Category: Àṣà Oòduà

Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.

  • Omidan asewo ti se ‘kerewa’ koja sorun alakeji

    Awon Yooba bo, won ni owo tada mo ni kada lehin. Iku ogun ni i pa akikanju, omi ni pada wa pa omuwe lodo. Okan ninu awon omo asewo ilu Abuja ti oruko re n je Omidan Ome Enyi lo ti se agbako iku ojiji bayii lenu ise nabi to yan laayo. Omobirin eni odun marunlelogbon (35) ni won ba oku re ninu ile itura kan to wa ni agbegbe Kubwa to wa niluu Abuja. Ome to je omo ilu Calabar lagbo wi pe oun ati okan ninu awon onibara re kan jo wole sun lale ojo Aje to koja yii fun “igbadun alailopin”.

     

    Sugbon nigba ti ile yoo fi mo, oku Ome nikan ni won ba nile gelete. Okan ninu awon agbale ile itura naa lo sakiyesi oku omobirin naa ki won to gbe lo si ile igbokusi. Titi di akoko akojopo iroyin yii, enikeni ko ti le so pato iru iku to pa omidan orekelewa ti n fidi re pawo naa. Bakan naa ni ko si eni mo ibi ti onibara re fara pa mo si.

  • Femi Adebayo, Funke Akindele, Mercy Aigbe, Toyin Aimakhu nibi ami eye Africa Magiki 2016

    Aimoye osere lo peju sibi ami eye (Africa Magic Viewers Choice Awards) 2016 to waye niluu Eko. Eyi to waye yii ni i se elekerin iru e. Oruko awon olubori ami eye naa wa nisale .

  • Won ti pago lori maanu to fowo kan oyan omoge

    Arabirin, Ifeoma Okoroafor, eni odun mejidinlogbon (28), lo ti salaye fun ilejo Upper Area Court to wa niluu Abuja wi pe, Ogbeni Musa Goddy fowo gbe oun loyan jo ni oun se fo nigo lori.  Ogbeni Musa lo fejosun lago olopaa to wa ni Garki ni ojo kejidinlogbon (28) osu keji odun yii (28/02/2016) nigba ti Arabirin Ifeoma fi igo da iho si aarin ori re ti eje si bere si ni tu jade bi emu inu akeregbe.

    “Sadeede ni arabirin yii fi igo da batani si gbogbo ori mi ati ara mi laise wi pe mo se ohunkohun fun un, kosi ohun to da emi a tie papo rara,” Ogbeni Musa se akosile alaye bayii fun awon olopaa.  Gege bi asoju ile ise olopaa, Urom Inah, se alaye niwaju adajo wi pe, iwadii awon ko fi eri kankan pataki han wi pe, lotito ni Musa fi owo gbe oyan Ifeoma ko to gun nigo.

     

    Ninu awijare Ifeoma, eni ti n gbe ni agbegbe Dutse to wa ni Apo, “Oluwa mi, ti ko ba nidi, obirin ki i je Kumolu. Musa Goddy fowo gbemi loyan jo laise wi pe ife inu mi ni. Isele yii sele ni akoko ti mo duro nidiko lale, nigba ti mo n dari bo lenu ise oojo mi lati wo moto lo sile. Mo koju re wi pe kilofa katikati to n ba mi danwo. Ki n to mo ohun ti n sele, o ti bere si ni na mi to si fa aso mo mi lara. Ti ko ba se awon eniyan to wa nitosi ti won dasi, omokunrin naa ko ba seku pami lale ojo naa, ” Ifeoma se alaye bee niwaju adajo

     

    Omobirin Ifeoma tun fi kun un niwaju adajo naa wi pe, oun ko jebi esun ti won fi kan oun rara.

    Adajo agba, Alhaji Umar Kagarko, faramo idasile Ifeoma ti won ti gbeti mole pelu owo itanran egberun lona ogun naira (20, 000) ati oniduro to rese wale. Nigba ti won tun sun igbejo naa di ojo kesan-an osu karun-un odun yii (09/05/2016).

  • Owo Jegudujera Abacha: Ile ejo ti fesun kan Obasanjo ati Jonathan

    *Won tun ranse si Yar’Adua lode orun wi pe ko wa salaye
    *Ile ejo ti gbe ise to le fun Aare Buhari lati se

    Obasanjo, Yar’dua ati Jonathan

    Kootu ijoba apapo to gaju lo to kale siluu Eko, Federal High Court, ti fesun kan awon aare ti won ti n je lati odun 1999 ti ijoba awaarawa tipada latari aise isiro ati afihan okodoro iye owo ti won ri gba pada lowo awon onijegudujera ile yii, paapa julo, eleyii ti won ko lasuwon Sani Abacha ati bi won se na awon owo naa.

    Ile ejo naa ti wa n pe ijoba Muhammadu Buhari to wa lode yii lati tanna wadii awon ijoba ti won ti je seyin, bere lati odo Baba Iyabo, Olusegun Aremu Obasanjo, ijoba oloogbe Umaru Musa Yar’Adua, ati ijoba Goodluck Jonathan to kogba wole ni kopekope yii.

    Idajo yii lo waye lojo Eti to koja yii lati enu onidajo M.B. Idris, eni to pase eleyii lori ipejo ti ajo Socio-Economic Rights and Accountability Project (SERAP) gbe si iwaju ile ejo naa.

    Ninu alaye onidajo Idris lo ti n so wi pe, awon ijoba ateyin wa yii gbodo so iye owo ti won gba lo awon ti won ko owo ile yii je, iye dukia ti won ri ko lakata awon onijegudujera, a ti bi ijoba se na awon owo wonyii pelu ohun ti won na le lori.

    Wayio, awon onwoye lagbo oselu foju wo abajade ile ejo naa gege bi ise lile fun ijoba Buhari lati musaloogun. Akoko na, gege bi alaye won, Buhari ti se ileri fun Jonathan wi pe, oun ko ni yo o lenu bo ti n wule ko mo. Idaniloju yii lo waye ninu oro apileso akoko Buhari gege bi aare.

    Bi e ba si kiyesi, Buhari ko mu koboko re sun mo Jonathan lati igba to ti n fina mo awon asebaje lawujo. Nipa ti Ebora tiluu Owu, Obasanjo wa lara awon igi leyin ogba Buhari ni akoko ipolongo iyansipo re gege bi aare. Se eniyan a tun ma ge owo to fun ni lounje je bi? Yato si wi pe Yar’Adua je omo gambari, iku ti mu sagba, ko si ni fe wu Buhari lati tu u lasiri. Bi nnkan se wa ri yii, oro naa dabi ise oba aigbodo ma je, odo oba to kun ko si se e rolu. Ki wa ni ki Buhari se lori oro to wa nile yii?

  • “Awon soja yin mi ni bajinatu, won fe pami” – Olu Falae

    *Awon ika eniyan wo lo wa nidi isele yii?
    *Se agbanipa ni won tabi awon soja ti won se palapala nigboro?

    Oloye Olu Falae ni ori ti koyo bayii lowo iku ojiji nigba ti awon soja kan ti enikeni ko mo orisun won sadeede doju ibon ko moto re loju ona Akure si Ilesa.

    Baba yii lagbo wi pe o n rin irinajo lo si Ile-Ife lojo Isegun to koja yii nibi ipade awon Afenifere pelu Ooni tuntun, Oba Adeyeye Ogunwusi.

    “Igba wo ni awon ajinigbe si ji mi gbe na, nibayii, won tile n lepa lati pami ni.” Olu Falae se alaye fun awon oniroyin. “Akure ni mo ti n bo, nigba to ku die ta ma de Ilesa, a ri oko kan niwaju wa. Oko nla van kan naa si tun wa niwaju tie, niwaju loun. Oko to wa niwaju wa n gbiyanju lati sare ya oko van to wa niwaju lo un sile, bee gele ni awa naa ba tele. A ti fe koja won ni mo gbo tako-tako iro ibon lara oko mi.

    Oko van yii ko duro, o tun tena lo ni. Igba ti a de Erin-Ijesa la salaye ohun to sele fun awon olopaa ta a ri nibe wi pe, oko van nla kan tabon luwa ni ikorita Ile-Oluji”. Oloye Olu Falae tun n se alaye re siwaju pelu edun okan nla nipa awon isele ti n sele si i.

    “Mi o modi ti won fi jimi gbe titi di akoko yii, mi o modi ti won fi fi olopaa gbemi lodun 1997 ti won si timi mole fun odun meji gbako. Nibayii, won tile fe pami patapata ni,” Falae se alaye re bee pelu edun okan nla.

    Sugbon sa, iwadii ko ti fidi re mule boya awon agbanipa ni awon soja to yinbon tabi awon soja oniwa palapala ti won fibon dabira to wu won. Ju gbogbo re lo, iwadii awon olopaa si n tesiwaju lori isele naa.

  • Iyanu ti sele nipa awon omo Babington Ikorodu ti won jigbe

    Ni ojo Aje to koja yii (29/02/15) ni awon ajinigbe kan yawo ileewe Babington Macaulay ‎Junior Seminary School to kale si agbegbe Ikorodu nipinle Eko ti won si ji awon omo obirin akekoo meta salo raurau.

    Gege bi alaye ti oga agba ileewe naa, Ven Olaoluwa Adeyemi, se, o ni koto giriwo kan ni awon onisebi naa gbewole leyin ogba ileewe naa. Leyin ti won wole ni won bere si ni tabon tau-tau soke ti ina si n fo yo lenu ibon won bi igba ti Sango olukoso ba n binu. “Orisii ibon igbalode to wa lowo awon amokunseka naa lagbara pupo eleyii ti ko fun awon osise alaabo ileewe wa ni anfaani lati le doju ija ko won. Ologini foju jo amotekun ni, nnkan ju nnkan lo,” ogbeni Adeyemi se alaye naa bee.

    Lara iwadii ti OLAYEMI ONIROYIN kojo lojo Isegun (01/03/16) ni wi pe, awon ajinigbe naa ti n beere ogorun milionu (N100m) lori omo kookan eleyii ti won tun pada din owo naa si ogun milionu (N20m). Okan ninu awon akoroyin wa gbiyanju lati ba okan ninu awon omo tabi oluko ileewe naa soro lojo keji isele naa sugbon awon alase ileewe naa ti paalase fun won lati ma dahun ibeere awon oniroyin kankan.

    Ni ojo Wesde (02/03/16), Igbakeji gomina ipinle Eko to tun je komisanna fun eto eko, Arabirin Idiat Oluranti Adebule, se abewo si ileewe naa lati ba won kedun isele to waye naa. Bakan naa lo tun fi da won loju wi pe, ijoba yoo lo gbogbo agbara re lati gba awon omo naa pada wale.

    Oludasile ileewe naa, Dr Michael Fape, ko sai dupe lowo ijoba ipinle Eko pelu bi awon osise alaabo ipinle naa se dide ni kanmonkobo nikete ti won fi isele naa to won leti. Gbogbo agbegbe ileewe naa si ni awon osise alaabo gunle si bayii lati daabo bo emi ati dukia.

    Iru isele to jo iru eleyii ni eyi to sele ni oru ojo kerinla si ojo keedogun osu kerin odun 2014, nibi ti awon omobirin orinlugba o din merin (276) ti gbe di ohun awati ni Chibok. Bi o tile je wi pe lati igba naa ni awon omo ologun ile wa ti n ja raburabu lati ri awon omo naa ko wa le pada, sibesibe, ori igbiyanju naa ni ijoba apapo wa.

    Wayio, komisanna fun etigbo ati agbekale ilana fun ipinle eko, Steve Ayorinde, kede laaro oni ojo Sande (7/03/16) wi pe awon omo naa ti di gbigba pade wale latari iranwo awon agbofinro ilu Eko

  • Awon ojogbon fi oye dokita da Tinubu lola

    Oloye agba egbe APC, Asiwaju Ahamed Bola Tinubu ni won ti foye dokita dalola bayii ni ogba Yunifasiti tiluu Abuja. Idalola agba oloselu to je gomina ti yoo je sikejila (12th) nipinle Eko lo waye ninu ayeye ikojade awon akekoo gboye ileewe naa. Ayeye yii to waye yii ni i se igba ogun ti ileewe naa yoo ma se ayeye ikojade awon akekoo gboye lati igba ti wan ti se idasile re.

    Ti e ko ba gbagbe, laipe yii ni iwe iroyin SUN tile wa fi ami eye “Man of the Year” da Tinubu lola latari akitiyan ati akikanju re lati mu igba yipada fun ile Naijiria lagbo oselu. Oloye Tinubu, eni ti won fun loye Jagaban niluu Borgu to wa nipinle Niger, ko sai fi idunnu re han bi awon alase Yunifasiti Abuja se gbe aponle ati iyi oye dokita naa fun un. Eleyii to tun fi da won loju wi pe, oun ko ni duro ninu akitiyan lati mu igbe aye awon eniyan larinrin ju ateyinwa lo.

  • Rogbodiyan Mile 12: “Won ja omo ikoko gba lowo mi” – Abiyamo

    Leyin rogbodiyan to be sile ni agbegbe Mile 12 to wa niluu Eko l’Ojobo ose to koja yii (03/03/16), okunrin kan ti oruko re n je Daniel Igba lo ti ke gbajari sita wi pe, awon kan ja omo gba lowo oun nigba ti wahala naa gbena kari. Ninu itaporogan to waye laaarin eya awon Hausa inu oja Mile 12 ati awon Yoruba ni Ogbeni Igba ti gbe padanu omo re, eni odun kan ati osu meje ti ko si le so pato ibi ti omo na wa bayii.

    “Ile ni mo wa ni nnkan bi ago mewaa aaro nigba ti wahala naa wo inu adugbo wa. Mo sare gbe omo mi lati sawo ile lo. Sugbon bi mo se n salo ni awon eniyan naa sare tele mi leyin, won lemi ba, won si bere si ni na mi. Won fi ake sami lori ati lowo. Ni akoko yii, mo si gbe omo mi mora sibe naa. Bi mo se ni ki n tun dide ki n maa salo ni mo subu. Bayii ni won se ri omo naa jagba lowo mi. Lati igba naa, a ko ti ri omo wa. Iya re ko si nile ni akoko naa, o lo si ileewe,” Ogbeni Igba se alaye naa bee.

    Ninu ija nla to waye yii ni aimoye emi ati dukia ti gbe sofo ko to di wi pe awon omo ologun ile wa to wa dawo rogbodiyan naa duro.

  • Ipo wo ni iwo fe wa ninu awon olowo ile Afirika?

    Ni owuro yii, mo fi akoko mi sile lati ka nipa aseyori Mike Adenuga, alase ati oludari ile ise ibanisoro Gbobacom. Ohun to ta mi kan ko ju iroyin tuntun nipa re eleyii to n se afihan re gege bi enikeji to lowo ju lo bayii ni ile Afirika gege bi atejade tuntun Magasiinni Forbes agbaye odun 2016. Ninu awon eniyan bi merinlelogun (24) ti Forbe se alaye won gege bi borokini olowo julo ni ile adulawo, ipo kinni si ni Dangote dimu, Adenuga se ipo keji. Femi Otedola wa nipo kerinla nigba ti Arabirin Folorunso Alakija wa ni ipo kerindinlogun.

    Iwadii Forbes fihan wi pe, ohun ti Adenuga n je lere ti fo fere lati bilionu merin owo dollar ile Amerika lodun 2015 bo si billion mewaa owo dollar ninu odun 2016.

    Ohun kan ti mo fe fi dayin loju ni wi pe, ki i se gbogbo eniyan to rise gidi se ni won sanwo riba fun enikan ki won to fun won nise se. Bakan naa ni ki i se gbogbo olowo ile Naijiria ni won jale tabi gba ona alumonkoroyi ki won to deni atata lawujo.

    Eyin naa le ti apata dide, ke e si di bee di eniyan atata lawujo.

    Aseyori eda bere lati ibi ero okan re. Ohun ti e dimu gege bi otito ni o pada royin lara bi aso. Ti e ba gbagbo wi pe e pada doke, mo fi n dayin loju wi pe, ohun to seese ni. Nitori ero okan yin, igbagbo yin, bope-boya yoo pada royin lara bi aso. Ewu wa ninu igbagbo yin wi pe, eniyan ko le debi giga laise se wi pe o gba ona alumonkoroyi.

    Ti e ba ni iru ero bayii lokan, ohun ti e n so fun ara yin ni wi pe, e ko peye to lati se asela laye. Iru ero wo le dimu nipa igbe aye yin? Kini igbagbo yin nipa ojo ola yin? Oni le koro bi ewuro, sugbon e fi igbagbo yin sinu ola. E ma so ireti aseyori yin nu. E si ma fi gbogbo igba ro ire nipa igbe aye yin. E ma gbagbe ohun ti mo so saaju, orisii ero yowu ki e ni lokan, bope-boya, ero okan yin yoo pada royin lara bi aso. Olayemi Olatilewa ni oruko mi, ilu Naija olokiki ti n san fun wara ati oyin lemi n ja fun lojo gbogbo. E ku ikale!

    http://www.olayemioniroyin.com/2016/03/ipo-wo-ni-iwo-fe-wa-ninu-awon-olowo-ile.html