Home / Àṣà Oòduà / Yunifasiti ijo Mountain of Fire yoo bere eko kiko lojo Monde

Yunifasiti ijo Mountain of Fire yoo bere eko kiko lojo Monde

Gbogbo eto ti to bayii fun ileewe giga ti ijo Mountain of Fire and Miracles Ministries (MFM) eleyii ti won pe ni Mountain Top University lati bere eko kiko fun awon akekoo lojo Monde ose yii, 21/12/15.

Eto ibere eko kiko ifafiti tuntun yii ni yoo bere pelu ayeye igbaniwole awon akekoo eleyii ti yoo waye lojo Monde kan naa.   Ikede tuntun yii lo jade lenu oga agba fun ile iwe naa, Ojogbon Elijah Ayolabi, nigba ti n ba awon oniroyin soro.

Gege bi akojopo iroyin Olayemi Oniroyin, Ojogbon Ayolabi ni awon akekoo bi aadorinlerugba (270) ni awon yoo maa se ayeye igbawole fun lojo Aje to n bo yii. Eleyii ti won si maa gba won si elekajeka abala eko kiko to wa ninu ogba ileewe tuntun naa.

Yato si eleyii, lara ayeye ti yoo tun waye ni sisi gbongan nla kan to wa ninu ogba MFM Prayer City, Kilometre 12, Masose Eko-Ibadan, Ibafo.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo