Home / Àṣà Oòduà / Ògún Majek wọ káà ilẹ̀ sùn

Ògún Majek wọ káà ilẹ̀ sùn

Ògún Majek wọ káà ilẹ̀ sùn

Ọlọ́jọ́ ń kajọ́, ẹ̀dá ò fiyè si.
Ìjọ ọmọ tuntun dáyé, nijọ́ ìdùnnú, ẹ̀rín, òhun ọ̀yàyà fún ẹbí,ará, pẹ̀lú ìyekan. Ṣùgbọ́n kìí rọgbọ ká sàdédé sàfẹ̀kù èèyàn ẹni pékú yọwọ́ ọ rẹ̀ ní dúníyàn.

Àsamọ̀ yìí ló díá fún ìròyìn tó ń tẹ̀ wá lọ́wọ́ báyìí pé, ìlúmọ̀ọ́ká òṣèré tíátà Gbọ́lágadé Akínpẹ̀lú, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Ogun Majek ti jáde láyé, bákan náà wọ́n ti sin-ín ní ìlànà mùsùlùmí.

Ọ̀rẹ́ tímọ́timọ́ Ògún Majek tí wọ́n tún jọ jẹ́ òṣèré tíátà, Musiliu Dásọfúnjó, tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Èṣù làálú, ló fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún akọròyìn.

Dásọfúnjó ní ìbànújẹ́ ọkàn ló jẹ́ fún òun nígbà tí òun gbọ́ nípa ikú ọ̀rẹ́ òun yìí, nítorí kò dàgbà débi tó yẹ kó kú lásìkò yìí.

Dásọfúnjó ní wọ́n gbé Májẹ́kódùnmí dìgbàdìgbà lọ sí iléèwòsàn UCH ní Ìbàdàn, nígbà tí àìsàn rẹ̀ fẹ́ bọ́wọ́ s’órí àmọ́ ẹ̀pa kò bóró mọ́.

Ó fikún-un pé, kìí ṣe pé àgbà ló dé sí ọ̀rẹ́ òun nítorí ọjọ́ orí rẹ̀ kò tíì tó nǹkan, àmọ́ àsìkò ti tó, ni Majek fi di èrò ọ̀run.

Àìsàn kídìnrín àti àìsàn ìtọ ṣúgà ni Majek ti ń bá fínra fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kó tó jáde láyé.

Dásọfúnjó fikún-un pé, ọ̀sán òní ni wọn sin Majek gẹ́gẹ́ bí ìlànà ẹ̀sìn mùsùlùmí.

Ọ̀rẹ́ tímọ́timọ́ Ògún Majek, Musiliu Dásọfúnjó ní ìlú wọn ní agbègbè Elesude, lọ́nà Ọmí ní ìlú Ìbàdàn ni wọ́n sin-ín sí.

Musiliu Dásọfúnjó ní àwọn ẹgbẹ́ òṣèré Yorùbá ló se kòkàárí ètò ìsìnkú rẹ̀.

Ọ̀rẹ́ olóògbé náà wá sàpèjúwe Ògún Majek gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ní sùúrù, tí kìí sì í fa wàhálà.

“Majek jẹ́ ẹni tí kò sí nǹkan tí kò ba lára mu, tó sì tutù ní ìwà.”

Dásọfúnjó tún ní “láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn, Majek jẹ́ ẹni tó lawọ́, tí kò bá ní, ó máa ń jẹ́ ìbànújẹ́ ọkàn fún un.”

Dásọfúnjó ní ohun tó dun òun jù ni pé, òun kò ní rí i mọ́, tí wọn kò sì ní leè sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ìléwọ́ mọ́.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

IGP usman

Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá Ìròyìn òkèrè, bí ò lé, a dín.Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣàlàyé bí ìdigunjalè kan tí ìròyìn sọ pé ó gba ẹ̀mí èèyàn kan ṣe wáyé ní ọjà Bódìjà nílùú Ìbàdàn. Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Adéwálé Òṣífẹ̀sọ̀, sọ nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún pé lọ́jọ́ ẹtì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Ó ní arákùnrin kan, Abubakar Ibrahim, ni àwọn adigunjalè kọlù ní nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n sì yìnbọn mọ́ ọ kí wọ́n ...