Home / Àṣà Oòduà / APC kò ní ì ṣe ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Òǹdó àyàfi.. Olùdíje kan

APC kò ní ì ṣe ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Òǹdó àyàfi.. Olùdíje kan


APC kò ní ì ṣe ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Òǹdó àyàfi.. Olùdíje kan

Láìpẹ́ yìí ni ìròyìn kàn pé ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress (APC) tó ń ṣe àyẹ̀wò àwọn olùdíje lábẹ́ ẹgbẹ́ náà sọ pé Segun Abraham ni kò kójó òṣùwọ̀n tó nínú àwọn tó ń díje nítori náà ni won ṣe yọ.

Segun Abraham jẹ́ ọ̀kan lára àwọn méjìlá tó ń dije lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ APC tó sì ti gbá ìwé láti fi èrò rẹ̀ hàn pé, òun ṣetan láti kópa nínú ìdìbò abẹ́lé ẹgbẹ́ náà ti yóò wáye ní Ogúnjọ́, Oṣù Keje ọdún yìí.

Sùgbọ́n nínú ìfọ̀rọ̀wáni lẹ́nu wò tí akọròyìn ṣe fún olùdíje náà, Ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé títí di àsìkò yìí, ìgbìmọ̀ kò ti fi tó òun léti pé òun ni wọ́n yọ.

Títí di àsìkò yìí mí ò ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìgbìmọ̀ àyẹ̀wò pé èmì ni wọ́n yọ, tàbi ki wọ́n kọ lẹta nípa rẹ, wọ́n ni, wọ́n ni, ní mò ń gbọ́.”

Àwọn tí wọ́n jọ díje ni Joseph Olusola Iji, Odimayo Okunjimi, Olayide Owolabi Adelami, Isaacs Duerimini Kekemeke, Olusola Oke Alex, lfeoluwa Olusola Oyedele àti Olajumoke Olubusola Anifowoshe.

Àwọn tó kù ni Awodeyi Akinsehinwa Akinola Colinus, Olubukola Adetula, Dr. Abraham Olusegun Michael, Gomina Rotimi Akeredolu ati Dokita Nathaniel Adojutelegan.

http://iroyinowuro.com.ng/2020/07/16/apc-ko-ni-i-%e1%b9%a3e-idibo-ni-ipinle-o%c7%b9do-ayafi-oludije-kan/

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

ojo keji

Ó San Owó Ilé Ìwé Mi Títí Mo Fi Jáde, Ṣùgbọ́n Mo Fi Májèlé San!

Àti ilé ìwé e gírámà ni èmi àti Kọ́lá ti jọ ń fẹ́ ra wa. Àwọn òbí i mi ò kí ń fẹ́ rí Kọ́lá pẹ̀lú u mi nítorí ààfín ni. Nígbà tí mo fẹ́ wo ile ìwé gíga ni bàbá à mi ní àìsàn an rọ́pá, rọsẹ̀,ọpẹ́lọpẹ́ kọ́lá tó san owó ilé ìwé è mi láti ìgbà tí mo wolé ẹ̀kọ́ gíga títí mo fi jádé. Nígbà ti mo lọ ṣe agùnbánirọ̀ mo pàdé sẹ́nátọ kán,èmi àti ẹ̀ sì ...