Home / Àṣà Oòduà / Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni pásítọ̀ Sòtítọbirẹ̀ yóó ti ṣe kérésì

Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni pásítọ̀ Sòtítọbirẹ̀ yóó ti ṣe kérésì

Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni pásítọ̀ Sòtítọbirẹ̀ yóó ti ṣe kérésì

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ondo ti gbé Pásítọ̀ Alfa Babatunde tíí ṣe olùdásílẹ̀ Ìjọ Sòtítọbírẹ ní Ondo lọ Ilé ẹjọ́ léyìí tí ìwòye sì tún ń ṣàfihàn rẹ̀ báyìí pé Wòlíì náà yóó najú tayọ ọdún Kérésìmesì lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tó wáyé nílé ẹjọ́, adájọ́ ní kí wọ́n sọ Pásítọ̀ náà ṣí ẹ̀wọ̀n ọjọ́ mọ́kànlélógún gbáko títí wọn yóó fi parí ìwádìí.

Fún Ìdí èyí, ilé ẹjọ́ ti sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kínní ọdún 2020.

Ẹsẹ̀ kò gbèrò nínú ilé àti ìta ọgbà Ilé ẹjọ́ Oke Eda nílùú Akurẹ níbi tí Ìjọba gbé e lọ.

Ṣe ni àwọn èrò tó wá wòran káwọ́ mórí nígbà tí wọ́n rí i tó jáde síta láti inú Ilé ẹjọ́, torí nígbà tí wọ́n gbé e wọlé, àwọn òṣìṣẹ́ àjọ DSS yí i ká, wọn kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ráàyè wọ̀sọ́sọ́ sọ́dọ̀ ọ rẹ̀.

Ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò tó wà níbi ìgbẹjọ náà sọ pé ní Ìlànà òfin, kò tíì sí àrídájú kankan tí wọ́n fi lélẹ̀ pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo ló gbé pásítọ̀ Ìjọ Sòtítọbírẹ Miracle Centre, Wòlíì Alfa Babatunde lọ ilé ẹjọ́,Oke Eda, tó wà nílù Akure fún ẹ̀sùn ìjọ́mọgbé.

Pásítọ̀ náà àti àwọn meje mìíràn ni Ìjọba fojú u wọn balé ẹjọ́.

Lára ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan wòlíì náà àti àwọn èèyàn rẹ̀ ,ni ìdìtẹ̀ láti jí ọmọ gbé àti ẹ̀sùn jíjí ọmọ gbé.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ẹ̀sùn náà ṣe sọ ọ́, lára àwọn èèyàn tí ìjọba pè lẹ́jọ́ ọ̀hún ti na pápá bora.

Nígbà tí akọ̀ròyìn fi ọ̀rọ̀ wá agbẹjọ́rò rẹ̀ lẹ́nu wò, ó ṣàlàyé pé bí onibara òun kò bá ṣẹ̀ sí òfin, wọn yóó fi sílẹ̀. Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá rí i pé ó jẹ̀bi, òun gan gbà pé kí wọ́n fi jófin.

” Àwa gan ń fẹ́ ìdájọ́ tó tọ́”, lọ̀rọ̀ tí agbẹọ́rò rẹ̀ sọ.

About ayangalu

x

Check Also

IGP usman

Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá Ìròyìn òkèrè, bí ò lé, a dín.Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣàlàyé bí ìdigunjalè kan tí ìròyìn sọ pé ó gba ẹ̀mí èèyàn kan ṣe wáyé ní ọjà Bódìjà nílùú Ìbàdàn. Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Adéwálé Òṣífẹ̀sọ̀, sọ nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún pé lọ́jọ́ ẹtì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Ó ní arákùnrin kan, Abubakar Ibrahim, ni àwọn adigunjalè kọlù ní nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n sì yìnbọn mọ́ ọ kí wọ́n ...