Home / Àṣà Oòduà / Oselu ipinle Oyo: Alao Akala ti wa ogbon mii da

Oselu ipinle Oyo: Alao Akala ti wa ogbon mii da

Christopher Alao Akala ti wa ogbon mii da
Nibayii ti Christopher Alao-Akala, eni odun marunlelogota (65) ti pinnu lati darapo mo egbe APC lati inu egbe Labour Party ni awon awuyewuye kan ti bere si ni jeyo jade.

Lara awon oro ti a gbo ni wi pe awon omo egbe APC ti ipinle Oyo ko fi taratara dunnu si igbese tuntun yii. Ero won ni wi pe Akala, eni ti awon kan tun pe ni omo Iya Alaro fe wa fi buredi ko won lomi obe je lasan ni.

Nigba ti awon kan tun wi pe nigba ti obe dun, to jina tan ni Akala n sare bo wa lati wa kore ise owo awon.

Gege bi Kola Balogun, oludari egbe ti n polongo ibo fun Alao-Akala se so, o ni gbogbo eto lo ti to fun Akala ati awon alatileyin re nipinle Oyo lati tele e wonu egbe onigbale, APC.

Agbaoje oloselu, eni to ti fi igba kan je gomina ipinle Oyo ri, lagbo wi pe o ti n ni ipade po pelu awon oloye sankosanko lati inu egbe APC lori igbese re tuntun naa.

Gege bi oro Lukman Agboluaje, okan ninu awon omo egbe kan ti n se atileyin fun Alao-Akala, Destiny group, naa je ko ye gbogbo aye wi pe, ibikibi ti Akala ba lo lawon setan lati tele lo. Lara awon to peju sibi ipade naa ni Honourable Tajudeen Abisodun, Dr. Adetunji Gbola, Senator Brimo Yusuf, Dr Kola Balogun, Alhaji Omilabu Ghandi, ati awon kan-anrinkan-anrin lagbo oselu ipinle Oyo.

Sugbon gege bi oro Kehinde Ayoola, olori ile igbimo asofin ipinle Oyo nigba kan ri, okunrin naa gba wi pe ogbon ati dije fun ipo gomina lodun 2019 ni Akala n da. Bakan naa lo fi kun un wi pe ko si ohun to buru ti Akala ba ni i lero lati dije nitori eto re ni. Sugbon bi o se rorun fun ala re lati wa si imuse gan-an ni ko daju.

Alao Akala to ti fi igba kan je alaga ijoba ibile Ariwa Ogbomoso labe egbe oselu All Peoples Party (APP) laaarin odun 1999 si 2002 darapo mo egbe PDP lodun 2003. Eleyii ti won si pada yan-an gege bi igbakeji gomina eleyii ti ara ilu pada dibo yan sipo.

Akala bo si ipo gomina leyin rugudu to waye laaarin Lamidi Adedubu ati Rasheed Adewolu Ladoja to je gomina igba naa. Won yo Ladoja loye lojo kejila osu kini odun 2006 eleyii to fun Akala lanfaani lati bo si ori aga isakoso ipinle Oyo gege bi gomina.

Leyin eyi ni won tun pada dibo yan Akala si ipo gomina laaarin odun 2007 si 2011.

Leyin iku Adedubu, PDP ko gba Akala mo latari orisiirisii wahala ti n fi joojumo je jade. Eleyii lo mu wo inu egbe Labour Party.

Ninu egbe yii naa lo si ti dije fun ipo gomina ipinle Oyo lodun 2015 sugbon ti apapo iye ibo re ko si gbe e leke idibo naa.

Gege bi alaye awon onwoye nipa oro oselu se so, nibayii ti Alao-Akala ti setan lati darapo mo egbe APC, lara awon pataki omo egbe ati alatileyin fun egbe APC ipinle Oyo ti Akala yoo ba nikale l’Oba Lamidi Adeyemi III, Alaafin tiluu Oyo.

Ti e ko ba si gbagbe, ni awon akoko ti Alao-Akala wa lori oye gege bi gomina lo tako bi won se fi alaafin Oyo je alaga igbimo lobaloba ipinle Oyo gege bi oye ajegbe.

Akala so wi pe iru oye alaga igbimo lobaloba naa lo ye ko je oye ti won yoo ma pin je laaarin awon oba. O si daba ki won pin oye alaga awon lobaloba ipinle naa laaarin Olubadan tile Ibadan, Soun tiluu Ogbomoso ati Alaafin tiluu Oyo.

Bi o tile je wi pe awon omo ile igbimo asofin ko fara mo aba naa, eleyii ti ko si mu ero Akala wa si imuse. Sugbon aarin Akala ati Oosa ilu Oyo ko pada gunrege mo lati igba naa wa.

 

Orisun

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*