Mo layo lati so fun yin wipe oni ni ojo ibi mama wa Omolola Adex ti won je okan gboogi ninu ebi Omo Yoruba Atata.
Maami Olojo ibi a ki yin e ku ayo oni, e o se pupo re laye ninu alafia ara ati ibale okan. E o ni ba won na oja warawara nile aye beeni e o si ni dagba yeye, gbogbo ohun rere ti n mu’le aye rorun fun eda ni Eledua yoo fi jinki yin. E o gbo, e o to, e o fewu pari, e o ferigi jobi, e o gbele aye sohun rere bi o ti wa wu ki e pe to laye e o ni f’oju mo saare omo lase Eledumare.
Kabiyesi ati awon Oloye ati gbogbo ebi Omo Yoruba Atata pata nileloko nki yin wipe IGBA ODUN, ODUN KAN NI O..
Category: Àṣà Oòduà
Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.
-
Olojo Ibi Ti Oni
-
Ire ni mo ko
Ire ni mo ji ri
Ire tororo d’ori awa o
Ire toorun ogberi o mo o
AaseIyaOgbe OmoEdu Yeyelufe Oyewole
-
Odu ifa IROSUN OPINNI/ IROSUN ORO
| |
| |
| | | |
| | |Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, gegebi oni se je ojo isegun olorun alagbara yio muwa bori Ogun ota ase.
Odu ifa IROSUN OPINNI/ IROSUN ORO lo gate laaro yi, ifa yi gba eniti odu yi ba jade si niyanju wipe ki o rubo daradara nitori aarin ota Omo araye lo wa, ifa ni won maa jowu re beeni won si maa se inunibini si sugbon nipa etutu yio segun won.Ifa naa ki bayi wipe: irosun reterete babalawo oro difa fun oro lojo ti oro nbe laarin ota Omo araye won ni ki o karale ki o rubo ki o baa le segun won, ki o baa si le di eni nla nibikibi yio wu ki won gbe lo si, obi meji, obuko, epo pupa, iyo oro kabomora o rubo esu si gba ebo re nigba kutukutu iwase inu ira ni oro wa seni omo araye se inunibini re ti won si si kuro nibe ti won gbe lo sori apata, nigbati o tun dori apata seni esu odara lo gba yepe sidi re bee lo tun ntobi esu odara wa ki egugun obuko ti oro fi rubo si lara o sin da iyo si lara, oro wa bere sini tobi, beeni inu tun bi awon ota won tun sope won maa si oro kuro lori apata to wa yen ibiti won ti lo nge oro seni oje igi oro ta siwon loju, seni oju wa ntawon bi won se salo niyen o lati ojo naa ni oro ti segun awon ota re oro wa njo o nyo o nyin awo awon awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju ko pe ko jina ifa wa bami larusegun arusegun ni a nba awo lese obarisa.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe ibiti o wu ki awon ota da ori wa ko ao se rere nibe, ota kota to ba sope oun fe ge wa kuro lori ile yio fo loju lesekese ao si se gbogbo ogun awon ota to dojukowa o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.English Version:
Good morning my people, how was your night? Hope you slept soundly, as today is Tuesday, a victory’s day may almighty father help us to conquer the power of our enemies ase .
It is IROSUN OPINNI/ IROSUN ORO corpus that revealed this morning, ifa advised whoever this corpus revealed out for that he/she should offer sacrifice because of the war of enemies, ifa said there would be a jealous from enemies because of his/her prosperity and those enemies will want to trying to kill him/her.Hear what the corpus said: Irosun reterete the priest of oro plant cast divined for oro plant when oro was at the midst of enemies, oro was advised to offer sacrifice so that whatever enemy do to it, it will prosper, two kola nuts, he-goat, salt, palm oil and oro complied, oro was located at swamp area before and it was very big but the enemies persecuted it they shift oro from its position to the surface of rock, when oro reached the surface of rock esu odara has eating its sacrifice and he put sand to the bottom of oro plant and oro started germinating esu odara put the bone of he-goat that oro offered as a sacrifice on its body and he also put salt too to its body, when enemies saw that oro has became big they went there with cutlass to cut it off, when they cut it the water of oro splashed into their eyes and it was very peppery they shouted and they ran away, that is how oro plant conquered its enemies oro started dancing and rejoicing praising priest the priests were praising ifa while ifa was praising God.
My people, I pray this morning that wherever enemy plan to shift us to,we shall succeed there and prosper, and enemy that want to trying to cut us down will become blind immediately and we shall conquer all the wars that enemy is waging against us amen.
Faniyi David Osagbami
-
Iwure owuro 26.07.2016
*Aje ko ni di ota a mi.
*Edumare dakun fidi aje sole nile mi.
*Imo ota, imo elenini ko ni se lori mi.
*Emi ko ni di eni arisa ati arisunkun.
*Edumare fi aso iyi wo mi(Ase).Aare Olasunkanmi Alani Agbasaga
-
Ore yeye Osun!
May we all be blessed today and beyond.
Ore yeye Osun!Take it to the river.
Ore yeye Osun! – – –
-
Iyawo tagbe wani ojo aiku mati soro, egbo bose wi
Olotu: ekasan ooo eyin ara ile,asiku asiko yin, eledua yowa pelu gbogbo wa o,ase. Iyawo tagbe wani ojo aiku mati soro egbo bose wic….Gbogbo eyin ebi mofe ki e fi ise yin bura fun mi pe ti moba so e ni lemi jade ni ile oko mi,e sini jeki iya oko mi wa gbe ile wa.
Olotu:arabinrin yin wipe awon ebi mase,leyin re lotun tesiwaju pe….Se eri emi te woyi mi o ki se eyan lasan,eranko igbo ni mi,se e wari iya ti e woyi babalawo kan ti sofun iya yi wipe oko mi loma seku pa,inu iya nan baje tori ninu gbogbo omo tobi oko mi lo feran ju,iya yi bere pe kini oun lese si,baba nan wipe kosi ikan tole sesi afi toba le koko pa omo nan,tori iya yi nan lopa iya re.Asiko esan si tide,leyin opolopo ironu ni iya yi gba lati se,idi niyi ti o fi fe magbe lodo wa.
Olotu;too,eyin ara ile oro leti gbo lenu iyawo yi,kini ki awon ebi se ?,iwo ti o baje abiyamon gidi fi owo di ori remu,koni oloun mafun mini omo ti yo pami,masi fun mi ni iya ti yo pami.Iwo odo wipe eledua maje siyan.Ire ooooooo -
Odu ifa IROSUN ATAPO – Faniyi David Osagbami
| |
| |
| | |
| | | |Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, bi a se njade lo laaro yi pelu ayo ati alaafia a koni pada sile pelu ibanuje o ase.
Odu ifa IROSUN ATAPO lo gate laaro yi, ifa yi fore fun akapo ti odu ifa yi ba jade si, ifa ni inu ise ati iya ni akapo yi wa sugbon ifa ni oun yio mu kuro nibe oun yio si mulo sinu oro, sugbon ifa yi kilo gidigidi fun akapo yi ki o mase silekun aseju leyin ti aye re bati wa dara tan ti o ti ni laari ki o ma baa pada sinu osi ati iya to wa tele.
Ifa naa ki bayi wipe: Orunmila ni gbongbo ta gongo dina a difa fun olobahun lojo ti o nbe ninu ise oun iya ijahanjahan igi oko ti won ni ki o karale ebo ni ki o wa se ki o baa le kuro ninu Iya to ngbe ki o ba le di olowo oloro sugbon won kin nilo wipe ti o bati di olowo oloro tan ki o mase silekun aseju o olobahun loun ti gbo , obi meji, eyele funfun, ekuru funfun, adiye funfun, otin olobahun rubo won si se sise ifa fun ko pe ko jina seni olobahun ba ara re ninu ile nla tokun fun gbogbo nkan meremere inu olobahun dun olobahun dolowo o doloro, selo di bi ojo melo kan sii seni olobahun ri lekun kan ninu ile to wa yen olobahun wa ndaro wipe ti oun ba silekun yi bayi boya oun a tie tun di oloro ju bayi lo seni olobahun lo silekun nigbati o maa wonu yara naa selo ba opolopo nkan meremere ile aye nibe to tun poju ti ibiti o wa tele lo o wa nwo OLOKUN to joko soju Omi, OLOKUN wa sope olobahun! Sebi won kilo fun e wipe ki o mase silekun aseju, olobahun wa bere sini be OLOKUN wipe ki o ma binu soun OLOKUN ba gba ipe olobahun o si lo olobahun wa bere aye iwo re jije o ni gbogbo oro ile aye patapata, ko tun pe ti olobahun tun ri lekun miran ninu yara to wa yen, bo se tun da ngbimoran niyen wipe ah! Oun tun maa silekun yi o oni inu Ibe gan ni oro ile aye maa pin si, bi olobahun se silekun niyen o to maa wole sinu yara bayi se lo ba ara re ninu apalapolo igi oko ti ibe se kiki idoti ati egbin pelu ijahanjanhan isepe igi olobahun bere sini da ara re lebi bi olobahun se pada sinu osi ayeraye niyen o, o wa bere sini nyin babalawo re layin sodi nje ko pe ko jina eyin ko wa rifa ojohun bo ti nse ifa de alase ebora abise ope abise wara.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe eledumare yio muwa kuro ninu ise ayeraye yio muwa wonu oro, ori wa yio gbewa dele olokun seni ade, ako ni siwawu ojukokoro ati aigbonran koni muwa pada sinu osi ayeraye o, eti wa koni di si ibawi o aaaseee.English Version:
Good morning my people, how was your night? Hope it was fantastic, I pray as we are going out this morning with peace and joy, we shall not return back home with sadness ase.
It is IROSUN ATAPO corpus that revealed this morning, ifa foresee goodness for whoever this corpus revealed out for, ifa said this person will be take out of suffering life and put him/her in a good and treasury abode, ifa also warn this person not to misbehave whenever he/she is living fine so that he/she won’t go back into his/her wretch life.
Hear what the corpus said: Orunmila said the root spread buckled on the road it cast divined for tortoise when he was advised not to open a misbehaving door, this tortoise was living in poverty then and he was asked to offer sacrifice so that he could excel and became rich but he was warned not to misbehave when he become rich, two kola nuts, White hen, white pigeon, ekuru funfun, gin and he complied, suddenly tortoise just saw himself in a beautiful place that full up of treasure and he was so happy and started enjoying, when it was some days he found out there is another door inside the beautiful place that he was living and he was meditating that if he could open the door maybe he would be more wealthy than this, so he opened the door and he entered there and he found plenty things that is more than where he was living and he saw “OLOKUN” sitting on the top of ocean saying tortoise! And you have been warned not to open a misbehaving door, tortoise begged her not to be angry with him and OLOKUN accepted and she went away tortoise became rich plentifully he started enjoying a great life, in a few days he found another door in the treasury room and he also meditating as before that this place would be a very great place than where he has been living so far, tortoise had forgotten the warnings he opened the door again when he will entered the room he found himself in a corner of tree that full of dirty and dried stems of tree than where he was living when he was still wretched, tortoise was started blaming himself, this is how covetousness and misbehaving led tortoise back to wretched life.
My people, I pray this morning that God will take us from wretch home to treasury home, our head will lead us to house of OLOKUN and we shall never misbehave to return back to wretched life, our ears will never block to warnings ase.
ABORU ABOYE OOO.Faniyi David Osagbami
-
Iba Bambi Oluorojo arigba ota segun!
Arira mase fi ina re na mi o!
Aase!
A ku Ose Sango!Cc- IyaOgbe OmoEdu Yeyelufe Oyewole
-
Abi e roju aye bi?
Orewa nso fun ara ile wipe ki won
Ba oun gbe orin, sugbon won o da loun, lo ba binu lo
Si oko o da orin sugbon won o fun lounje, o tun lo si
Odo o da orin won o je ko we(bath) beni won o fun ni
Omi mu, o wa pada sinu ile o n sofun ara ile wipe se
Eo gbe orin a bi eo gbe orin? Orewa bi orin o ba fie
Si le boya kofi orin sile koye tan arare je. Toripe
Yoruba bo won ni, bi eniyan ba ‘ko orin ti
Orin nan ko dun sebi oun nan f’eti arare
Gbo. Orewa itumo asamo mi nipe iwa wo lon wu tofi
Je pe aye o gba tie nibi gbogbo? O ya fura ko ronu
Pi’wada ki ojo to lo, toripe aye yi o lo bi opa-
Ibon. Ibi araye ko oju si awa o ni ko eyin si.
Oju-itere ojulowo omo ooduarere