Author: oodua

  • Diezani Alison-Madueke Wo gau! Madaamu Naa Setan Ti O Foju Bale Ejo

    Owo awon olopaa ilu London ti te Diezani Alison-Madueke to je minisita fun epo robi nigbakan labe isejoba Goodluck Jonathan. Alison-Madueke ati awon merin kan ni owo te laaro ojo Eti to koja yii pelu esun Jegudujera, riba ati sise owo ilu mokumoku.

    Ogbeni Joseph Abuku to je alukoro fun ile ise asoju ijoba ile Biritiko ni ile Naijeria jeri si i wi pe lotito ni awon agbofinro ilu London ti gbe awon eniyan marun-un kan ti won je omo Naijeria laaro ojo Eti. Sugbon okunrin naa ko lati daruko awon eniyan ti owo te naa.

    Laaarin wakati meji ti won so Alison-Madueke sinu gbaga niluu London, awon ajo EFCC gbera lo fi agadagodo ti ile madaamu naa pa eleyii to wa ni Asokoro niluu Abuja.

    Orisirisi awuyewuye lo ti n jeyo lori ero ayelujara nipa bi won se mu Alison-Madueke.  Awon kan ni Buhari lo wa nidi isele naa nigba ti awon kan gba wi pe oseese ko je lara iranwo ti awon ilu okeere pinnu lati se fun aare Buhari latari awon abewo re si awon olori orileede agbaye ni awon akoko kan seyin.

    Saaju igba yii, lara atejade to te Olayemi Oniroyin lowo fi han wi pe iye owo bi bilionu mejilelogbon owo dola ile Amerika ($32b) lo poora ninu asunwo ile ise epo NNPC ile Naijeria ni akoko ti Alison-Madueke je minisita fun epo robi.  Ju gbogbo re lo, nigba ti o fi di asaale ojo Eti kan naa ti won mu Alison-Madueke, awon olopaa ilu London tun pada gba beeli re nipase oniduro to rese wale.

    Sugbon won ti gba iwe irinna re, won si tun ni ko pada fara han ni Charin Cross Police Station lojo Aje, ojo karun-un osu kewaa odun yii lori esun kan naa ti won mu fun.  Ojo to n ro ti o ti da kosi eni moye eni ti o pa. Iroyin to jade nipa bi won se mu obirin akoko ti o je minisita fun epo robi ti bere si ni da aibale okan sile fun pupo lara awon igbimo ijoba ana.

     

    Orisun:

  • Ohun to mu Odun Ominira eyi yato si ti igba ti Goodluck Jonathan wa lori oye

    Ara opo awon omo Naijiria tun ya gaga si orile ede won lojo Alamisi to koja, nigba ti a se ayeye ominira odun karunlelaadota.
    Kaakiri awon ipinle, opo eniyan lo ki akegbe won ku oriire, ti won si n soro lori ireti pe nnkan yoo pada bo sipo fun Naija.

    Awon onmoran woye pe igbagbo ninu ijoba Aare Muhammadu Buhari lo fa eyi, tori awon eniyan gba pe o fe fi otito inu tun ilu to.

    Idi niyii ti ko fi yani lenu pe opo eniyan lo ra asia Naijiria, ti won si ta a si ara moto won.

    Lori ero alatagba intaneeti naa, awon enyan n kira won, ti won si n ka aseyori Buhari.

    Odun 2015 yii ko ni igba akoko ti orileede Naijeria yoo maa yo ayo ominira. Odun eyi to wole lo je odun marundinlogota (55) ti ilu awon eniyan dudu to poju lo lagbaaye yoo maa yo ayo bibo lowo awon oyinbo amunisin.

    Bi o tile je wi pe teru-tomo pata ni won fo fayo lojo kinni osu kewaa odun 1960 latari akikanju, ifomoniyanse ati ilakaka awon akoni igbaani bi Nnadi Azikiwe, Obafemi Awolowo ati Ahamadu Bello; sugbon nigba to ya, irewesi n de ba awon omo Naijiria nipa yiyo ayo odun ominira eleyii ti opolopo gba gege bi omi inira.

    Eleyii ko sadeede waye, jegudujera, riba gbigba, ojelu, aisododo, ainife ara ilu to gbile laaarin awon alase ati olori ile yii lo bu omi tutu si okan awon eniyan.

    Aimoye ibeere ni awon eniyan n beere lati ojo pipe eleyii ti enikeni ko ri idahun si. Kilode ti Naijeria to kun fun wara ati oyin n sun lebi? Kilode ti omo eleran n jeegun? Kilode ti omo alaso alaari wo akisa kiri igboro?

    Leyin eto idibo aare to waye lojo kejidinlogbon osu keta odun ta a wa yii, igbagbo awon eniyan ko ja wale eleyii to fun ireti awon ara ilu lagbara ninu isejoba Aare Muhammed Buhari.

    Bi o tile je wi pe o pe ki Buhari to yan awon minisita ti won yoo jo maa sise gege bi igbimo, sibesibe iyipada to loorin ko sai foju han nipa ina monamona, igbogun ti iwa jegudujera, ifese mule eto abo ati igbenusoke eto oro aje bi baalu to setan ti o fo soju orun.

    O ku ojo bi meloo kan ti ayajo ominiran odun yii yoo wole, bee ni atejade kan bere si ni fo kiri ori ero ayelujara eleyii to n se afihan iye owo ti ijoba to kuro loye, Ijoba Goodluck Jonathan, ti i na lori ayeye ayajo ominira ati eleyii ti aare tuntun to wa lode yii setan lati naa fun ayeye kan naa.

    Atejade naa ni yii:
    Ijoba Jonathan 2011:
    Bilionu metala (13b)

    Ijoba Jonathan 2012:
    Bilionu meedogun (15b)

    Ijoba Jonathan 2013:
    Bilionu merinla (14b)

    Ijoba Jonathan 2014:
    Bilionu mejilelogun (22b)

    Ijoba Buhari: 2015:
    Aadorin Milionu (70m)

    Awon iroyin to jade yii tun bo mu inu opolopo dun eleyii mu won jigiri si ajoyo ayajo ominira odun yii ju ti ateyin wa lo.
    Sugbon sa, ajoyo ayajo odun ominiran ko fi bee rinle ni awon ipinle bi Osun ati ipinle Oyo.

    Sebi awon Yoruba bo, won ni aja ti o yo kii ba eyi ti ko yo sere. Bi ijoba awon ipinle naa se je awon osise lowo ko je ki inu awon eniyan dun debi wi pe ara won yoo ya gaga.

    Sebi bi oode ko dun, bi igbe niluu ri.

    Orisun: Olayemioniroyin.com

  • Awon Oruko Minisita Buhari Lati Enu Awon Omo Naijeria Niyii

    Awon Minisita Buhari: Niwon igba ti awon ara ilu si n reti oruko awon eniyan ti Aare Buhari fe fi je minisita, awon oruko wonyii ni awon ara ilu ni oseese ko jeyo ninu awon oruko minisita ti Buhari ko ni pe gbe jade.

    1. Prof. Tam David West
    2. Femi Falana (SAN)
    3. Lt.-Gen. Abdulrahman Dambazu (rtd)
    4. Prince Olagunsoye Oyinlola
    5. Wale Edun
    6. Abubakar Malami (SAN).
    7. Mrs. Ifueko Omoigui-Okaru
    8. Chief Bode Mustapha
    9. Engineer Segun Oni
    10. Dr Kayode Fayemi
    11. Dr. Abba Ruma
    12. Chief Kanu Agabi
    13. Donald Duke
    14. Babatunde Raji Fashola
    15. Chibuike Rotimi Amaechi
    16. Rotimi Akeredolu
    17. Rabiu Musa Kwankwanso
    18. Festus Odimegwu
    19. Engineer Funsho Kupolokun
    20. Yinka Folashade Oredola
    21. Bisola Adegbenro
    22. Isaiah Danjuma (omo TY Danjuma)
    23. Dele Momodu
    24. Kehinde Lawanson
    25. Chief Bayo Ojo (SAN)
    26. Pat Utomi
    27. Charles Chukwuma Soludo

  • Ajimobi ati Amosun Da Ara Ilu: Won Ni Ko Si Eko Ofe Mo


    Lati inu iwe Iroyin Owuro to jade lose to koja ni iroyin naa ti jade wi pe Ajimobi ati Amosun ti pada ninu ileri eto eko ofe ti won se ileri re fun awon ara ilu. Won ni ki olomu da omu iya re gbe; won ni ki awon obi maa san owo idanwo asejade (WAEC) awon omo won funra won.

    Ki ni ero awon eniyan nipa igbese tuntun yii? E le ka awon ero ara ilu ninu linki isale yii.

    Orisun

  • Se N’Ibadan Tia Nile Oluyole?

    Ibadan tia!

    Se n’Ibadan tia?
    Ibo lawa o mo lOluyole Ibadan?
    MAPO d’AYẸYẸ
    Gbogbo ODÍNJÓ tia ni,
    ELEKURỌ, ALEKUSỌ,
    Ibo gan-an lawa o mo n’Ibadan?
    BẸRẸ titi to fi de ÒÓPÓ Yoosa,

    Ibi to ku taa mo ni ke e wi,
    Sebi Ibadan fe pupo.

    ISALE AAFA, GBAREMU,MOSFALA,
    Olayemi oba mo mọ Ibadan.

    AGODI to fi d’ALAKIA ISEBỌ
    Mo ti gba MỌKỌLA de YEMETU ri
    Emi ti gba ỌJỌỌ de SASA pada bo.
    ODO ỌNA yato s’ODO ỌNA ELEWE
    Melo la fe ka n’Ibadan tiatia
    Ka maa paro, Ibadan fe ju orileede ibo mii lo.

    E tun le ka si nipa Ibadan nibi: www.olayemioniroyin.com/2015/08/ibadan-omo-ajorosun-ohun-to-ye-ke-e-mo.html?m=1

  • Tai Solarin Dilu Nla

    Tai Solarin dilu nla
    Tai Solarin ile ẹkọ nla to dilu nla.
    Ibi ọgbọn gbe pamọ si.
    Arọni imọ ti n ja ni laya bi oke.
    Gbékanlùkan isẹ ọpọlọ to fakíki.
    Kinihun o jẹran ikaṣi.
    To ba jọ bi irọ,
    Ẹniso n’Ijgun nibi ise akada gbe gbona bi ajere.

    Iba fun dokita ti n fi efun gbomola ni kilaasi.

  • Olopaa Ko Le Mu…

    Okan lara awon aworan to jade lati ipinle Bauchi sori ayelukara lojo odun ileya to koja ni yii.  Lotito, olopaa ko le mu won. Nitori olopaa kan wo won lotito ko si le da won duro. Sebi odun lo de.

  • Enu Kofi Omo Ghana Pada Re Ba a Lese


    Eyin eniyan mi, ohun kan se pataki ti mo fe ko da wa loju; ti mo si fe ki oye re ye wa gidi.  Igbe aye eniyan wa ninu oro siso tabi ohun ti a fenu se ijewo re. Iru igbe aye ti eniyan yoo gbe ni i se pelu awon oro to n jade lati enu re. Eniyan si le ya aworan iru igbe aye to fe gbe nipa awon oro ti n jade ninu enu re.

    Ti Yoruba ba ni “enu re ba eniyan lese.” Ohun ti won so ni wi pe enu ko ba eniyan. Sugbon bi a ba tu wo akanlo ede naa daada, a ri wi pe enu lo sokunfa ipo ti ese gbe eniyan de.  Aimoye awon eniyan ni won ti ko sinu wahala kan tabi ekeji nipase oro enu. Oro enu dabi obe oloju meji bi obe gambari ni. Bo se ran awon kan lowo bee lo n koba awon kan.

    Ohunkohun to seese ko sele niise pelu orisi oro ti n jade lenu wa. Iru awon oro wo lo n jade lenu yin? Nitori oro enu yin ni ese yin ba sise. Oro te e fenu so, ni ese yin sise pelu. Ohun kan naa lo si n dari igbe aye eniyan. Ilu Ibadan ni mo ti se kekere, mo ranti okunrin ara Ghana kan ti n sise gbegilere leyinkule ile wa. Ti okunrin yii ko ba nise ti n se lowo tabi ti owo re ba dile, lara awon oro to maa n jade lenu re ni ‘ehin erin’.

    A ni ti oun ba ri ehin erin, aye oun ti dara. Gbogbo igba ni i soro ehin erin; yala awada tabi igba ti o sawada. Ko le soro meji ko to menu ba ehin erin. Die lo ku ki awon ara ile wa maa pe ni “ehin erin” nigba naa. Emi o mo pataki ehin erin nigba naa, sugbon nipase Kofi ni mo fi mo wi pe ohun iyebiye bi igba eniyan ri ojulowo goolu ni ehin erin ni awon akoko yii.

    Igba to ya ni Kofi ko kuro leyinkule ile wa nibi ti soobu re wa.(Inu soobu naa ni Kofi n su). Leyin to ti ko kuro ni ile wa nigba naa ni iroyin kan wa wi pe okunrin naa ti ri ehin erin ti n wa. Bakan naa la gbo wi pe o ti rin irin-ajo lo silu Oba. (O seese ko je wi pe ehin erin to ri lo mu ko kuro ni ile wa nigba naa).

    Leyin bi osu mejo ti Kofi ti kuro nile wa, mo pade re lojo kan. Bi won ko tile yanu so fun eeyan, irisi Kofi fihan lotito wi pe ara oke okun ni.

    Eniyan dudu ni, dudu re n dan, bee lo tutu bi ara omo tuntun jojolo. Kootu dudu lo wo pelu seeti funfun labe kootu. O rerin si mi, ehin re funfun bi yinyin. O fu mi lowo, o ni ki maa ki iya mi ti mo ba dele. Mo n wo akoyinsi Kofi lo, kootu re gbe tekiteki bee lo le mo o lara bi oga banki, o dan bee ni i ko yeriyeri.

    Mo boju wo owo naira marun-un, eyo meji to ko le mi lowo, aganra ni; ontoosi bi asa Kamo. Mo fi imu gboorun owo naa, orisi turari ti n run lara Kofi ni i run lara owo naa. Abi maanu yii fi turari sowo ni? Mo sare ko sapo, mo si mori le ona ile. Igba ti mo ri Kofi Keyin re ni igbe aye mi. Ayafi ti maa ba tun foju kan lola. Igba kan ni won tile so wi pe okunrin naa ni oun ko ni pada si Naija mo. Ilu eebo ti dun mo gbaa.

    Bi mo tile kere, sibesibe, mo mo iru igbe aye ti Kofi n gbe tele. Salubata oniroba ti won wo lo baluwe ni i wo kiri aye. Gbogbo igba ni ara re maa n bu to ba n sise lowo, se eranti wi pe gbegilere nise re? Kofi ana lo ti pada di eniyan pataki lonii ti n re oke okun bi eni lo Bariga. Dafiiidi so fun Golayaati omiran wi pe oun yoo ge ori re kuro lorun re. Bibeli so wi pe Dafiidi ko ni ida lowo ni akoko to n soro yii, sugbon oro to so pada wa si imuse.

    Nje eyin tile ti se iwadii ohun ti obirin onisun eje so ko to kuro nile?

    Ipo ti e wa lonii le buru jai, sugbon isoro ti e n la koja ko se pataki bi ohun ti e n fi enu yin so jade nipa igbesi aye yin. Kini awon ohun ti e n so nipa igbe aye yin ati ojo ola yin? Nitori oro enu yin yoo pada “re ba yin lese.” Ese yin ko si ni sai gbe yin debi ti oro enu yin so nipa re.

    Olayemi Olatilewa ni oruko mi. Sultan Akoroyin to gbamuse ni won pe mi niluu India. Laipe, okiki mi ko ni pe kan kari aye. Bi won ka awon olowo aye, oruko mi ko ni gbeyin nibe laelae. Sebi ire ni mo yan, Eleda mi lo kobi.

    E ku isimi oni!

  • Ogo Omu-Aran Ni Ipinle Kwara Pe Eni Odun Mokanlelogota (61)


    Oni, 27-09-2015, ni Bisoobu Dafiidi Olaniyi Oyedepo pe eni odun mokanlelogota (61). Omo bibi Omu Aran ni ipinle Kwara ni i se, oun kan naa ni oluso aguntan agba fun ijo Living Faith Ministry to kari aye pata. Onkowe ni, olukoni oro Olorun ti okiki re kan kari aye ni, bakan naa lo tun je oludasile ile iwe. A ba olojo ibi yo lonii, a si gbadura wi pe Olorun yoo so agbara Bisoobu dotun. Igba odun, o dun kan ni.

     

    Source: olayemioniroyin.com