Tag: Àṣà Yorùbá
-
ÌȘẸLẸ̀ INÁ NÍ BÁGÀ
Hàáààà!!! Iná ooooooo. Iná pupa bẹ́lẹ́ńjẹ́. Bẹ́lẹ́ńjẹ́ bẹ̀lẹ̀ǹjẹ̀ bẹ́lẹ́ńjẹ́. Bẹ́lẹ́ńjẹ́ pupa arańta. Iná gorí òrùlé tán; Ó wá fẹjú kẹkẹẹkẹ. Ìpínlẹ̀ Èkó gb’àlejò iná ńlá. L’ágbègbè Òjòdú Bágà. Ó kọjá ohun a le máa f’ẹnu sọ. Iná ṣe bẹ́ẹ̀, ó búrẹ́kẹ́. Iná ńlá ọmọ ọ̀rara. Lónìí ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oșù kẹfà, Ọjọ́ burúkú Èșù gb’omi mu.…
-
Ó mà se ooo
Àfi kí olórun, elédùmarè gbà wá lówó ikú òjijì ní orílè èdè Nìjíríà. Kí tún ní eléyìí báyìí olúwa gbà wà, e wo òkú òpò nílè bí won se jó ná tán à kí olórun gbà wá wo.
-
Tánkà tí Ó gbiná ní ànà tí Ó sì pa òpò èèyàn.
Ní déédé agogo márùn-ún ìròlé àná ni ìjàmbá ńlá tí Ó tún jé mánigbàgbé fún orílè èdè Nìjíríà selè, nígbà tí Tánkà ńlá kan gbiná ní ojú pópó ònà tí ó wà láàrin ìlú Èkó si Ìbàdàn. Òpò àwon èèyàn ni ókú tí àwon kan sì fi ara pa, ti Òpò okò sì sègbé. Ó…
-
Nìjíríà ìgbà wo ni a ó gba òmínira.
Nìjíríà ńlé sunkún Àwon èèyàn ibè ò ye é rérìn-ín òfò Èrín òfò tí won rò pé ti ìdùnú ní se Nìjíríà ìlú tí òmínira rè ti di omi ìnirà Atún ti wálé Ojó wo ni àwa náà yóò gba ife gbogbo àgbáyé Ó mà se o! Argentina tún ko bò wá láàná, won tún…
-
A DÚPẸ́ OOO GBOGBO ILẸ̀ WA TI DI IBOJÌ
A dúpẹ́ o Ikú ti di tiwa A dúpẹ́ o Àwọn èèyàn wa ò figi da mààlúù mọ́ AK 47 ni wọ́n ń lò A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Iṣẹ́ darandaran ti di iṣẹ́ dánràndáràn Èdùmàrè a dúpẹ́ o Ẹ dúró ná Kí loun tá a ṣe Tí gbogbo ilé wa kún fún ikú Tí gbogbo…
-
Àbíkéyìn gbajúgbajà olórin tí a mò sí D’banj ni a gbó wípé Ó kú sí omi ní àná.
omokùnrin gbajúgbajà olórin tí a mò sí D’banj tí orúko omo náà ń jé Daniel ni a gbó wípé Ó kú sí omi ní àná tí a mò sí ojó kerìnlélógún osù kerin odún yii. Kí olúwa kí ó bá wa rò wón lókàn.
-
Rántí òla
Ohun tí a se lónìí Ìtàn ni b’ódòla Lisabi Agbongbo Àkàlà Fi ìwà akin gba gbogbo Ègbá kalè L’óko erú Olóòyó Ògèdèngbé ń be nínú ìwé ìtàn ìjeshà Asíwájú rere ní se Moremi obìnrinkùnrin n’ífè ńkó, a kò le gbàgbé rè láéláé Efunroye Tinubu l’égbàá ilé ńkó, obìnrin ogun tí Ó so àwon òyìnbó d’òdè…
-
Ọ̀YÀYÀ (CHEERFULNESS)
Èro àlọ, Ẹ wá gbọ́, èrò àbọ̀, Ẹ wá tẹ́tí sími Oògùn ọlá tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ní mo fẹ́ wí f’áyé Oògùn ọrọ̀ tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà ní mo fẹ́ ròyìn Àtọjọ́ mo ti dáyé, Àtọjọ́ mo ti ń ṣiṣẹ́ Àtòjọ mo ti ń dààmú sáré kiri Èmi ò mọ̀ pé oògùn ọlá kan…
-
Ìgbà èdá
Ìgbà kò lo bí òréré Ayé kò lo bí òpá ìbon, Ìgbà kan ńlo Ìgbà kan ńbo Kí elédùmarè jé kí á n’ígbà tó dára n’ílé ayé wa Ìgbà kan ni ogún náírà yí níyì púpò Sùgbón nísìnín Ó ti di ohun tí èèyàn ò fé rí mo. Ìgbà rere ni kí á ma toro…