Home / Awọn Iroyin Agbegbe / Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì fèsì lórí ìwọ́de EndSARS
endsars

Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì fèsì lórí ìwọ́de EndSARS

Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì fèsì lórí ìwọ́de EndSARS

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba orílẹ̀-èdè United Kingdom, ti fèsì lórí ìwé ẹ̀sùn tí àwọn ọmọ Nàìjíríà fọwọ́ sí, tí wọ́n sì fi ránṣẹ́ síi.

Ìwé náà ló ń ké sí àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé tó wà nínú àjọ Commonwealth, láti fi ‘ ìyà’ jẹ àwọn Olórí Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí ìbáwí, fún ẹnikẹ́ni nínú wọn tó lọ́wọ́ nínú títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú, gẹ́gẹ́ bí òfin àjọ náà ṣe sọ.

Ọmọ Nàìjíríà bíi okòólérúgba ó dín díẹ̀ (219,665) ló fi ọwọ́ sí ìwé ẹ̀sùn náà lọ sọ́dọ̀ọ Ìjọba UK.

Ilé Aṣòfin Orílẹ̀-ede UK sọ pé, ominú ńkọ òun lórí rògbòdìyàn tó wáyé lásìkò ìwọ́de ENDSARS, àti pé àwọn ṣì ń dúró de ìwádìí tí Ìjọba Nàìjíríà yóó ṣe lórí ẹ̀sùn ìfìyàjẹni tí aráàlú fi kan àwọn ọlọ́pàá.

Ìwé ẹ̀sùn tó bá ti ní ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn èèyàn tó fọwọ́ sí i , ní ilé aṣòfin orílẹ̀-èdè UK má ń jíròrò lé lórí, ìwé ẹ̀hónú ENDSARS yìí sì ti lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba.

Àmọ́ṣá, wọ́n ní àwọn kìí sọ ìgbésẹ̀ tí àwọn yóó gbé lórí àwọn ìwé ẹ̀sùn náà ní gbangba.

About asatiwa

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

A Dúró Lójú Òpó Ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ Àkọ́kọ́ Lórí Ẹjọ́ Ajimobi – Adájọ́

A dúró lójú òpó ìdájọ́ ilé Ẹjọ́ àkọ́kọ́ lórí ẹjọ́ Ajimobi – Adájọ́ Fẹ́mi Akínṣọlá Gómìnà àná ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Abiola Ajimọbi ti fìdí rẹmi nínú ìpẹ̀jọ́ rẹ̀ láti tako ìbò tí ó gbé ojúgbà rẹ̀ Kọla Balogun wọlé gẹ́gẹ́ bíi Sẹ́nétọ̀.Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ni ó fagilé ìwé ìpẹ̀jọ́ tí Ajimọbi fi pe sẹ́nétọ̀ náà tí ó ń ṣojú gúúsù Ìpínlẹ̀ náà lẹ́jọ́. Ṣe lórí ìdìbò ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kejì ọdún yìí tí Balogun ní ìbò 105,720 nígbà tí Ajimọbi ...