Àti ilé ìwé e gírámà ni èmi àti Kọ́lá ti jọ ń fẹ́ ra wa. Àwọn òbí i mi ò kí ń fẹ́ rí Kọ́lá pẹ̀lú u mi nítorí ààfín ni. Nígbà tí mo fẹ́ wo ile ìwé gíga ni bàbá à mi ní àìsàn an rọ́pá, rọsẹ̀,ọpẹ́lọpẹ́ kọ́lá tó san owó ilé ìwé è mi láti ìgbà tí mo wolé ẹ̀kọ́ gíga títí mo fi jádé.
Nígbà ti mo lọ ṣe agùnbánirọ̀ mo pàdé sẹ́nátọ kán,èmi àti ẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe wọléwọ̀de. Sẹ́nátọ̀ ra ilé fún mi, ó tún, tún ilé àwọn òbí ì mi kọ́.
Mi ò fi ọ̀rọ̀ ọ kọ́lá pamọ́ fún sẹ́nátọ̀, ṣẹ́nátọ̀ fún mi ni mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dógún pé kí n lọ fún Kọ́lá kó fi ṣe owó tó fi rán mi lọ ilé ìwé, Kọ́lá fárígá, ó ní dándán ni ki òun fẹ́ mi. Lọ́jọ́ mò mí n mọ̀ọ́ èmí àti sẹ́nátọ̀, Kọ́lá kọ́ àwọn jàndúkú wà ilé e wà láti wá da ayẹyẹ náà rù ṣùgbọ́n àwọn ṣọ́jà fí imú u wọn dánrin.
Ní ọjọ́ kejì tí mo ṣe mò mí n mọ̀ọ́, mo wá Kọ́lá lọlé ,mo bẹ̀ẹ́, mo purọ́ fún pé, mo kàn n fẹ́ ṣẹ́nátọ̀ láti fi gbá owó ọwọ́ ẹ̀ ni kí èmi àti ẹ̀ lè dìjọ kúrò nínú u ìṣẹ́ àti òṣì. Lẹ́yìn náà ni mo gbé ẹ̀fọ́ rírọ̀ àti sèmó ti mo ti fi májèlé sí fún Kọ́lá. Lẹ́yìn ọ̀ṣè mẹ́jì ni májèlé tí mo fún Kọ́lá jẹ yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́.
Ọjọ́ kejì tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀ ni mo kó ẹrù mí ti mo gbá ọ̀dọ̀ sẹ́nátọ̀ lọ nílùú Àbújá.
Sunday Igboho, ti kéde rẹ̀ fún gbogbo ọmọ Yorùbá pé ìforúkọsílẹ̀ láti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àbò “Iru Ekun Security Network” jẹ́ ọ̀fẹ́ ti kò sì ní ná kọ́bọ̀ kankan fún ẹnikẹ́ni tó fẹ́ yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún àbò ilẹ̀ baba rẹ̀. Nínú àlàyé tuntun tí wọ́n ṣe fún àwọn kòòdínétọ̀, Ìgbòho sọ pé wọn kò gba owó kankan lọ́wọ́ ará ìlú fún fọ́ọ̀mù nítorí pé iṣẹ́ náà jẹ́ ti ìfẹ́ orílẹ̀-èdè àti ààbò gbogbo ilẹ̀ Yorùbá láti dènà àwọn jandùkú àti adigunjale.
Ó tẹnumọ́ pé ẹnikẹ́ni tó bá ń gbowó fọ́ọ̀mù lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ń ṣiṣẹ́ lòdì sí ète ẹgbẹ́ náà, nítorí pé iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni tó mọ́ gaara ni láti dá ààbò bo àwọn oko ati igbó wa.
Olóyè Sunday Adeyemo ṣàlàyé pé bí wọ́n ṣe ń pín fọ́ọ̀mù ọ̀fẹ́ yìí, wọ́n ń ṣe ìwádìí kíkún lórí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ darapọ̀ mọ́ wọn láti rí i pé àwọn ènìyàn gidi tí kò ní àbàwọ́n ọ̀daràn nìkan ni wọ́n ń gbà wọle. Ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹgbẹ́ tuntun yìí ti forúkọ sílẹ̀ lábẹ́ òfin láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá àti ológun láti rí i pé gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ tẹ̀lé igbowo tó tọ́ láti dáàbò bò àwọn àgbẹ̀.
Nípa sísọ ìforúkọsílẹ̀ yìí di ọ̀fẹ́, ó ní èyí yóò fún gbogbo àwọn ọ̀dọ́ tó nìfẹ́ sí àbò ní àǹfààní láti dáàbò bò agbègbè wọn pẹ̀lú òfin lábẹ́ àbò Gómìnà láti mú àlàáfíà padà sí gbogbo ilẹ̀ Gúúsù-Ìwọ̀ Oòrùn.
Arápájà di Igbákejì Alága ẹgbẹ́ PDP níhà Gúúsù Orílẹ̀ yìí
Ọrẹ Akínṣọlá
Ṣé bóṣe wu Ọlọ́run Ọba ní-ín sọlá, èèyàn tó bá wù Ú ní-Ìn ṣe lógo. Igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nígbààa kan, Ọ̀gbẹ́ni Taofeek Arapaja, ti jáwé olúbori sípò Ìgbákejì Alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní Gúúsù ilẹ́ wa, ó sì fẹ̀yìn alátakò rẹ̀ tóun náà jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀sun tẹ́lẹ̀rí, Ọmọọba Ọlágúnsóyè Oyinlọlá, janlẹ̀.
Iṣẹlẹ yii waye lowurọ ọjọ Aiku, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹwaa yii, lasiko ti wọn n ka abajade ibo tawọn aṣoju to pesẹ sibi apero apapọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ọhun di, lati mọ ẹni to maa wa nipo igbakeji alaga ẹgbẹ lagbegbe Guusu Naijiria.
Ṣaaju ni awuyewuye ti wa pe ki ẹnikan ninu awọn ondije fun ipo Igbakeji alaga naa juwọ silẹ fun ẹnikeji, ko le dọgba pẹlu eto ti ẹgbẹ PDP ṣe lori awọn ipo ijoye ẹgbẹ yooku, leyii ti ko si alatako kankan, ayafi ipo Igbakeji alaga Ariwa.
Ṣugbọn ko sẹni to juwọ silẹ laarin Arapaja, ti Gomina Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ jẹ igi lẹyin ọgba fun gbagbaagba, ati Ọmọọba Oyinlọla ti gbogbo eeyan bọwọ fun bii ọkan lara awọn agba ẹgbẹ PDP. Eyi lo mu kọrọ naa di didibo le lori.
Lẹyin idibo, gẹgẹ bi Gomina Ahmadu Umaru Fintiri tipinlẹ Adamawa ṣe kede abajade rẹ, Arapaja ni ibo ẹgbẹrun meji o le mẹrin (2004), nigba ti Oyinlọla ni ibo ẹẹdẹgbẹrin o le marun-un (705), ninu ẹgbẹrun mẹta aabọ ati mọkanla (3511) aṣoju ti wọn pesẹ sibi eto naa.
Aropọ ibo marunlelọgọjọ (165) ni wọn ni ko wulo, wọn da a nu bii omi iṣanwọ ni, awọn aṣoju ojilelẹgbẹta din mẹta (637) ni wọn ko dibo lasiko idije ọhun.
Pẹlu eyi, Taofeek Arapaja ni Igbakeji alaga ẹgbẹ PDP niha Guusu ilẹ wa.
À ṣẹ kò sééyan táyé ò lé bá ṣọ̀tá, ó tún hàn pé wọ́n le bínú òkú ọ̀run , yàtọ̀ sèèyan tí wọ́n jọ ń wà láyé. À bí kín ní ká tí pé tàwọn kọ̀lọ̀rànsí t’ọ́wọ́ Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti tẹ̀ báyìí pé wọ́n digunjalè sọsẹ́ nílé olóògbé Olóyè Moshood Abíọ́lá tó wà ní Ìkẹjà nílùú Èkó níbi tí wọ́n ti jí nǹkan tó tó ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù lọ.
Abíọ́lá ló jáwé olúborí nínú ìbò Ààrẹ gbogbogbòò tó wáyé lọ́dún 1993 èyí tí Ọ̀gágun fẹ̀yìntì Ibrahim Babangida wọ́gilé nígbà náà.
Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá nípìńlẹ̀ Èkó, Hakeem Odumosu ló sọ pé ọwọ́ àwọn agbófinró ti tẹ àwọn amòòkùnṣèkà ẹ̀dá ọ̀hún tí wọ́n yabo ilé Abíọ́lá L’ọ́jọ́rùú.
Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá tó sàbẹ̀wò sí ilé ọ̀hún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé mẹ́ta làwọn olè ọ̀hún ṣùgbọ́n ọ̀kan lára wọn ló gbé ìbọn dání.
Ọ̀gbẹ́ni Odumosu ní ”ẹbí Abíọ́lá sọ f’óun pé àwọn olè náà jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ góòlù àti owó lọ.”
”Àwọn agbófinró ti wà lojufo báyìí lágbègbè ìkẹjà tí ilé náà wà tó fi dé ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá tó wà ní ibodè Ìdírókò àti Seme,” Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá ló sọ bẹ́ẹ̀.
Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ní kò sí ẹni tó farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà nínú ìyàwó Abíọ́lá, Bísí àti ọmọbìnrin méjì tó wà nílé.
Ọ̀gbẹ́ni Odumosu fikún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìwádìí ṣì ń tẹ̀ síwájú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Àwọn Aládùgbóò tó báwọn akọròyìn ṣọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé géètì tó wà lẹ́yìn làwọn olè bá wọlé, wọ́n ní láago mẹ́rin ìdájí ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé nígbà táwọn ẹṣọ tó wà nínú ilé náà ti sùn lọ.
Bí ọmọ èèyàn bá wá sílé ayé, ìgbàgbọ́ Yorùbá ní pérúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ wáyé wá nájà ni. Ènìyàn ò sáà lè tajà tán kò sùn sínú ọjà, àti pé n tí kóówá gbe wá sínú ayé fún títà kò papọ̀.
Ìbà Ọ̀jẹ́túndé Asòlẹ̀kẹ̀ Olorì alágbàáà àná tó sílẹ̀ bora. Ó ní èèyàn tó wáyé wá ta góòlù kò papọ̀ mọ́ tẹni wáyé wá ta ẹ̀kọ. Ẹni o wá tẹ̀kọ ṣe é ṣe kó tètè sẹ́rí wálé, góòlù kò yá títà bí ẹ̀kọ. Gbogbo àsamọ̀ yìí ló díá fún pé n tá a bá wá tá láyé ní yóó ṣọ bí ìrìnàjò yóó ṣe pẹ́ tó tàbí yá sí.
Kò sí nínú ìròyìn mọ̀ pé Kofi -19 ń soro bí agbọ́n láàrin àwọn èèkàn ọmọ bíbí Orílẹ̀ yìí tó lóókọ lóókì, ọ̀kan pàtàkì sí ní Buruji Kashamu ẹni tí a fi àkójọpọ̀ ìwòye àwọn èèyàn lẹ́yìn rẹ̀ sọ di ìròyìn.
Ṣé lọ́jọ́ a kú làá dère, èèyàn ò sunwọ̀n láàyè. Gbólóhùn yìí ló bi Onírúurú gbólóhùn tó ń fọhùn lẹ́yìn ikú èèkàn olóṣèlú n nì,Buruji Kashamu. Ṣé gángan láyé pẹ̀lú ojú méjì, ìbí tó bá sì gbà kójú sí kóówá ní yóó ṣọ bí ìròrí rẹ̀ yóó ṣe lọ.
Bí àwọn ìlúmọ̀ọ́ká àti olókoòwò ṣe n dárò àgbà ọ̀jẹ̀ olóṣèlú náà ló fẹ́ ẹ̀ jẹ́ àrà ọ̀tọ̀. Díẹ̀ lára àwọn tó ṣọ tinú wọn ni Olóyè Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ Ẹbọra Owu. Bàbá náà ṣọ̀rọ̀ ìkẹ́dùn pé olóògbé náà kú . Bẹ́ẹ̀ ló bó o lójú pé Buruji khasamu rí gbogbo àǹfààní òfin lò láti borí àwọn Onírúurú ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án nílẹ̀ yìí àti lókè okùn síbẹ̀ ikú ti wá mú un lọ.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, Dàpọ̀ Abíọ́dún ti sàpèjúwe Sẹ́nétọ̀ Búrùjí Kashamu gẹ́gẹ́ bí ẹni tó nífẹ̀ẹ́ ọmọnìyàn.
Gómìnà ní bótilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kò jọ sí nínú ẹgbẹ́ òṣèlú kan náà, síbẹ̀ òun mọ̀ pé Sẹ́nétọ̀ náà ti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ gidigidi. Àgbà òṣèlú àti adarí ẹgbẹ́ APC nílẹ̀ yìí Olóyè Bola Ahmed Tinubu tí sàpèjúwe Sẹ́nétọ̀ Búrùjí Kashamu gẹ́gẹ́ bí olóṣèlú tó fẹ́ràn àwọn èèyàn rẹ̀ tó sì nífẹ̀ẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tó nígbàgbọ́ nínú rẹ̀.
Ó ní . Bruce ni ọ̀rẹ́ wọlé wọde ni òun àti Kasamu kó tó jẹ́ Ọlọ́run nípè. Ó ròyìn ẹ̀ pé èèyàn rere ni àti pé ikú olóògbé náà jẹ́ ìmọ̀lára fún òun.O gbàá ládùúrà pé kí Ọlọ́run fáànù gbàá.
Gómìnà t’ẹ́lẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì, Ayodele Fayose náà wà lára àwọn tó kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn ọmọ Orílẹ̀ yìí àti ẹbí olóògbé.O ròyìn rẹ̀ pé ojúlówó olóṣèlú tó fẹ́ràn àwọn èèyàn ẹkùn rẹ̀ ni.
Ó ní ẹ̀dá kìí rìn kórí ó mọ́ mì, kò sééyan tí wọ́n wọ́n sí abíyá ẹ̀ sókè tí kò ní rùn. Èyí ló fi fèsì sí ọ̀rọ̀ tí Olóyè Olúṣẹ́gun Obasanjọ ṣọ lórí olóògbé Búrùjí Kashamu. Bí ó ó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú olóògbé náà kò tẹ́yìn mọ́, síbẹ̀ ìtàn àṣesílẹ̀ n fọhùn lẹ́yìn olóògbé Búrùjí Kashamu. Níwọ̀n ìgbà tí èèyàn tí kò tíì kú kò mọrú ikú tí yóó pa á, ẹ jẹ́ á gbìyànjú ká nítàn réré, ṣaájú ọjọ́ àtisùn un wa.
APC kò ní ì ṣe ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Òǹdó àyàfi.. Olùdíje kan
Láìpẹ́ yìí ni ìròyìn kàn pé ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress (APC) tó ń ṣe àyẹ̀wò àwọn olùdíje lábẹ́ ẹgbẹ́ náà sọ pé Segun Abraham ni kò kójó òṣùwọ̀n tó nínú àwọn tó ń díje nítori náà ni won ṣe yọ.
Segun Abraham jẹ́ ọ̀kan lára àwọn méjìlá tó ń dije lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ APC tó sì ti gbá ìwé láti fi èrò rẹ̀ hàn pé, òun ṣetan láti kópa nínú ìdìbò abẹ́lé ẹgbẹ́ náà ti yóò wáye ní Ogúnjọ́, Oṣù Keje ọdún yìí.
Sùgbọ́n nínú ìfọ̀rọ̀wáni lẹ́nu wò tí akọròyìn ṣe fún olùdíje náà, Ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé títí di àsìkò yìí, ìgbìmọ̀ kò ti fi tó òun léti pé òun ni wọ́n yọ.
Títí di àsìkò yìí mí ò ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìgbìmọ̀ àyẹ̀wò pé èmì ni wọ́n yọ, tàbi ki wọ́n kọ lẹta nípa rẹ, wọ́n ni, wọ́n ni, ní mò ń gbọ́.”
Àwọn tí wọ́n jọ díje ni Joseph Olusola Iji, Odimayo Okunjimi, Olayide Owolabi Adelami, Isaacs Duerimini Kekemeke, Olusola Oke Alex, lfeoluwa Olusola Oyedele àti Olajumoke Olubusola Anifowoshe.
Àwọn tó kù ni Awodeyi Akinsehinwa Akinola Colinus, Olubukola Adetula, Dr. Abraham Olusegun Michael, Gomina Rotimi Akeredolu ati Dokita Nathaniel Adojutelegan.
Ajakale arun coronavirus ti n pa eni kukuru, to n pa eni giga, ti ko mo olowo yato fun talaka, ko mo oba bee ni ko mo ijoye, ko ki n ja ija elesinmesin, ko si ohun to kan an pelu eleyameya.
Ajakale ohun naa lo ko lu odidi bii gomina mejo ni orileede yi, ni eyi ti Arakunrin Rotimi Akeredolu wa ninu won. Ose to koja lo kede funra re pe ayewo oun gbe arun coronavirus jade. Gomina yii ba lo fun iwosan, o bere si ni sise ofiisi nile.
Gomina yii naa lo tun kede ni irole oni pe ki a ba oun dupe nipa esi ayewo to tun jade lonii ti o si gbee pe aisan naa ti kuro ni ago ara Gomina Akeredolu.
Atiku, Saraki, Dogara ati Melaye lè má bó̩ nínú e̩jó̩ jìbìtì Hushpuppi- APC
Ogbeni Ramoni Igbalode Abbas to je omo Naijiria ti owo te ni ilu Dubai pelu esun jibiti lilu lori ero ayelujara lose to koja ni egbe oselu APC ni owo PDP ko mo nibe.
Gege bi atejade to egbe oselu APC gbe jade nipa irinkurin egbe oselu PDP paapaa julo ni asiko idibo odun 2019 to koja. APC ni ki won to so pere, won ti ko ara won lo Dubai fun ipade.
APC ni iru ipade wo ni won n lo se ni orileede naa ti ko see se ni Naijiria. APC tun ni gbogbo foto ti won ya pelu Hushpuppi nibi ipade ati gbogbo ohun to da won po lo maa jade laipe.
APC ni o da awon.loju to ada pe awon oyinbo maa wadii gbogbo irinajo Ogbeni afunrasi naa.
Gege bi atejade egbe APC ti igbakeji akole agba egbe naaogbeni Yekini Nabena fowl si, APC ni ki egbe PDP maa se sun asunpiye nitori ejo naa ti kuro ni Dubai lo si Chicago ni orileede Amerika. O ni afaimo ki Ogbeni Hushpuppi ma se fi ewon ogun odun gbara.