Home / Àṣà Oòduà / Omo yibo yari mo awon omo ile igbimo asofin Eko lowo.

Omo yibo yari mo awon omo ile igbimo asofin Eko lowo.

Omo yibo yari mo awon omo ile igbimo asofin Eko lowo.
*O ni oun o fara mo siso ede Yoruba nile igbimo asofin
Onarebu Jude Idimogu, okan lara awon omo ile igbimo asofin ipinle Eko, ti tako aba ile lati maa lo ede Yoruba pombele gege bi ona ibanisoro nigba ti ile ba joko lati jiroro.

O ni sise amulo ede Yoruba dabi igba ti won dogbon ati di rikisi eleyii ti ko dara to fun ijoba awaarawa. ” A ni ede ajumolo, ede Geesi, kilode ti a fi ni ko ye ni lilo mo o?”- Idimogu

Omo ipinle Imo ni Odimogu, oun si lo n soju ekun keji Oshodi/Isolo nile igbimo asofin ipinle Eko labe egbe oselu PDP.

Oun kan naa si ni omo yibo akoko ti o joko nile igbimo asofin ipinle Eko gege bi onarebu.
Olayemi Olatilewa, okan ninu awon akoroyin IROYIN OWURO jade lo lati mo ero awon eniyan nipa isele yii. Ohun to mu bo ni yii:

Bayo Sola: Aba lati maa lo ede Yoruba nile igbimo ki i se tuntun, ki lode ti maanu naa n tako o?

Chidinma Amaeshia: Ti o ba ti n lo si ile igbimo asofin, eni ko mu eniyan ti yoo ma ba se ayan ogbufo da ni.

Franklin Egbuche: Ona meji lo pin si. Eniyan ko le soju awon eniyan to yato silu eni lai se wi pe eniyan gbo ede won lojulowo. Agbegbe ti eniyan yoo ba soju, dandan ni ko gbo ede won daada.

Apa keji, abala ofin kan so wi pe ede ajumolo, ede geesi, ni ede kan ti igbimo yoo maa lo lati fi daba ofin. Bi o tile je wi pe ile igbimo asofin ipinle le se ipinnu ti won, sibesibe ohun to fin so ni yen.

Bayo Akinola: Oro lo fe gbo, omo atiro to ra bata ranse sile si iya re. Imado i ba se bi elede a balu je…Aifini peni, aifeeyan peeyan ti n mu ara oko san bante wolu.

Ugo Stevenson: Awon ipinle ni eto labe ofin lati se ifilole ofin ti won. Sugbon ipinle bi Eko to je ipinle to kun fun aimoye eya ko gbodo maa lo agbara kan-anpa nipa sise amulo ede kan lati fi bori ede mii.

Uzo Chikere: Yoruba ni iyawo Idimogu, oun gan-an si le so Yoruba to ja geere. Kini isoro re gan-an?

Yato si ipinle Eko, a gbo wi pe awon ipinle kan ni apa Ila-oorun Guusu ile Naijiria naa ti n daba ati maa lo ede yibo gege bi ona ibanisoro ni awon ile igbimo asofin won.

Orisun: http://www.olayemioniroyin.com/

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Tinubu, má dàá sí ọ̀rọ̀ ìdìbò gómìnà Edo–PDP kìlọ̀

Tinubu, má dàá sí ọ̀rọ̀ ìdìbò gómìnà Edo–PDP kìlọ̀ Ṣé látàrí a á sìnlú a à sìnlú yìí náà lọ̀rọ̀ wá di fàá ká já a báyìí, tí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ń jùkò ọ̀rọ̀ lu ra wọn.Nífèsì padà sí n tí aṣíwájú Tinubu ṣọ , ẹgbẹ́ òṣèlú “Peoples Democratic Party,PDP ” náà tí fèsì padà fún Aṣíwájú Bola Ahmed Tinubu lórí fídíò tó ti ní kí àwọn èèyàn Edo má ṣe dìbò fún Godwin Obaseki. Gómìnà Godwin Obaseki ni olùdíje ...