
Ase !!
Author: oodua
-
Anu opolopo obinrin si se mi lojo oni !
Hunmmmmmm, Ẹ ku ọsan o, e ku ataaro o, o ga o, anu opolopo obinrin si se mi lojo oni, nitori opolopo ninu won lo ti so aponle ara re nu niti tori eja #300 ati hi malt #100, tabi tori aso #1,500 won ni awon nse ayajo ololufe. Awon oponu ayirada nigba ti o si je pe opolopo ni ko mowe ti won ya olodo kale, e lo wo itumo valentine dada ki e mo itu mo re ni odoodun ni awon okunrin fi nba aye awon obinrin je sibesibe won o gbon ni. Nigbati kosi si iberu olohun lara gbogbo wa.

Sebi won ni iberu olohun ni iplese ogbon, e je ki gbogbo wa beru olohun. Ki awa naa le ni ayo okan, olomo kan wa po lo bisu ewura, e wa ni awon okunrin gidi kife olomo kan talo ma ri agbebo edie loja to ma kowo le, e je ka sora ki a ma tori ede ba ode je. Oro mi ko po, die to fun ologbon eniyan. Ire ooo -
Egbo eyin eniyan mi Kinni Opin eda laye?

Edakun e ba wa dasi oro to nlo
Egbo eyin eniyan mi Kinni Opin eda laye? -
E ku ojumo eyin omo ile kaaro ojiire. Se daada ni?
Mo gba l’adura wipe bi a tin jade lo fun ise oojo wa, ao ni ko el’esu l’ona. Iko ki n ko ejo l’ese, ayun lo ayun bo l’owo n yun enu. Atepe ni ese n te’na. Ire ila oorun, iwo oorun, gusu oun ariwa ki eledua gbe ko wa. A pa m’owo owo, ata jere oja.

Ewe gbegbe ko gbe ire to wa wa,
ewe ewuro ko je ki oloore wa ko mu ti wa ro.
Ona ki n di mol’oko, ona ki n di mo al’ada, ona ko ma se di mo wa.
Ire l’oju owo nri, ire la o ma ri.Aseye ni alakan n s’epo, aseye la o se.
Ase





