Home / Idile Gisiti / Ó San Owó Ilé Ìwé Mi Títí Mo Fi Jáde, Ṣùgbọ́n Mo Fi Májèlé San!
ojo keji

Ó San Owó Ilé Ìwé Mi Títí Mo Fi Jáde, Ṣùgbọ́n Mo Fi Májèlé San!

Àti ilé ìwé e gírámà ni èmi àti Kọ́lá ti jọ ń fẹ́ ra wa. Àwọn òbí i mi ò kí ń fẹ́ rí Kọ́lá pẹ̀lú u mi nítorí ààfín ni. Nígbà tí mo fẹ́ wo ile ìwé gíga ni bàbá à mi ní àìsàn an rọ́pá, rọsẹ̀,ọpẹ́lọpẹ́ kọ́lá tó san owó ilé ìwé è mi láti ìgbà tí mo wolé ẹ̀kọ́ gíga títí mo fi jádé.

Nígbà ti mo lọ ṣe agùnbánirọ̀ mo pàdé sẹ́nátọ kán,èmi àti ẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe wọléwọ̀de.
Sẹ́nátọ̀ ra ilé fún mi, ó tún, tún ilé àwọn òbí ì mi kọ́.

Mi ò fi ọ̀rọ̀ ọ kọ́lá pamọ́ fún sẹ́nátọ̀, ṣẹ́nátọ̀ fún mi ni mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dógún pé kí n lọ fún Kọ́lá kó fi ṣe owó tó fi rán mi lọ ilé ìwé, Kọ́lá fárígá, ó ní dándán ni ki òun fẹ́ mi.
Lọ́jọ́ mò mí n mọ̀ọ́ èmí àti sẹ́nátọ̀, Kọ́lá kọ́ àwọn jàndúkú wà ilé e wà láti wá da ayẹyẹ náà rù ṣùgbọ́n àwọn ṣọ́jà fí imú u wọn dánrin.

Ní ọjọ́ kejì tí mo ṣe mò mí n mọ̀ọ́, mo wá Kọ́lá lọlé ,mo bẹ̀ẹ́, mo purọ́ fún pé, mo kàn n fẹ́ ṣẹ́nátọ̀ láti fi gbá owó ọwọ́ ẹ̀ ni kí èmi àti ẹ̀ lè dìjọ kúrò nínú u ìṣẹ́ àti òṣì. Lẹ́yìn náà ni mo gbé ẹ̀fọ́ rírọ̀ àti sèmó ti mo ti fi májèlé sí fún Kọ́lá. Lẹ́yìn ọ̀ṣè mẹ́jì ni májèlé tí mo fún Kọ́lá jẹ yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́.

Ọjọ́ kejì tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀ ni mo kó ẹrù mí ti mo gbá ọ̀dọ̀ sẹ́nátọ̀ lọ nílùú Àbújá.

© Omidan Yoòbá …

About asatiwa

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

sunday igboho

Iru Ekun: Sunday Igboho ti kéde o!

Sunday Igboho, ti kéde rẹ̀ fún gbogbo ọmọ Yorùbá pé ìforúkọsílẹ̀ láti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àbò “Iru Ekun Security Network” jẹ́ ọ̀fẹ́ ti kò sì ní ná kọ́bọ̀ kankan fún ẹnikẹ́ni tó fẹ́ yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún àbò ilẹ̀ baba rẹ̀. Nínú àlàyé tuntun tí wọ́n ṣe fún àwọn kòòdínétọ̀, Ìgbòho sọ pé wọn kò gba owó kankan lọ́wọ́ ará ìlú fún fọ́ọ̀mù nítorí pé iṣẹ́ náà jẹ́ ti ìfẹ́ orílẹ̀-èdè àti ààbò gbogbo ilẹ̀ Yorùbá láti dènà àwọn ...