I never once in my life regrets ever since I started listen to voice of OLODUMARE through IFA. Is the only way to hear the true/real voice of OLODUMARE try and see.


Author: oodua
-
Post of the Day !
-
Akasu oro Fayose: “Eni ba fori so mi, yoo fo yangayanga”
Gomina ipinle Ekiti, Ayodele Peter Fayose, ti fi da gbogbo ara ilu loju wi pe didun losan yoo so fun egbe alaburada, PDP, ninu eto idibo alaga ibile eleyii ti yoo waye lojo kokandinlogun osu kejila odun yii (19-12-15).
Sugbon gege bi atejade akowe ipolongo fegbe APC, Ogbeni Taiwo Olatunbosun, so wi pe awon ko ni igbagbo ninu igbimo ti n se kokari eto idibo naa, Ekiti State Independent Electoral Committee, ESIEC. O ni pupo awon omo igbimo naa lo je awon omo egbe PDP, eleyii si wa lara ohun to mu Fayose fokan bale.
Sugbon gege bi oro Fayose, eni odun marunlelaadota (55), salaye wi pe aileja nita baba mi ko de hin-in. “Omi ti tan leyin eja awon omo egbe APC ti ipinle Ekiti lo mu won ma japoro bi eni won ta lofa,” Fayose fi kun oro re bee.
Rugudu to waye latari wi pe egbe onigbale, APC, ko faramo awon igbimo ajo ti o seto idibo naa lo ti pada dele ejo bayii.
“E je ki gbogbo wa ka pade nile ejo. Enikeni ko le da eto idibo naa duro ayafi ohun ti ile ejo ba so lojo kerinla osu kejila odun yii,” Fayose tun fidi re mule bee.
Gege bi alaga igbimo. Eto idibo fun ipinle Ekiti, Onidajo-feyinti Kayode Bamisile, so wi pe iro funfun balau ni wi pe awon omo igbimo oun je omo egbe oselu kan. O si fi kun un wi pe, enikeni to ba ni eri to daju le fi sita. Alaga naa ko sai kede ojo Satide ti n bo, 19-12-15, gege bi ojo ti eto idibo naa yoo waye.
Wayio, ogbeni Owen Chigozie Ewenike, okan ninu awon oludije fun ipo kanselo adugbo lagbe egbe oselu PDP ti gbe oriyin fun gomina Fayose fun anfaani to fun un lati kopa ninu eto idibo to n bo naa.
Ti e ko ba gbagbe, nnkan bi osu meloo kan seyin ni Gomina Fayose fi atejade kan sita, eleyii ti oludamoran re nipa iroyin ayelujara, Lere Olayinka gbe jade faraye ri. Ninu atejade yii ni ogbeni Fayose ti n ju akasu oro ribiti fun awon alatako re:
“Ni ipinle Bauchi nibi ti alaga egbe PDP apapo ati minisita fun ilu Abuja ti wa, won ko ri ida marun-un ninu ogorun (5%) ibo mu fegbe PDP.“Ninu eto idibo aare to waye, mo bori ibo naa fun PDP nipinle Ekiti, mo bori gbogbo ibo asoju ile igbimo asofin agba ati asoju-sofin Abuja, mo tun bori gbogbo ibo omo ile igbimo asofin ipinle ti apapo won je merindinlogbon (26) fun egbe oselu PDP l’Ekiti.
“Mo dabi Isireli ti awon ota dooyi yika, sugbon to n leke saa nigbogbo ojo. Peteru ni oruko mi, eyi to tunmo si apata. Ti enikeni ba fori so mi yoo fo yangayanga, ti mo ba subu lu enikeni, maa lo luulu. Fun idi eyi, e fi apata sile jeje o.” – Fayose
-
Taye Ogunlaja: Won ti pa oloye omo egbe NURTW tiluu Eko
*Won gun un lobe lorun pa ni
Awon olopaa olotelemuye, eka ti ile ise olopaa ti n risi iwa idaran to wa ni Panti, Yaba ti bere ise iwadii to gbepon bayii lati mo odaju eda to seku pa Taye Ogunlaja, oloye NURTW nikete to jade ninu Mosalaasi kan to wa ni agbegbe Abule- Egba nipinle Eko.Ogbeni Ogunlaja ti enikan sadeede gun lobe legbe orun leyin irun alaasari lagbo wi pe o n mura lati rekoja lo si ilu Faranse pelu awon omo re meji ati iyawo re lati lo jegbadun opin odun mo odun tuntun to n bo lona.
Gege bi iwadii ti OLAYEMI ONIROYIN ri kojo, okan pataki omo egbe awako (NURTW), eka ti Marina ni Ogbeni Ogunlaja je. Bakan naa la si gbo wi pe rugudu kan an sele lowo leka egbe won naa eleyii ti won pinnu lati yanju nibi ipade gbogboogbo olosoosu to ma n waye ninu egbe naa.
Nibi ipade yii naa ni won wa ki Ogbeni Ogunlaja to jade lo josin fun oba Allah ko to di wi pe ika eniyan kan pinnu lati ran sodo oba Allah patapata nipa fifi obe oloju meji, elenu sonso, eleyii ti won tibo egbe orun re. Ogbeni Ogunlaja ko ku loju-ese, o n japoro nile ninu agbara eje to ti kun gbogbo ile ko to re ni sun mo o.
Iyawo oloogbe naa salaye fun awon olopaa wi pe ohun ti oko re so gbeyin lori foonu ko to lo si mosalaasi ni wi pe, wahala ti won ba awon yanju naa ko ti kesejari.
“Lojo Alamisi to koja yii, oko mi gba ipe ori foonu lati odo okan lara awon omo egbe onimoto lati ran an leti ipade olosoosu won ti won maa n se.
Oko mi sare woso bee lojade nile ni nnkan bi ago kan osan-an. Igba to se die mo pe e, o si fi damiloju wi pe oun ti debi ipade naa. Ohun ti oko mi tun so ni wi pe awon oro ti won ba oun so ko ye oun rara. O ni awon owo kan ti oun ko modi ni won ni ki oun maa se isiro re. O si so fun mi wi pe laipe, oun yoo fi ipade naa sile lati lo kirun,” aya Ogunlaja se lalaye bee.
Leyin eyi ni won pe aya Ogunlaja wi pe oko re wa losibitu. Igba ti yoo fi de osibitu ti won gbe lo l’Abule-Egba, won ni won ti taari re lo si Lagos State University Teaching Hospital (LASUTH) to wa n’Ikeja nigba ti agbara osibitu ti won koko gbe lo ko kaa. Sugbon ki won to de LASUTH, ogbeni Ogunlaja ti padanu opolopo eje ninu inira nla eleyii to si mu je ipe Olorun laipe ojo.
Aya Ogunlaja ti bere si ni rawo si awon agbofinro lati ma je ki iya naa je e lajegbe nipa sise awari ika eniya to seku pa oko re.
Gbogbo igbiyanju OLAYEMI ONIROYIN lati kan si alarinna ile ise olopaa ipinle Eko lori oro naa lo jasi pabo.
-
Ile ejo to gaju lo ni yoo pari idaju iku Reverend King
Ile ejo to gaju nile yii ti kede ojo kerindinlogbon osu keji odun ti n bo (26/02/15) gege bi ojo ti igbejo adari ijo Christian Praying Assembly, Reverend Chukwuemeka Ezeugo, ti gbogbo eniyan mo si Reverend King yoo ma waye.
Reverend King yii lo pe ejo ko-temi-lorun latari ejo iku ti ile ejo giga ti ipinle Eko da fun-un.
Ile ejo to gaju yii, nibi ti Onidaju Walter Onoghen ti n joko ni o ti sun igbejo naa siwaju nigba ti awon agbejoro fun igun mejeeji bere si ni gba oro naa bi eni gba igba oti, ti won si tun bere iyan jija niwaju adajo.
Olori eka idajo ati komisanna fun eto idajo ipinle Eko, Onidajo Adeniji Kazeem, eni to farahan ni ile ejo naa pelu Arabirin Idowu Alakija ro ile ejo naa lati da ipejo tuntun naa nu, ki won si tele idajo ile ejo giga ipinle eko eleyii to ni ki won yegi fun maanu naa.
Reverend King, eni to koko farahan nile ejo lojo kerindinlogbon osu kesan-an odun 2006 lori esun mefa to dale ipaniyan ati igbiyanju lati paniyan.
Ninu awijare re, okunrin naa ni oun ko jebi awon esun naa. Sibesibe, onidajo Joseph Oyewole ti n joko nile ejo giga ilu Eko to wa ni Ikeja da ejo iku fun un lojo kokanla osu kini odun 2007 lori esun ipaniyan okan ninu awon omo ijo re, Ann Uzoh.
Ninu esun ti ijoba ipinle Eko fi kan Reverend King lo n wi pe, okunrin naa da epo bentiro si ara awon eniyan marun-un kan. Lara awon eniyan naa si ni Uzoh to doloogbe lojo keji osu kejo odun 2006 wa latari isele to sele sii lati owo Reverend King .
Orisun
-
Gobe sele lagbo Davido
Orisiirisii ara ni awon omo olorin igbalode maa n da lagbo ere orin. Iru ara bee ni bi ki won bo aso lorun ki won si ju si aarin ero onworan. Awon mii a maa bo alakorun danu soju agbo lati fi ife han. Nigba mii ewewe, won maa da bi oti tabi omi inu ike si awon ero ti n je igbaladun won loju agbo ariya.
Iru asa yii naa ni Dafidi omo Adeleke ti gbogbo eniyan mo si Davido da lara lagbo ere re kan ni Ilu Burkina Faso. Alase ile ise orin HKN da omi inu ike si ara awon ero onworan nibi o ti n korin. Nibi ti Davido ti n fo soke ti n yo bi eni iya re bimo tuntun ni maanu giripa kan ba jade wa ba a lori pepe laaarin awon ero.
O gba omo baba olowo laso mu girigiri, bee ni i gbo jigijigi, to si n bi leere idi to fi n da omi si oun lara. Opelope awon osise alabo omokunrin olorin naa, ese nla rigidi ti maanu naa gbe soke ko ba sokale sori gongo imu Davido baba Imade nibi o ti n jo Skelewu pelu sokoto re to gbe si bebere-idi.
-
“Oruko awon to ja Naijiria lole ko ni pe jade” – Buhari
Aare Buhari ti fi da awon omo Naijiria loju wi pe, laipe, awon oruko awon ojelu ti won ko owo Naijiria je ko ni pe di tite jade fun gbogbo aye. Gege bi oro re, eleyii to se nibi ipade Anyiam-Osigwe Foundation to waye nilu Abuje lose to koja, ibe ni aare ti n so wi pe awon oruko yii ni banki agba ile yii, Central Bank of Nigeria (CBN) ti se akojopo won.
Sugbon won da atejade naa duro latari awon iwadii kan ti n lo lowo labenu. Aare tun fi kun un wi pe pupo ninu awon eniyan yii ni won ti n da lara awon owo naa pada si asunwon ijoba nipase eto igbogun ti iwa jegudujera ti n lo lowo.
“A ti gbe awon igbese to joju lati ri awon owo ti won je mole yii gba pada. Mo si fi da yin loju wi pe iwadii to fese mule n lo kaakiri tibu-toro ile yii ni awon eka ile ise ijoba pata. Awon osise tabi awon ti won wa nipo agbara ni awon igba kan seyin naa pelu awon ti a n tanna wadii wo. Awon ti won ba fe aponle, anfaani wa lati da awon owo naa pada lai si wahala.
“Mo si fi n dayin loju wi pe oruko awon asebaje yii pata ni banki agba yoo gbe jade. Ohun to fa ti a fi dawo atejade naa duro ni wi pe, igbejade awon oruko naa ni akoko yii le se akoba fun awon iwadii kan ti n lo lowo. Sugbon gege bi ara ilu to ran wa nise, a fi dayin loju wi pe dandan ni ka jabo fun yin nigba ti akoko ba to,” Buhari se lalaye bee.
Olayemioniroyin
-
Oselu ipinle Oyo: Alao Akala ti wa ogbon mii da
Christopher Alao Akala ti wa ogbon mii da
Nibayii ti Christopher Alao-Akala, eni odun marunlelogota (65) ti pinnu lati darapo mo egbe APC lati inu egbe Labour Party ni awon awuyewuye kan ti bere si ni jeyo jade.Lara awon oro ti a gbo ni wi pe awon omo egbe APC ti ipinle Oyo ko fi taratara dunnu si igbese tuntun yii. Ero won ni wi pe Akala, eni ti awon kan tun pe ni omo Iya Alaro fe wa fi buredi ko won lomi obe je lasan ni.
Nigba ti awon kan tun wi pe nigba ti obe dun, to jina tan ni Akala n sare bo wa lati wa kore ise owo awon.
Gege bi Kola Balogun, oludari egbe ti n polongo ibo fun Alao-Akala se so, o ni gbogbo eto lo ti to fun Akala ati awon alatileyin re nipinle Oyo lati tele e wonu egbe onigbale, APC.
Agbaoje oloselu, eni to ti fi igba kan je gomina ipinle Oyo ri, lagbo wi pe o ti n ni ipade po pelu awon oloye sankosanko lati inu egbe APC lori igbese re tuntun naa.
Gege bi oro Lukman Agboluaje, okan ninu awon omo egbe kan ti n se atileyin fun Alao-Akala, Destiny group, naa je ko ye gbogbo aye wi pe, ibikibi ti Akala ba lo lawon setan lati tele lo. Lara awon to peju sibi ipade naa ni Honourable Tajudeen Abisodun, Dr. Adetunji Gbola, Senator Brimo Yusuf, Dr Kola Balogun, Alhaji Omilabu Ghandi, ati awon kan-anrinkan-anrin lagbo oselu ipinle Oyo.
Sugbon gege bi oro Kehinde Ayoola, olori ile igbimo asofin ipinle Oyo nigba kan ri, okunrin naa gba wi pe ogbon ati dije fun ipo gomina lodun 2019 ni Akala n da. Bakan naa lo fi kun un wi pe ko si ohun to buru ti Akala ba ni i lero lati dije nitori eto re ni. Sugbon bi o se rorun fun ala re lati wa si imuse gan-an ni ko daju.
Alao Akala to ti fi igba kan je alaga ijoba ibile Ariwa Ogbomoso labe egbe oselu All Peoples Party (APP) laaarin odun 1999 si 2002 darapo mo egbe PDP lodun 2003. Eleyii ti won si pada yan-an gege bi igbakeji gomina eleyii ti ara ilu pada dibo yan sipo.
Akala bo si ipo gomina leyin rugudu to waye laaarin Lamidi Adedubu ati Rasheed Adewolu Ladoja to je gomina igba naa. Won yo Ladoja loye lojo kejila osu kini odun 2006 eleyii to fun Akala lanfaani lati bo si ori aga isakoso ipinle Oyo gege bi gomina.
Leyin eyi ni won tun pada dibo yan Akala si ipo gomina laaarin odun 2007 si 2011.
Leyin iku Adedubu, PDP ko gba Akala mo latari orisiirisii wahala ti n fi joojumo je jade. Eleyii lo mu wo inu egbe Labour Party.
Ninu egbe yii naa lo si ti dije fun ipo gomina ipinle Oyo lodun 2015 sugbon ti apapo iye ibo re ko si gbe e leke idibo naa.
Gege bi alaye awon onwoye nipa oro oselu se so, nibayii ti Alao-Akala ti setan lati darapo mo egbe APC, lara awon pataki omo egbe ati alatileyin fun egbe APC ipinle Oyo ti Akala yoo ba nikale l’Oba Lamidi Adeyemi III, Alaafin tiluu Oyo.
Ti e ko ba si gbagbe, ni awon akoko ti Alao-Akala wa lori oye gege bi gomina lo tako bi won se fi alaafin Oyo je alaga igbimo lobaloba ipinle Oyo gege bi oye ajegbe.
Akala so wi pe iru oye alaga igbimo lobaloba naa lo ye ko je oye ti won yoo ma pin je laaarin awon oba. O si daba ki won pin oye alaga awon lobaloba ipinle naa laaarin Olubadan tile Ibadan, Soun tiluu Ogbomoso ati Alaafin tiluu Oyo.
Bi o tile je wi pe awon omo ile igbimo asofin ko fara mo aba naa, eleyii ti ko si mu ero Akala wa si imuse. Sugbon aarin Akala ati Oosa ilu Oyo ko pada gunrege mo lati igba naa wa.
-
Iriri awon omuti: Ore meji ku, iketa fara pa
Gege bi oro awon Yooba,”eni Sango ba toju re wole, eni naa ko ni ba won bu oba Koso laelae.” Okunrin kan to pe ara re ni Cde Zenzele Nkosi lori FACEBOOK lo salaye ijamba moto to sele si i nipa iwa oti mimu pelu oko wiwa. Okunrin naa se afihan foto oju-apa to gbe jade nibi isele naa eleyii to ti n jina. Bakan naa lo si n gba awon eniyan niyanju lati yago fun oti mimu pelu moto wiwa.
Ninu alaye Nkosi, okunrin naa salaye wi pe awon ore oun meji ti won wa pelu oun ninu oko naa lo ku, oun nikan ni ori koyo. Awon meji yoku ti padanu emi won danu latari wiwako-muti.
“Oko naa baje koja atunse, awon ore mi meji ti won wa ninu oko naa si ku loju-ese. Mo je oloriire lati wa laye. Too ba wako, ma muti; too ba muti, ma wako. Mimu oti wako je pakute iku ti n duro deni. Ti o ba fe wo oko ni akoko poposinsin odun taa wayii, ri daju wi pe direba re ko mu oti, o gbodo tun je eni ti ara re bale daada. Gba mi gbo, ile aye yii ko too pon,” Nkosi fidi alaye re gunle bee.
Atejade Nkosi eleyii to se lojo keje osu kejila odun yii (7/12/15), ni nnka bi aago meta osan ku iseju mejila ni awon eniyan bi ogorun mefa (600) ti se atunpi atejade naa. Nigba ti awon eniyan bi ogofa (120) baa kedun labe iriwisi re titi di bi ago mokanla ojo Eti to koja yii ti OLAYEMI ONIROYIN se abewo si ikanni re lori ayelujara.
Die lara ikini ati ibanikedun ti awon eniyan se fun arakunrin naa ni yii:
M’lori Mlori Hardy: Cde…ki Oluwa fi orun ke awon to ti lo. Inu mi dun si bo se lo irora re lati fi se kilokilo ati ijigiri fun awon eniyan. Akoni loo se.
Sibiya Magoodies: Gbogbo ohun ti yoo sele seda laye lo ti wa ninu akosile Oosa Oke. Sugbon maa fi ope fun Oluwa wi pe o wa laaye lonii. Ki Oluwa bu tutu si okan awon eniyan ti won padanu awon eniyan won.
Orisun: Olayemioniroyin





































