Category: Iroyin Pajawiri

  • Ọ̀ọ̀ni lfẹ̀ wọ ilédì fún ọdún ọlọ́jọ́

    Ọ̀ọ̀ni lfẹ̀ wọ ilédì fún ọdún ọlọ́jọ́

    Ọ̀ọ̀ni lfẹ̀ wọ ilédì fún ọdún ọlọ́jọ́

    Bí a bá ń ṣọ̀rọ̀ ọ̀nà, yóó sòro púpọ̀ kí á tó yọ tí ẹsẹ̀ kúrò.
    Bí a bá sì ń ṣọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀ṣe, òpó kan jàǹràn ni ilé Ifẹ̀ níbi tí ó ti jẹ́ pé ọdọọdún ni ọdún Ọlọ́jọ́ máa ń wáyé fún gbogbo ọmọ káàárọ̀ , o jíire paàpá àwọn ọmọ Ilé Ifẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá.

    Gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn ọ́ lọ́dọọdún, Ọba Ogunwusi ni yóó kọ́kọ́ ṣíde nípa wíwọ Ilé Oòduà kí ó tó wọ adé Aare láti jẹ́ kí ayẹyẹ náà bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu.

    Lẹ́yìn náà ni ayẹyẹ tí wọ́n ń pè ní Gbajure yóó wáyé káàkiri àwọn ojuko kan ní ìlú Ifẹ̀, tí àwọn aráàlú yóó sì maa tẹ̀lé wọn káàkiri láti ṣe àjọyọ̀ náà.

    Bákan náà ni Ọba Ogunwusi yóó gbàlejò àwọn tó ẹlẹ́ṣìn Ògún, Sàngó àti Ọ̀ṣun ní ààfin ọba pẹ̀lú ayẹyẹ lórísirísi.

    Ní Ọjọ́ Keje tó jẹ́ kòkàárí ètò, Ọọ̀ni yóó gbàlejò ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn láti òkèèrè àti káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọn yóó wá láti bá wọn ṣe ayẹyẹ.
    Ní ọdún tó kọjá, Ààrẹ orílẹ̀-èdè-ede Nàìjíríà, Muhammadu Buhari tó péjú sí ibi ayẹyẹ àṣekágbá náà rọ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti gbogbo Adúláwọ l’ágbàáyé láti má ṣe gbàgbé ìṣẹṣe àti àṣà wọn.

    Fẹ́mi Akínṣọlá

  • Odù, Ìwòrì bogbè cast for today’s Òsè Ifá

    Odù, Ìwòrì bogbè cast for today’s Òsè Ifá

    Looking at the Odù, Ìwòrì bogbè cast for today’s Òsè Ifá, it could be said that sometimes our detractors feel they are hurting us but they don’t know they are pushing us to wealth. Just listen to this stanza from the Odù.

    Òtééré ilè ńyó
    Òtèèrè ilè ńyò
    Ilè ńyó ará iwájú
    Èrò èyìn e kíyèsí ílè
    Adífá fún Ìwòrì tí yóó tarí Ogbè sínù àbàtàbútú ajéKòìpé kòìjìnà, Ogbè ló wá jìn sínú ajé gbugburu

    Òtééré, the ground is slippery
    Òtèèrè, the ground is difficult to walk on
    The ground has made the frontline people to slip
    Those coming behind should be cautious
    Cast divination for Ìwòrì who will push Ogbè into a deep trench of treasures
    In a short time, Ogbè fell into a pit of prosperity.

    Short story- Ìwòrì betrayed his friend Ogbè as a result of envy and greediness by pushing him into a trench so that he could inherit all the profits they made in their business not knowing that it was a trench of prosperity. May our enemies push us to the land of joy.

    Happy Òsè Ifá today to you all.
    Stay blessed From Araba of Oworonsoki land Lagos Nigeria

  • Tinubu, má dàá sí ọ̀rọ̀ ìdìbò gómìnà Edo–PDP kìlọ̀

    Tinubu, má dàá sí ọ̀rọ̀ ìdìbò gómìnà Edo–PDP kìlọ̀

    Tinubu, má dàá sí ọ̀rọ̀ ìdìbò gómìnà Edo–PDP kìlọ̀

    Ṣé látàrí a á sìnlú a à sìnlú yìí náà lọ̀rọ̀ wá di fàá ká já a báyìí, tí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ń jùkò ọ̀rọ̀ lu ra wọn.
    Nífèsì padà sí n tí aṣíwájú Tinubu ṣọ , ẹgbẹ́ òṣèlú “Peoples Democratic Party,PDP ” náà tí fèsì padà fún Aṣíwájú Bola Ahmed Tinubu lórí fídíò tó ti ní kí àwọn èèyàn Edo má ṣe dìbò fún Godwin Obaseki.

    Gómìnà Godwin Obaseki ni olùdíje ẹgbẹ́ náà nínú ìdìbò Gómìnà tó ń bọ̀ lọ́nà.

    Nínú àtẹjáde tí ẹgbẹ́ náà fi síta lójú òpó abẹ́yefò Twitter, wọ́n ní ẹ̀yìnkùlé baba Tinubu kò dé Edo, nítorí náà gàlègàlè rẹ̀ tó ń ṣe nínú fídíò ọ̀hún kò le è yí ìpinnu àwọn ará ìlú Edo padà.

    Ẹgbẹ́ náà sọ pé àwọn èèyàn Edo ti pinu lọ́kàn wọn ti pẹ́ láti yan Obaseki sí ipò padà nítorí náà kí Tinubu lọ ṣa gbé jẹ́ ẹ́ mọ́wọ́.

    Yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹgbẹ́ yìí, Olùdámọ̀ràn Gómìnà Obaseki lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Crusoe Osagie sọ pé kí Tinubu dá ọ̀rọ̀ rẹ̀ padà.

    Ó ṣàlàyé pé àwọn èèyàn Edo kò fààyè gba baba ìsàlẹ̀ nínú òṣèlú ìpínlẹ̀ wọn nítorí náà kí Tinubu fàwọn lọ́rùn sílẹ̀.

    Fẹ́mi Akínṣọlá

    http://iroyinowuro.com.ng/2020/09/16/tinubu-ma-daa-si-oro-idibo-gomina-edo-pdp-kilo/
  • Òṣìṣẹ́ mẹ́rin bọ́ sí gbaga ọlọ́pàá lórí ikú ọ̀gá wọn tó rì sómi

    Òṣìṣẹ́ mẹ́rin bọ́ sí gbaga ọlọ́pàá lórí ikú ọ̀gá wọn tó rì sómi

    Ìgbákejì Ọ̀gá Àgbà iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ owó orí, Price Water Coopers , PwC Nigeria , Tola Ogundipẹ ti jáde láyé.

    Ọjọ́ Sátidé ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wá arákùnrin náà lẹ́yìn tó wọ ọkọ̀ ojú omi ní ìpínlẹ̀ Èkó.
    Ọjọ́ Àìkú ni wọ́n rí ọkọ̀ ojú omi náà, àmọ́ tí àwọn ọlọ́pàá tó ń ṣiṣẹ́ lórí omi sì rí òkú rẹ̀ ní Ọjọ́ Ajé.

    Agbẹnusọ fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nípìńlẹ̀ Èkó, Muyiwa Adejọbi sọ wí pé, lóòótọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, àwọn òṣìṣẹ́ olóògbé mẹ́rin ni àwọn ti fi ọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò.
    Ó sàlàyé wí pé, Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá nípìńlẹ̀ Èkó, Hakeem Odumosu ti pàṣẹ ìwádìí ìdákọ́ńkọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

    ” A ti gbé ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ sí ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìwà ọ̀daràn ní Yaba, nípìńlẹ̀ Èkó láti ṣe ìwádìí náà ní kíkún.”

    ”Tí ìwádìí bá parí, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá yóó fi àbájáde hàn sí gbangba.”

    Nínú ọ̀rọ̀ tí iléeṣẹ́ Price Waterhouse Coopers fi léde, Ọ̀gá àgbà pátápáta ní Nàìjíríà, Uyi Akpata sàpèjúwe Ogundipẹ tó d’olóògbé náà, gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ dójú àmì.

    Kó tó di olóògbé, Tola Ogundipe ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí adarí ẹ̀ka “PwC Africa Tax , Assurance Leader for PwC Africa” àti àwọn ipò míràn tó dìmú nínú iléeṣẹ́ PwC.

    Iléeṣẹ́’ Price Waterhouse Coopers” ní àwọn yóó fi ọjọ́ ìsìnkú rẹ̀ léde lẹ́yìn ìjíròrò pẹ̀lú àwọn ẹbí àti ará olóògbé náà.

    Fẹ́mi Akínṣọlá

  • Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn tó f’ọ́lé e MKO Abiola

    Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn tó f’ọ́lé e MKO Abiola

    Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn tó f’ọ́lé e MKO Abiola

    À ṣẹ kò sééyan táyé ò lé bá ṣọ̀tá, ó tún hàn pé wọ́n le bínú òkú ọ̀run , yàtọ̀ sèèyan tí wọ́n jọ ń wà láyé. À bí kín ní ká tí pé tàwọn kọ̀lọ̀rànsí t’ọ́wọ́
    Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti tẹ̀ báyìí pé wọ́n digunjalè sọsẹ́ nílé olóògbé Olóyè Moshood Abíọ́lá tó wà ní Ìkẹjà nílùú Èkó níbi tí wọ́n ti jí nǹkan tó tó ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù lọ.

    Abíọ́lá ló jáwé olúborí nínú ìbò Ààrẹ gbogbogbòò tó wáyé lọ́dún 1993 èyí tí Ọ̀gágun fẹ̀yìntì Ibrahim Babangida wọ́gilé nígbà náà.

    Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá nípìńlẹ̀ Èkó, Hakeem Odumosu ló sọ pé ọwọ́ àwọn agbófinró ti tẹ àwọn amòòkùnṣèkà ẹ̀dá ọ̀hún tí wọ́n yabo ilé Abíọ́lá L’ọ́jọ́rùú.

    Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá tó sàbẹ̀wò sí ilé ọ̀hún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé mẹ́ta làwọn olè ọ̀hún ṣùgbọ́n ọ̀kan lára wọn ló gbé ìbọn dání.

    Ọ̀gbẹ́ni Odumosu ní ”ẹbí Abíọ́lá sọ f’óun pé àwọn olè náà jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ góòlù àti owó lọ.”

    ”Àwọn agbófinró ti wà lojufo báyìí lágbègbè ìkẹjà tí ilé náà wà tó fi dé ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá tó wà ní ibodè Ìdírókò àti Seme,” Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá ló sọ bẹ́ẹ̀.

    Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ní kò sí ẹni tó farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà nínú ìyàwó Abíọ́lá, Bísí àti ọmọbìnrin méjì tó wà nílé.

    Ọ̀gbẹ́ni Odumosu fikún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìwádìí ṣì ń tẹ̀ síwájú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

    Àwọn Aládùgbóò tó báwọn akọròyìn ṣọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé géètì tó wà lẹ́yìn làwọn olè bá wọlé, wọ́n ní láago mẹ́rin ìdájí ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé nígbà táwọn ẹṣọ tó wà nínú ilé náà ti sùn lọ.

    Fẹ́mi Akínṣọlá

  • Ìjọba Nàìjíríà kéde ìlànà tuntun fún ìséde Kofi-19

    Ìjọba Nàìjíríà kéde ìlànà tuntun fún ìséde Kofi-19

    Ìjọba Nàìjíríà kéde ìlànà tuntun fún ìséde Kofi-19

    Ṣe àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní kò sí ohun kan tó le le le tí kìí padà rọ̀, ìdí nìyí tó fí jẹ́ pé, ìrọ́jú ló yẹ ẹni tí eégún bá ń lé…

    Ìjọba Orílẹ̀ yìí ti fi ọjọ́ kún ìséde Kòrónáfairọ̀ọ̀sì jákèjádò Nàìjíríà.

    Ní báyìí, dípò aago mẹ́wàá alẹ́ sí mẹ́rin ìdájí, aago méjìlá òru sí mẹ́rin ìdájí ni Ìṣéde yóó fi má a wà.

    Ọgbọ̀nọ́njọ́, oṣù Kẹta, ọdún 2020 ni Ààrẹ kọ́kọ́ kéde Ìṣéde ní ìpínlẹ̀ Èkó, Ògùn àti ìlú Àbújá, níbi tí Kofi-19 ti kọ́kọ́ gbilẹ̀.

    Alága Ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá fún amójútó kòrónáfairọ̀ọ̀sì ní Nàìjíríà, Sani Mustapha, ló kéde àṣẹ tuntun yìí lọ́jọ́bọ.

    Ó ṣàlàyé pé àǹfààní ti wà fún àwọn Ilé sinimá, ibùdó tí wọ́n ti ń se eré ìdárayá, àti àwọn ibùdó fàájì tó kù, láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà.

    Bákan náà ló sọ pé kí àwọn ile ẹ̀kọ́ má a múra sílẹ̀ fún wíwọlé padà.

    Musatpha sọ pé kọ́kọ́rọ́ kan tó ba eyín ajá jẹ́ ni àwọn tí kò tẹ̀lé Ìlànà Ìjọba fún àrùn Kofi-19.

    Àwọn nǹkan tó tún wà nínú àṣẹ tuntun tí Ìjọba kéde

    Àwọn ilé ìtura ti lè sí ìlẹ̀kùn wọn.
    Ilé sinimá, ibi tí wọ́n ti ń ṣe eré ìdárayá le sí padà, ṣùgbọ́n èrò wọn kò gbọdọ̀ ju ìdá àádọ́ta lọ


    Àwọn gbọ̀ngàn ayẹyẹ lè síi padà, ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ ju ìdá àádọ́ta lọ
    Àwọn ilé oúnjẹ kò gbọdọ̀ gbà kí ẹnikẹ́ni jókòó jẹun lọ́ọ̀dọ wọn
    Àwọn ilé ọtí àti ilé ijó kò gbọdọ̀ ṣí ìlẹ̀kùn


    Àjọ NYSC yóó bẹ̀rẹ̀ ìmúra sílẹ̀ fún ìgbà tí àwọn ile ẹ̀kọ́ yóó di ṣíṣí padà
    Àjọ INEC yóó ríi dájú pé ó tẹ̀lé Ìlànà lórí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì – ẹni tí kò bá lo ìbòmú kò gbọdọ̀ dìbò. Bákan náà ni wọn ó tún má a ṣe àyẹ̀wò bí ara àwọn èèyàn ṣe gbóná sí, lo sanitáísà, àti títakété síra ẹni.

    Fẹ́mi Akínṣọlá

  • Ìrọ̀rùn dé, Yínká Ayéfẹ́lẹ́ le è dúró kọrin báyìí

    Ìrọ̀rùn dé, Yínká Ayéfẹ́lẹ́ le è dúró kọrin báyìí

    Ìrọ̀rùn dé, Yínká Ayéfẹ́lẹ́ le è dúró kọrin báyìí

    Ẹ̀dá tí tó bá sì wà lókè èèpẹ̀ tó ń ṣẹ̀mí, ìrètí kò pin fúnrúfẹ́ onítọ̀ùn, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí fún gbajúgbajà olórin jùjú n-nì, Yínká Ayéfẹ́lẹ́ bí ó ti jẹ́ pé ó ti le è nàró báyìí lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ tó bá wù ú.

    Èyí kò ṣẹ̀yìn kẹ̀ẹ̀kẹ́ ìgbàlódé kan tó ní àwọn èròjà ìrọ̀rùn tó ṣe é yí sí ọ̀tún àti òsì, òkè àti ilẹ̀, ibi tó bá sì wu èèyàn, ló le è yí kẹ̀ẹ̀kẹ́ náà sí.

    Yínká Ayéfẹ́lẹ́ , ló kéde pé ó ti rọrùn fún òun báyìí láti rìn pẹ̀lú kẹ̀ẹ̀kẹ́ tuntun náà lójú òpó Sítágíràmù rẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì.

    Ó fikún un pé ẹlẹ́yinjú àánú kan, tó pé orúkọ rẹ̀ ní Hon Obama Oludare Akande ló fún òun ní kẹ̀ẹ̀kẹ́ tuntun náà láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

    Ayéfẹ́lẹ́ ní “Mo lè dúró kọrin níbikíbi báyìí pẹ̀lú kẹ̀ẹ̀kẹ́ tuntun náà, ‘action’ bẹ̀rẹ̀ báyìí, mo dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ Dáre Obama.”

    Akọrin Tùǹgbá náà fikún un pé “ìrọ̀rùn dé bá mi gidi báyìí pẹ̀lú kẹ̀ẹ̀kẹ́ tuntun náà, Dáre Obama tún ti fún mi ní ìrètí láti rìn padà,.”

    Ó wá gbàdúrà fún Aláànú náà pé kò ní mọ ìnira nílé ayé rẹ̀.

    Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, ó ti lé ni ogún ọdún tí gbájúmọ́ akọrin ẹ̀mí náà ti pàdánù ọ̀pá ẹ̀yìn rẹ̀, tí kò sì leè rìn mọ́ nítorí ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé.

    http://iroyinowuro.com.ng/2020/08/29/irorun-de-yinka-ayefele-le-e-duro-korin-bayii/

    Fẹ́mi Akínṣọlá

  • Wọ́n ti yan adarí tuntun fún Ifásitì “Unilag”

    Wọ́n ti yan adarí tuntun fún Ifásitì “Unilag”


    Ó jọ bíi ẹni pé kángun kàngùn kángun ilé ẹ̀kọ́ Ifásitì ìpínlẹ̀ Èkó tí kángun síbi kan báyìí o, bí Ìròyìn tó ń tẹ̀ wá lọ́wọ́ ṣe ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn aláṣẹ Ilé ẹ̀kọ́ gíga Ifásitì Èkó, Unilag ti yan Gííwá tuntun míì láti máa tukọ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà.

    Ọ̀jọ̀gbọ́n Folashade Ogunsola ló gbégbá orókè nínú gbogbo àwọn tí wọ́n dìbò yàn, èyí tó wáyé láàrin àwọn Ilé ìgbìmọ aṣòfin Ifásitì náà tí wọ́n fi yan adelé.

    Folashade ni ìgbákejì ẹ̀ka ìdàgbàsókè fún Gííwá tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀, Oluwatoyin Ogundipe.

    Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí a gbọ́, nínú ìbò mẹ́tàdínláàdọ́ṣàn, Folashade nìkan ní ìbò márùnléláàdóje.

    Ẹnìkejì tí wọ́n tún fojú sùn fún ipò kan náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ben Ogbojafor ní tirẹ̀ ní ìbò mọ́kànlélọ́gbọ̀n.

    Níbi ìpàdé ìjókòó ilé Ìgbìmọ̀ aṣòfin Ifásitì náà tó wáyé lọ́jọ́ Ajé ni wọ́n ti yan Folashade.

    Fẹ́mi Akínṣọlá

  • Sunday Shodipe tí wà láhàámọ wa– Alukoro ọlọ́pàá Ọ̀yọ́

    Sunday Shodipe tí wà láhàámọ wa– Alukoro ọlọ́pàá Ọ̀yọ́

    Sunday Shodipe tí wà láhàámọ wa– Alukoro ọlọ́pàá Ọ̀yọ́

    Fẹ́mi Akínṣọlá

    Ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti sọ ọ̀rọ̀ kanranjágbọ́n afurasí Sunday Shodipe di ẹgbẹ̀rún ìsáǹsá tí wọn ò lè sá mọ́ Ọlọ́run lọ́wọ́, bí ìròyìn tó ń tẹ̀wà lọ́wọ́ ṣe sọ ọ́ di mímọ̀ pé ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti tẹ arákùnrin kan, Sunday Shodipe tó sá mọ́ wọn lọ́wọ́ láìpẹ́ yìí.

    Shodipe jẹ́ afurasí tí wọ́n ti kọ mú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣekúpani tó ń wáyé láìpẹ́ yìí lágbègbè Akínyẹlé ní ìlú Ìbàdàn.

    Kò tíì dájú ibi tí wọ́n ti rí i mú, ṣùgbọ́n alukoro ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Fádèyí Olugbenga ṣọ̀rọ̀, ó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó tí wà lákàtà ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá.

    Bí ẹ kò bá gbàgbé, ìròyìn jáde rẹpẹtẹ nígbà tí ọwọ́ kọ́ tẹ Shodipe tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún Kódà, àti ìgbà tó tún sá lọ mọ́ ọlọ́pàá lọ́wọ́, ìròyìn kò tíì tán nílẹ̀ títí di àkókò yìí.

    Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́, ó ti pẹ́ díẹ̀ tí Ìròyìn sọ pé afurasí ọ̀daràn yìí ló wà nídìí ikú ọ̀wọọwọ̀ọ́ tó ń wáyé lágbègbè Ìjọba ìbílẹ̀ Akínyẹlé nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́.

  • Bishop Oyedepo ní láti tẹ̀lé òfin tàbí kí ó dá orílèèdè tirẹ̀ sílẹ̀ – Iléesẹ́ Ààrẹ

    Bishop Oyedepo ní láti tẹ̀lé òfin tàbí kí ó dá orílèèdè tirẹ̀ sílẹ̀ – Iléesẹ́ Ààrẹ

    Oludasile ile ijosinLiving Faith Church Worldwide, Bishop David Oyedepo lo ti n gbe peregi kana pelu ijoba apapo lati bii odun meloo kan seyin.


    Ofin lori owo ori ati amojuto awon ile-ise ati awon ile-ijosin ti ajo Company and Allied Matters Acts (CAMA) maa samojuto gege bi ijoba apapo se sagbekale re lo fa gbonmi-sii-omi- o too ti ote yii.

    Bishop Oyedepo ni eyinju Olorun ni ile-ijosin, ko letoo sii ki enikeni fowo kan an. O ni oro ile-ijosin da bi igba ti alagata kan ba fowo kan iyawo wa. O ni eleyii maa n fa ibinu gidi. O ni bee gege ni oro ile-ijosin ri si Olorun.

    O ni ijoba ko letoo lati maa da si amojuto tabi oro nipa owo ori ni ile Olorun.


    Arabinrin Lauretta Onochie ti o je okan ninu awon olubani-damoran lori iroyin ni ileese Aare lo da Bishop Oyedepo lohun lori ero ayelujara Twitter pe ko letoo bi Alagba ijo yii se n benu ate lu ofin ijoba apapo.

    Arabinrin yii ni ile ijosin Bishop Oyedepo kan naa to wa ni orileede London n san owo ori re deedee, bee lo si n tele gbogbo ofin ti ijoba orileede naa gbe kale.

    Arabinrin yii ni bawo lo se wa je ti ijoba Naijiria ko tii ni soro ti Alagba yii ti maa koo danu?

    Onochie ni eyi ku die kaa to, o ni ko si orileede ti ile-ijosin tabi enikan ti ga ju ofin lo. O ni ti Alagba Oyedepo ba si ti mo pe oun ko ni tele ofin Naijiria, ki o yara lo da orileede tire sile ki o si maa sofin bi o ba se wuu.