Home / Àṣà Oòduà / Yẹ Kí Nàìjíríà Dín Iye Àwọn Sẹ́nétọ̀ Tó Ń Ṣojú Wọn Kù Tàbi, Ka Kúkú Pa Ipò Náà Rẹ́ – Fayemi

Yẹ Kí Nàìjíríà Dín Iye Àwọn Sẹ́nétọ̀ Tó Ń Ṣojú Wọn Kù Tàbi, Ka Kúkú Pa Ipò Náà Rẹ́ – Fayemi

Ó yẹ kí Nàìjíríà dín iye àwọn Sẹ́nétọ̀ tó ń ṣojú wọn kù tàbi, ka kúkú pa ipò náà rẹ́ …..Gomina ìpínlẹ̀ Ekiti

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ó ní àwọn sẹ́nétọ̀ tí ń náwó tó pọ̀jù léyìí tí Ìjọba yí le fi owó náà ṣe nǹkan mìíràn fáwọn ará ìlú.
Ó gba Ìjọba nímọ̀ran láti ṣàmúlò àbọ ìwádìí àwọn ìgbìmọ̀ Orosaye Stephen.
Àbọ ìwádìí Orosaye ni pé kí wọ́n da àwọn iléeṣẹ́ Ìjọba àpapọ̀ tí iṣẹ́ wọ́n jọra pọ̀ di ọ̀kan ṣoṣo kí wọ́n le gbòòrò síi
Fayẹmi gba u ìmọ̀ran yìí lásìkò tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi àpérò lórí ètò ọrọ ajé Nàìjíríà ẹlẹẹkẹdọgbọn irúu rẹ̀ tí àkòrí rẹ̀ jẹ́: Nàìjíríà ni 2050: kín ló kù ní ṣíṣẹ yàtọ̀?

Ṣaájú ni gómìnà ìpínlẹ̀ Imo tẹ́lẹ̀, Rochas Okorocha tí kọ́kọ́ ní kí wọ́n dín o òdiwọ̀n iye àwọn aṣojúṣòfin kù nílé Ìjọba ní Abuja.
Rochas ní sẹ́nétọ̀ tó ń ṣojú ìwọ̀ oórùn ìpínlẹ̀ Imo báyìí nílé ìgbìmọ̀ ìjókòó kẹsan an.
Ó ní iye owó tí sẹ́nétọ̀ kọ̀ọ̀kan ń ná tí pọ̀jù lọ́júu t’òun àti pé ó yẹ k’íjọba dín wọn kù sí ẹyọ kan láti ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan dípò o mẹ́ta yìí.
Lọ́wọ́lọ́wọ́ ni Nàìjíríà, àwọn aṣojú jẹ́ mọkandinlaadọfa nílé ìgbìmọ aṣòfin àgbà nílùú Abuja láti ipinlẹ mẹrindinlogoji àti Olúùlú FCT.
Nígbà tí àwọn aṣojúṣòfin jẹ́ ọtalelọọdunrun nílé ìgbìmọ aṣojúṣòfin kékeré ní Abuja.
Nínú àbá eto ìṣúná tuntun tọdún 2020 ti Ìjọba àpapọ̀ gbé wá síwájú ilé láìpẹ́ yìí ló ṣafihan pé biliọnu mẹẹdọgbọn le ní ọgọrun un ni àwọn aṣojú wọ̀nyí yóò ná tán. Okorocha
Gomina Fayemi ni oun ko ro pe ọrọ Nàìjíríà nilo aduro ero yii lati maa na owo ti wọn n na tan loṣooṣu ki a to lè yanju iṣorọ Naijiria.
O ni awọn aṣojúṣòfin la nilo lati ṣe agbẹkalẹ awọn ofin to yẹ ni Nàìjíríà kìí ṣe àwọn sẹ́nétọ̀ rara.

Fayẹmi fi ìpínlẹ̀ Ekiti rẹ̀ ṣe àpẹrẹ pé kínni sẹ́nétọ̀ mẹta ń ṣe láti Ekiti kékeré yẹn kí á tó sọ àwọn ìpínlẹ̀ tí kò tún tóbi tó Ekiti.

About ayangalu

x

Check Also

IGP usman

Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá Ìròyìn òkèrè, bí ò lé, a dín.Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣàlàyé bí ìdigunjalè kan tí ìròyìn sọ pé ó gba ẹ̀mí èèyàn kan ṣe wáyé ní ọjà Bódìjà nílùú Ìbàdàn. Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Adéwálé Òṣífẹ̀sọ̀, sọ nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún pé lọ́jọ́ ẹtì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Ó ní arákùnrin kan, Abubakar Ibrahim, ni àwọn adigunjalè kọlù ní nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n sì yìnbọn mọ́ ọ kí wọ́n ...