Home / Àṣà Oòduà / Ògún lákáayé .

Ògún lákáayé .

Ọ̀wọ́nyán rosùn porogodo lóso, Agogo ńlá ni wọ́n fi ń fọ́ri fálágbára mu, Àtàtà ńlá ni wọ́n fi ń fọ yíìrí mọrọ̀, Adífáfún Ògún tíń gbógun lọ sí Ìgbòmẹkùn-eséji, ẹbọ lawo níkóse, Ògún ló sẹbọ sètùtù lówá kóre dé ìtùtúrú

Ògún lákáayé
Oníjà oòle
Ẹjẹmu olúwọnran
Adìgìrì rebi ìjà
Koríko etídò
tíírú mìnìmìnì
Sékélé ni ń o ma rọ̀bẹ
ní pópó iyemakin
Sàgàlà lọ̀bẹ ìrè
Ọ̀bẹ ìrèmògún di ogójì
Ọ̀bẹ ìrèmògún di ọ̀wọ́ngógó
Ọmọ rọ́wọ́rọ̀wọ̀rọ́wọ́
Bí Alágbẹ̀dẹ́ kòbá rọ́wọ́
Ọmọ fínnáfìnnàfínná
bí Alágbẹ̀dẹ kòbá fínná
Tọlọ́kọ́ taládàá ni yóò mọ sùn sọ́nà oko

Ògún yeeeeeeeeeeeeeeeeeeeeeee

About Awo

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo