Electricity Distribution Company to fi ikale si ilu Osogbo.
Mama yii di awon nnkan to le nilo ti ebi ba n paa bii – sitoofu idana, abo idana, kerosinni, abo ijehun ati awon nnkan ilo inu ile miran.


Kin ni “mama yii ri lobe ti o fi waro owo”? Mama ni oun ti san owo fun mita ti ko ni itanje, to je pe bi eniyan ba se n loo ni owo re se n lo. Mama ni oun reti remu, oun ko gburo awon ajo onina yii lo ba mu ki oun kuku see ni “oju awo ni awo fi n bu obe”.


Ni igba ti awon ara ofiisi yii tii pe mama yii ko mu ni oro awada, Kia ni won ranse si olu ile ise won to wa ni ilu Ibadan. Ibe naa ni ase ti gun un ki won mu mama naa lo ile ki won si lo so mita ina naa.


Awon ajo IBEDC ilu Osogbo pa akiti mole won si gbe mama de ile re ni Atelewo ni ilu Osogbo. Won so mita naa mo ile , won si pari gbogbo eto miran to tun ye ki won to kuro ni ile mama naa.

http://iroyinowuro.com.ng/2019/10/29/mama-aado%cc%a9rin-o%cc%a9dun-roo-pin-si-ofiisi-awo%cc%a9n-onina-mo%cc%a9namo%cc%a9na/

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo