Home / Àṣà Oòduà / OAU se ìràntí àwon akoni tí won pàdánù èmí won sí owó àwon omo egbé òkúnkùn ní ogún odún séyìn.

OAU se ìràntí àwon akoni tí won pàdánù èmí won sí owó àwon omo egbé òkúnkùn ní ogún odún séyìn.

OAU se ìràntí àwon akoni tí won pàdánù èmí won sí owó àwon omo egbé òkúnkùn ní ogún odún séyìn.
Àwon alámòójútó àti akékòó ilé-èkó gíga Obafemi Awolowo University ti ilé- ife, máa péjo sí gbàgede Amphitheater tí ilé èkó yí ní òní ojó rú láti se ìrántí ogún odún tí àwon egbé òkùnkùn jà tí won sì pa màrùn-ún lára àwon akékòó ogbà náà.
Ojó nlá, ojó tí èsù gb’omi mu ni ojó àbáméta, tí se ojó kèwá osù keje, odún 1999, tí ó mú òdómokùnrin omo odún mókànlélógún di èrò òrun.
Ìtàn so fún wa pe, Akékòó ìpele kerin tí a mò sí 400level ni George Iwilade, tí ìnagije rè njé AFRIKA, tí ó sì jé Akòwé fún àwon omo egbé akékòó, ilé-èkó gíga ifáfitì Obafemi Awolowo, ni ilú ile-ife.
Lóòtó òun nìkan kó ni won pa ni ojó náà, lára won ni Eviano Ekeimu (400level Medicine); Yemi Ajileteru, Babatunde Oke àti Godfrey Ekpede, ni won se alápàdé ìkú òjijò láti owo àwon omo egbé òkùnkùn ti ilé-èkó Obafemi Awolowo University. Ati ìgbà yí ni kò ti si egbé òkùnkùn kankan ni ilé èkó náà mó.
Olorí pátápátá ilé-èkó yí ní ìgbà náà ní se Wale Omole, tí won sì fi èsùn kàn án wípé kò wá nkankan se sí òrò àwon omo egbé òkùnkùn náà
nígbà náà, tí won sì fi èsùn kàn an wípé òun ní ó n fá á tí won fi n jà, bí ó tilè jé wípé ó ní iró ni won pa.
Lanre Adeleke tí ó jé Ààre ilé-èkó yí ní ìgbà náà, so wípé tènbèlèkùn ìwà jegúdú jerá ti àwon ìjoba ni orílè èdè Nìjíríà kò jé kí won wá nkankan se fún àwon omo egbe okunkun tí owó tè. Àti wípé won padà tú won sílè ni láì se ohun k’óhun fún won.
Tayo Iwilade tí se àbúrò George, Akòwé ìgbà náà, so wípé ìdájó kò tán àfi t8 a bá se ohun tí ó tó.
Bàkan náà, Alága àti Akòwé àwon omo egbé tí ó jà fún ètó àwon akékòó, tí orúko won njé Dunsi Samuel àti Babatunde Oyatokun so wípé, rírì ìrànti ogún odún yí ni láti so fún gbogbo àgbáyé wípé, ilé-èkó gíga OAU kò fàyè gba egbé òkùnkùn.

About Awo

x

Check Also

tems

Mo setán láti kú’ – Tems

Mo setán láti kú’ – Tems Mary Fágbohùn Olorin Naijiria olugbafe eye Grammy, Temilade Openiyi, ti a mo si Tems, ti safihan pe oun setan lati doju ko saare nigba ti oun fi eya orin takasufe ti gbogbo eniyan mo kaakiri orile ede sile fun R&B. Tems wi pe oun ni igbagbo pupo ninu ara oun to bee ti oun ko bikita bi oun o ba “je nnkankan tabi da enikeni” pelu R&B. Olorin ‘Essence’ naa so pe oun kan ...