Home / Àṣà Oòduà / Odu Ifa Owonrinwese/ Owonrin Ose

Odu Ifa Owonrinwese/ Owonrin Ose

| |   |
 | |  | |
 |    |
| |   |

 

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o a si ku ola jimoh oni emi wa yio se pupo re laye o, ao si ri aanu eledumare gba pelu iyanu loni o ase.
Odu ifa OWONRINWESE/OWONRIN OSE lo gate laaro yi, ifa yi gba eniti odu yi ba jade si niyanju wipe ki o we ori re daradara nitori eleda re nta ko ire re, latari irun kan ti nbe laarin ori re ti ki nse irun ara re to ye ko wa nibe ni, ifa so wipe oun ni ile aye re ko se roju ti ona re ko se raye ifa ni sugbon ti won ba se ise ifa yi fun ti o si we ori naa sodo ti o nsan ki o wa ju kanhinkanhin to fi we ori naa seyin ile onile, ifa ni ona ire gbogbo ni yio si fun o ti nkan re yio si maa lo deedee nitori irun buruku ti nbe lori re naa yio ti tu danu.
Ifa naa ki bayi wipe: Owonrin wese emi we kanhinkanhin e wa wo kanhinkanhin oro ti mo ju seyinkule eleyinkule a difa fun orikogbo eyiti nse Omo bibi inu Orunmila eyiti o fi ori ara re sile sorun to gbe ori olori wa si ile aye ti nkan re ko gun ti ona re ko suhan won ni ko karale ebo ni ki o wa se, obi meji, kanhinkanhin tuntun, ogidi ose, oromoadiye, ati igba ewe ayajo ifa ki won fi se ise ifa fun ki o lo fiwe ori re sodo won ni ti o ba si nbo lati Odo ki o ju kanhinkanhin to fiwe ori naa seyinkule ile onile o si se bee, ko pe ko jina ona ire gbogbo ba si fun ile aye re wa roju ona re wa raye o si se aseyori laye o wa njo o wa nyo o wa nyin awo awon awo nyin ifa, ifa wa nyin eledumare oni nje riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifa wa bami larusegun arusegun ni a nba awo lese obarisa, o wa fiyere ohun bonu wipe; o ma bami we ori mi, o ma bami we ori mi o awede werisa o ma bami we ori mi o awede werisa o.

 
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe eledumare yio bawa we ise ati osi ori wa danu, ao se aseyori laye wa o ao si gbe nkan gidi se nile aye o, ile aye wa to ti ruju yio da tituse lodo eledumare, awede werisa yio bawa we ori wa o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

 

English Version:
Good morning my people, how was your night? Hope it was great, i wish everybody happy Friday, may heavenly father bless us today with surprise ase.
It is OWONRINWESE/OWONRIN OSE corpus that revealed this morning, ifa advised whoever this corpus revealed out for that he/she should wash away the imbalance of his/her head so that he/she could be doing well on the earth and prosper in all endeavors. Ifa said there is one hair in his/her head which is not suppose to be there, ifa said the hair is the one causing trouble into his/her life so it must be remove away from the head before this person can have a complete life.

 
Hear what the corpus said: Owonrin wese emi we kanhinkanhin(owonrin bathed with soap and I bathed with the sponge)come and see the sponge I threw at someone’s backyard it cast divined for orikogbo the child of Orunmila the one that leave his head behind in the heaven and carried another person’s head to the earth, when his life was tough and rough, when he couldn’t have any achievements in the earth he was advised to offer sacrifice so that his life could be prosper, achieve a great goal in the earth and have a smooth and easier path, two kola nuts, sponge, black soap, chicken and ifa leaves, the orikogbo complied with the sacrifice and he was told to drop the sponge he used to wash his head while coming from the river to another person’s backyard and he did so, aftermath his life replenished greatly, he prosper and achieve tangible things on the earth he started dancing and rejoicing praising priest the priests were praising ifa while ifa was praising God he started singing the song of ifa that; come and wash away my head come and wash away my head oh awede werisa come and wash away my head oh awede werisa.

 
My people, I pray this morning that heavenly father will help us to wash away the imbalance of our heads, we shall be triumphs in our life and achieve a tangible things, all our life’s that were seemed clumsy shall be rebrand by heavenly father and awede werisa will wash our heads ase.

Faniyi David Osagbami

About ayangalu

One comment

  1. always thought Owonrin Wese was about adultery

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

ifa

Kùtùkùtù Ìrèní Laó He Erè Nígbódù Oòni

Òní laó roko létí opónÒla laó sákà lágbèrùKùtùkùtù ìrèní laó he erè nígbódù oòniKáyáa múlé pontíKámú òdèdè rokàKáfi agbada dínranÀwèje wèmu nípón omodé wòyí lójúÒrìsà lópabuké tánLódákún sábaro nídìíOmo-ojo húnsáré gíríjo-gíríjoOmo-ojo húnsáré gìrìjo-gìrìjoIlé-ifón kògba obàtáláÈlàgboro kògba òrìsàOjúgboro ni tàfínÈlàgboro ni tòrìsàOmi níti ojú-omi rúwáÈròyà wáàponÈròyà wáàmuRúkú-rùkù-rúkú niwón nse lókè ohùnkòErú kùnrin won nííjé bánakúErú bìnrin won nííjé wòrúkúDimúdimù aleìgbòOkùnrin yàkàwú orí ìgbáÌgbá kòwóOkùnrin yàkàwú kòsòkalèÒní laóko igbó olú-kóókó-bojoÒla laóko igbó olú-kóókó-bojoAkogbó olú-kóókó-bojo tánApa ekùn kan mìnììjò-miniijo tínbe lábé ìtíWónní kí ...