Home / Àṣà Oòduà / Odu Ifa Iwure Ti Aaro Yi Ki Bayi Wipe

Odu Ifa Iwure Ti Aaro Yi Ki Bayi Wipe

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, a si tu ku imura toni eledumare koni jeki won gberu ibanuje wa kawa mole loni o ase.
Odu ifa iwure ti aaro yi ki bayi wipe:
Oseka ori odi a ki nleri oro buburu de ara eni a difa fun agbigboniwonran ti nse olori igbeposi ode orun, o gbe tomo kekere sekeseke o gbe tagbalagba baramubaramu, o gbe dele alara gbogbo won ku o gbe dele ajero kinosa gbogbo won ku o gbe dele owa orangun aga gbogbo won ku beerebe, won ni ibo lo tun ngbe oposi re nlo? o ni oke ijeti ile Orunmila, Orunmila gbo o mogbo mata o moran mobi baba o gboko alawo lo o gbodo wale agbede orun ro, won ni ko karaale ebo ni ki o wa se.

 

O kabomora o rubo, won wa duro de agbigboniwonran senu odi ilu, bi agbigboniwonran se yo lookan pelu oposi lori ni won bere sini nkorin si wipe; nje bo se iku lo ngbebo nile yi awa ko ra agbigboniwonran gberu re o awa ko ra
Bo se arun lo ngbebo nile yi awa ko ra agbigboniwonran gberu re o awa ko ra
Bo se ofo lo ngbebo nile yi awa ko ra agbigboniwonran gberu re o awa ko ra,
Bo se ajogun ibi gbogbo lo ngbebo nile yi awa ko ra agbigboniwonran gberu re awa ko ra
bi agbigboniwonran se gbe posi ibi re pada niyen, Orunmila ba njo o nyo o nyin awo awon babalawo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru atukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifa wa bawa laiku kangiri aiku kangiri ni a nba awo lese obarisa.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe, eledumare koni jeki won gbe posi wa bawa ninu ile lenu ibiti odun yi Ku si o, eru iku, eru aisan, eru ofo, eru ibanuje, eru inira ko mani je ipin tiwa laye o, enikeni ninu wa koni pedin lojiji o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

 

English Version:
Continue  After The Page Break

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

ifa

Kùtùkùtù Ìrèní Laó He Erè Nígbódù Oòni

Òní laó roko létí opónÒla laó sákà lágbèrùKùtùkùtù ìrèní laó he erè nígbódù oòniKáyáa múlé pontíKámú òdèdè rokàKáfi agbada dínranÀwèje wèmu nípón omodé wòyí lójúÒrìsà lópabuké tánLódákún sábaro nídìíOmo-ojo húnsáré gíríjo-gíríjoOmo-ojo húnsáré gìrìjo-gìrìjoIlé-ifón kògba obàtáláÈlàgboro kògba òrìsàOjúgboro ni tàfínÈlàgboro ni tòrìsàOmi níti ojú-omi rúwáÈròyà wáàponÈròyà wáàmuRúkú-rùkù-rúkú niwón nse lókè ohùnkòErú kùnrin won nííjé bánakúErú bìnrin won nííjé wòrúkúDimúdimù aleìgbòOkùnrin yàkàwú orí ìgbáÌgbá kòwóOkùnrin yàkàwú kòsòkalèÒní laóko igbó olú-kóókó-bojoÒla laóko igbó olú-kóókó-bojoAkogbó olú-kóókó-bojo tánApa ekùn kan mìnììjò-miniijo tínbe lábé ìtíWónní kí ...