Home / Naija Gisiti / Àwọn Ìyàwó Bàbá

Àwọn Ìyàwó Bàbá

Ìyàwó méjì ni bàbá mi fẹ́ àwọn ìyàwó méjèèjì ló sì ti papòdà. Èmi nìkan ni ìyá mi bí fún bàbá mi, mo ní àwọn 🧑‍🧑‍🧒‍🧒🧑‍🧑‍🧒‍🧒🧑‍🧑‍🧒‍🧒 ọbàkan mẹ́fà.Èmi ni àkọ́bí.

L ẹ́yìn Oṣù mẹ́fà ti bàbá a wa kú🪦 , àwọn àbúrò mi gbé ilé è 🏘️ bàbá a wa tà láì sọ fún mi.

Mo gbà owó èlé ni Ilé-ìfowópamọ́🏦 tí mo ti ń ṣiṣẹ́ mo ra ilé náà padà lọ́wọ́ ẹni to ràá. Àwọn àbúrò mi

ná owó titi wọn ní ìnákúnàá🥂🍾💃🚘🚖🥂

Lẹ́yìn ọdún kan, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní bẹ̀ mí pé kí n gbà àwọn sílé. Kò sẹ́ni tí wọn ò rán sí mi. Mo dé láti ibi iṣẹ́ lálẹ́ ọjọ́ kan ni mo bá Olórí ẹbí àti àwọn àbúrò mí nínú ilé ti wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní bẹ̀ mi pé kí n gba àwọn padà sílè.

Tó bá jẹ́ ẹ̀yin ni ṣe ẹ lè gbà wọ́n?

© Omidan Yoòbá …

About asatiwa

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Mercy Johnson Kìlọ̀ Gidi

😳 Mercy Johnson Kìlọ̀ Gidi: “Ọ̀rọ̀ Ọkọ àti Aya, Ẹ Jẹ́ Kí Wọ́n Yanjú Rẹ̀ Fúnra Wọn!”

“Ọ̀rọ̀ ọkọ àti aya tàbí ohunkóhun tó bá kan ìfẹ́, ẹ má ṣe dá sí i, ẹ má ṣe gbìmọ̀, ẹ má sì ṣe ran wọn lọ́wọ́. Wọ́n ti lò mí láti yanju ọ̀rọ̀ wọn.” Mercy Johnson, ẹni tí Regina Daniels ń pè ní Iya Isale(Godmother) rẹ̀, ti dá àwọn ènìyàn lójú lórí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí tí ó ń tàn káàkiri lórí social media. Àwọn olólùfẹ́ Regina ti ń so ọ̀rọ̀ tí Mercy so yìí pọ̀ mọ́ àwọn ìròyìn àti ...