Kabiesi re Edua! a se otito ni oro awon agba to sope mejimeji ni Eledua da eniyan. OUN TO BA JO(resemble) OUN LA FI WE ARAWON EPO-EPA JO POSI ELIRI OWO-ALABAUN JO HANHAN-OPE. tani arakunrin-olokada yi jo(resemble)?
Category: Àṣà Oòduà
Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.
-
Ogulutu Oro Toni
Igbiyanju loma ngbeni de ipo ola
Igbiyanju loma njeki kadara o se
# wo
Oremi masinmi igbiyanju oo ki o le dele ileri
Majeki isoro kisoro kopa okanre da Lori ipinu ayo re
Tepa mose re loni
Ki osi mo wo owolowo juen yio dara fun oooo.
IRE OO OOOO -
Iwure Owuro – 05.07.2016
E MAA WI TELE MI :
……..
*Edumare ma se je ki n fi ota s’ore.
*Oluwa gba mi lowo afoju-feni ma fokan-feni.
*Edumare gbe mi leke abinu eni.
*Oluwa ma se je ki n je egungun kehin eran.
*Edumare ma se je ki n subu fun ota yo(Ase). QE KU OJULONA #IBILE_FESTIVAL_SEASON1.
……….
Ilu ibile.
Ijo ibile.
Orin ibile (Ewi, Ijaala, Esa).
Iwosan ibile.
Ounje ibile.
Aso ibile.
#IBILE2016
……..
Fun ekunrere alaye : +2347031174331.
+2347062422360. -
Ojumo Ire ni
Ile to mo wa loni, ka ma subu ka ma feyin owo danu,toripe ojumo ire ni, ka ma ko elenini ka ma ko agbako toripe ojumo ire ni,ori owo Lori wa loni, ESE aje lese wa lonj aji lowuro ati ba eleda soro wipe koni San wa so rere. Oti ribe koyi pada Ase
-
Olojo ibi Toni
Mo layo lati so fun yin wipe oni ni ojo ibi mama wa MONSURAT KEHINDE ADENEKAN ALANI ti won je okan pataki ninu ebi Omo Oodua Rere.
Maami olojo ibi a ki yin e ku ayo oni, e o se pupo re laye ninu alafia ara ati ibale okan. Ni oruko Oluwa e o ni ba won na oja warawara nile aye beeni e o si ni dagba yeye, gbogbo ohun rere ti n mu’le aye rorun fun eda ni Eledua yoo fi jinki yin. E o gbo, e o to, e o fewu pari, e o ferigi jobi, e o gbele aye sohun rere bi o ti wa wu ki e pe to laye e o ni f’oju mo saare omo lase Edumare.
Kabiyesi ati awon Oloye ati gbogbo ebi Omo Yoruba Atata pata nileloko nki yin wipe IGBA ODUN, ODUN KAN NI O..
-
Eto Olobe Loloko Sokoyokoto Toni
Olorun ogo ni fun oruko re, oba to ni kokoro Iku ati iye lowo, oba ti o le pa, oba ti o le ji, adupe lowo eledua, oba ti o fi aanu re pawa mo.
“FURAIDI IRESI” (fried rice) ni ounje aladun ti a o fi ko ara wa leko loni,,,,
Awon ohun ELO ti a o lo lati se IRESI FURAIDI owun ree…
RICE
ORORO
ALUBOSA
IYO
MAGI
ALUBOSA ELEWE
CARROTTI
EDO ERAN
CURRY
THYME
EWA ALAWO EWE(green peas) IGBADO DIDUN(sweet corn)
Bii a o ti se iresi furaidi wa re oo, e ma bami Kalo :-ONA meji ni a le gba se iresi wa:-ONA KINNI RE O:-
IPELE AKOKO;- A o Koko san, carrotti, alubosa elewe, edo wa ti a ti bo yen ati alubosa, a o wa ge si kekeke. A o san iresi wa daradara,
IPELE IKEJI;- Leyin ti a ti pari ipele akoko,a o gbe iresi wa ka ina, a o se fun igba die(parboiled), a o so kale, a o si daa sinu ase kan.
IPELE IKETA;-Leyin eyi, a o da ororo si ori ina, ti ororo yii ba ti gbona, a o fi alubosa die si, a o carrotti si, alubosa elewe, curry, thyme, omi eran,alubosa elewe, Maggi die ati iyo die si, a o ro papo, ti a ba rii wipe omi eran yen kere, a le fi omi die si.
IPELE IKERIN;- leyin eyi, a o wa da iresi wa si, a o ro papo, a o ni je ki omi poju ninu iresi yen, a o wa de pa, a o sii yewo leyin iseju mewa,, leyin eyi, a o da edo sii.
IPELE IKARUN;- Leyin iseju mewa, ti a ba rii wipe iresi wa ti jina daradara, a o san ewe alawo ewe wa(green peas,) ati igba didun wa(sweet corn) .
IPELE IKEFA;-iresi wa ti dele niyen, a le je pelu, moinmoin, dodo, ati bee bee lo.
,,,,,,,,,, ONA KEJI TI A LE GBA SE IRESI FURAIDI,,,,,,,,,,,,,
IPELE KINNI:-a o San iresi wa daradara, a o da sinu ase kan, ki o le ma rooo IPELE KEJI:-, a o gbe oro ka ina, a o fi curry ati thyme die si, leyin eyi, a o wa da iresi wa sini ororo yen, a o si maa ro papo, ninu ororo yen, titi ti oju iresi yen yio fi yipada die, IPELE KETA:-leyin eyi, a o da carrotti, edo, aluboda elewe sii inu iresi yen, a o roo papo, a o wa omi eran wa si tabi Maggi ati iyo die, ao si de pa ki o le jina, IPELE KERIN :-leyin ti o ba ti jina tan, a o fi ewa alawo ewe ati igbadun sii, iresi wa ti dele niyen.
Too a o ni ri ja bayi lo lori eto olobe loloko sokoyokoto toni,, oruko temi ni OMIDAN FALADE OPEYEMI WURAOLA.
Aye wa fun Amoran, Afikun, Ayokuro tabi ibeere! Nje a ri eni ti o ni ibeere bii?? -
Odo Iwoyi – E Gbo Bi Atejise Na Ti Lo
Mo ki gbogbo wa pata lokunrin ati lobinrin, lomode ati lagba wipe a ku ise oni, a si ku abo sori eto wa eto yin, eto Odo Iwoyi ti ose yi. E wa nkan fidile tabi ki e gbiyanju fidile nkan, ki a jo gbadun ara wa bi ijebu ti ma n gbadun gari.
Gege bi ise wa lori eto yi, atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon Ololufe eto yi ni a o maa ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won lamoran bi o ti ye. E GBO BI ATEJISE NA TI LO;……
“Olootu mo ki yin fun ise takuntakun ti e nse lori eto yi, Eledua yoo san yin lesan ire o, Amin. Mo si ki gbogbo eyin ojogbon ati oloye eniyan ti e n da seto yi, Eledua yoo da soro aye enikookan wa na o Amin.
E jowo olootu oro kan ni o sebi oro laarin emi ati awon obi mi, ti oro na si se mi ni kayefi, iyen ni mo ni ki n fi to awon ojogbon eniyan leti, ki n le mo asise mi, ki awon odo egbe mi pelu si le kogbon nibe. Eni odun metadinlogbon ni mi, odun ti o koja ni mo setan ni ile eko ifasiti, ki n to setan ni ile eko ni maami a ti ma pe mi si ikoko, ti won a si maa so fun mi wipe, pelu ojo ori mi, o ti ye ki awon ti mo eni ti mo n fe gege bi afesona, sugbon nse ni mo ma n fun maami ni suuru wipe ohun gbogbo ni akoko wa fun, wipe kii se wipe nko ni eni ti mo nfe sugbon ti nko ba pari eko mi n ko le mu okunrin wa sile.
Leyin ti mo ti wa setan bayi, ni mo pe maami ti mo si fi to won leti wipe mo fe mu afesona mi wa ki o le mo awon obi mi, inu maami si dun si igbese yi pupo, maami si wa so fun mi wipe ki n fi oro na to baba mi leti, beeni mo se bi won ti wi, inu baami pelu dun nigba ti won gbo oro yi. Beeni a fi ohun gbogbo si ojo abemeta ti o koja lo yi.
Ibi igbafe kan ti o wa ni gbagede inu ogba ile wa, ni a joko si ni ojo ti mo nso yi, ibi igbafe yi ko jina si ibi ti a ma n ko oko ayokele wa si, ibe ni baami feran lati ma joko si nitori ategun. Ki n ma fa oro gun, ko pe ti a nfi oro jomitoro oro, ni afesona mi de, oko ayekole re ni o gbe wa, bi o ti de ni asona ile wa si enu ona fun-un ti o si gbe oko re wole, se ibi ti a kuku n gbe oko si ko jina si ibi ijoko wa, bi arakunrin yi ti jade ti mo si lo pade re ni a di mo ara wa ti a si fi enu ko ara wa lenu, bi a ti de ibi ti maami ati baami joko si, arakunrin yi ki won bi o ti ye.
Leyin iseju die ti arakunrin yi ti wa ni ijoko, ni baami tenu bo oro ti won si beere opolopo ibeere lowo arakunrin yi, maami pelu beere awon ibeere kookan, leyin bi wakati kan le die, ni arakunrin yi toro aye lati maa lo, beeni baami si fun-un laye koda won se adura fun arakunrin yi pelu. Bi o ti dide ni emi na dide, ti mo si tele de idi oko bi o ti fe wo inu oko ni a di mo ara wa ti a si tun fi enu ko ara wa lenu, beeni mo pada si ibi ti awon obi mi joko si pelu erin.
Sugbon iyalenu ni o je wipe, nigba ti n o fi pada de ori ijoko, mo se akiyesi wipe nse ni oju baami kore lowo, ni baami si pe oruko mi lemeeta, ti won si wipe
“Emelo ni mo pe o? Woo o koi ti r’oko o, duro na, se mo jebi ni bi mo se ran o lo ile eko ni? Se ese ni bi mo se na owo le o lori ni? Se ile eko ti mo ran o lo ni o gba iwa omoluabi kuro lara re ni? Se ti iwo o ba tie gbon, se daginidagini ti o pe ni afesona re owun ko ni lakaye ni? Nibo ni e ti ri iru asa buruku yi ni ile Yoruba? Okunrin ti koi ti san owo ori re, wa n ti enu bo o lenu niwaju mi!! Iru asa palapala wo ree? Woo nko gbudo tun ri okunrin yi ni ayika ile mi yi mo ti o ba mo wipe emi ni mo bi o”
Bi baami ti soro tan, ni won fe dide pelu ibinu, beeni maami wipe, “Dadi e dakun e mai ti lo, looto iwa ti won hu ko bojumu to, sugbon sibe, se e mo wipe omode ni won, a o maa to won sona ni, mo ro wipe nse ni o ye ki a pe awon mejeeji, ki a si ba won soro tori won le ma moo si iwa aida”
Ni baami wipe “Pe awon tani, ennn mo mo wipe eyin won ni iwo na yoo waa, woo ibi ti o ba ba aye awon omo wonyi je de, e o jo maa yanju re, temi ni wipe nko fe ri ogbeni yen mo ni ayika mi”
Bi baami ti dide ree, ti won si wonu iyewu won lo, nse ni emi ati maami wa nwoju ara wa, ni mo n bi maami wipe, se nkan miran wa lori oro ile yi ni? Abi ki ni o buru ninu ki emi ati afesona mi fi enu ko ara wa lenu? Oro yi ko tie fe yemi mo, koda nko gbo iru re ri. Leyin isele yi mo gbiyanju lati lo ba baami sugbon nse ni won wipe toba se lori oro afesona mi yen ni, nko gbudo tun soo leti awon mo. Iyen ni mo se ni ki n fi oro na to eyin oloye eniyan, ki e tun ba wa dasi, e dakun ki ni o buru ninu iwa ti a hu yi gan? E jowo se igbese ti baami pelu gbe yi si bojumu to? Mo ro wipe ti ife ba ti wa laarin ololufe meji kekere ni awon eyi ti o ku abi? Emi ati afesona mi yi si ni ife ara wa, se o wa ye ki o je oro a ntenu bo ara wa lenu loju awon obi mi ni baami yoo fi da arin wa ru bayi? Eyin baami ati maami nile, eyin ologbon ati oloye eniyan, oro ree o, e jowo e ba mi dasi o……”
Hmmmm oro ree o, eyin ojogbon eto Odo Iwoyi, gege bi e ti mo wipe ise ati asa Yoruba ni o je wa logun ni abala yi, ki ni asa Yoruba so lori oro yi? Nje iwa ti arabinrin yi ati afesona re hu ba asa Yoruba mu? Nje igbese baba yi pelu ba ise Yoruba mu? Nje mama arabinrin yi soro bi Yoruba bi? Ta ni ki a tie da lebi gan lori oro yi? Se okunrin ti ntenu bo afesona re lenu loju awon obi re ni? Se obinrin ti o koyan awon obi re kere loju afesona re ni? Se baba ti o fe da igbeyawo omo re ru nitori ifenukonu lasan ni? Se iya ti ko faramo igbese baba omo re ni?? Ju gbogbo re lo, ki ni amoran yin fun arabinrin yi gan? Igbese wo ni ki o gbe bayi ki oro ile yi le ni iyanju, se ki o se bi baba re se wi ni abi bo?? Eyin oloye eniyan oro ree ooo.`Abel Simeon Oluwafemi
-
Arun Karun Konifile Awa Se Ibugbe o
Eyin tiaa..akuu gbalegbata oni o…arun karun konifile awa se ibugbe o. Ase..Paronure lawaa..Se e gbagbe pe lati onilo di ola.faaji nson. Leyin Elere ti okan yin yan laayo. Pe kowa kolu siwa nibadi. Emaa gbagbe pe.idalu niselu. Onje tin lo ni repete. Oje won leyin nje ni ilu yin gan. Semo nbe.lafuu nan o gbeyin. Ewo ni tiyin o..tobawa di ni ola sunday kie maa reti Amuludun tie bere fun. Lagbo oje lawa loni.iruu onje wo leyin dibo fun.
-
Idile Alayo: E Gbo Bi Atejise Na Ti Lo
Mo ki gbogbo wa pata lokunrin ati lobinrin, lomode ati lagba wipe a ku ise oni, a si ku abo sori eto wa eto yin, eto Idile Alayo ti ose yi. E wa nkan fidile tabi ki e gbiyanju fidile nkan, ki a jo gbadun ara wa bi ijebu ti ma n gbadun gari.
Gege bi ise wa lori eto yi, atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon Ololufe eto yi ni a o maa ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won lamoran bi o ti ye. E GBO BI ATEJISE NA TI LO;“Olootu mo ki yin pupo o, mo si ki gbogbo awa ololufe eto Idile Aalyo wipe, ibanuje kere o tobi ko ni wo’nu ebi enikookan wa o.
E jowo olootu ati gbogbo eyin ojogbon eto Idile Alayo awon amoran meji kan ni o n se mi kami kami kami ti nko mo eyi ti n o tele ninu re, ni mo ro wipe ki n fi lo eyin baba ati iya mi, paapa julo eyin baba mi nile, tori won ni iriri sagba ogbon. Iyen ni mo se to yin wa loni, ki e ba mi gbe awon oro na yewo ki n le mo eyi ti n o tele gan, se eyin agba ni e kuku wipe “a ma n pejo gbon ni a kii pejo go” ori meji si san ju ori kan lo ni eyin agba wi, toto sebi owe o.Ose meji seyin ni mo se igbeyawo, emi nikan ni omo okunrin ninu omo marun ti baba mi bi, ki baba mi to jade laye won a maa gba mi lamoran lopo igba lori oro loko-laya, lara awon die ninu oro ti baami ma n so nigbana ti nko le gbagbe ree, nse ni won a ma wipe;-
“Kayode mi, pelu ore ofe Olorun, un o fi o saye lo ni, oniwaju mi ko ni keyin laye, beeni eleyin re ko ni siwaju lase Edumare.Woo mo wa n fi Olorun be o, maa se jeje o, ranti omo eni ti o nse nibikibi ti o ba n lo o, ju gbogbo re lo ti o ba to akoko ti iwo na yoo di oniyawo rora se o, nitori akoko ti o lewu julo ninu aye eda ni o, ti okunrin ba si ti oniyawo nile igba aye miran sese bere ni, akainiye adanwo ni yoo ma yoju, se o si ri obinrin ti o nwo yen hmmm awon ree esu re ni o, awon gan ni esu ti awa okunrin n wa kiri o, nitori na mo be o rora o, obinrin o se finu han o, jowo mase je ki ife ru bo o loju ki o wa ko gbogbo ile aye re le obinrin lowo o, bi obinrin bimo fun ni ko ni ki won ma pani o, suru ati ogbon ni a fi n soko obinrin, ti o ba ni ogorun nayira lowo nse ni ki o so fun iyawo re wipe adorin nayira ni o ku o ku laye lorun ni o, tori ko ni ya o lenu wipe ti e ba jo na adorin nayira owun tan, obinrin yoo tun beere owo miran ti o si mo wipe kosi owo lowo re mo, idi niyi ti o gbudo maa da bi ogbon, bi be ko ile yin o le toro o.
Obinrin ni obinrin yoo si maa je o, nko ni ki o ma fi ife han si iyawo ati awon omo re sugbon ti a ba n sore nse ni a ma n fi aye ija sile o, oko o kii n je ti baba ati omo ki o ma ni ala o, mase ba obinrin da owo po o, mo fi Olorun be o, mase ba obinrin da owo po o, tori o lewu o, rii daju wipe o ntoju iyawo re bi o ti wa ni ipa re, Olorun yoo ran o se o”
Awon oro wonyi ati opo miran beebe ni baami fi ma n jimi nire ni akoko yen loun, ni bayi baami o si mo, sugbon awon oro yi a maa so si mi lokan lopo igba, bi a ti wa pari ijosin ni ojo isinmi ti o koja yi ni alagba ijo wa pemi ti won si gba mi lamoran pupo, die lara awon oro won ree…..
“Buroda Kayode mo ki yin e ku aseyege o, Olodumare ko ni fi eyin ati idile yin sile o, se e rii, igbe aye tuntun miran ni e sese bere si gbe yi o, ni akoko ti e wa yi, e nilo lati fi suuru kun suuru yin o, tori ati ba obinrin gbe ko rorun, koda awa ti a je iranse Olorun gan, a ma la opolopo nkan koja pelu iyawo wa, tobe jube lo suuru ni gbogbo re gba, ki e wa gbadura fun emi isokan, nitori bibeli wipe “Nigbana ni obinrin yoo si fi iya ati baba re sile, okunrin yoo si fi baba ati iya re sile, awon mejeeji yoo si di okan”.Isokan ni ohun elo ti n mu idile se aseyori, ohun gbogbo ti e ba n se, e gbudo je ki iyawo yin mo sii, e ko gbudo se ohun kan laisi ilowosi iyawo yin nibe, e je ki iyawo yin mo gbogbo bi e ti to laye ati lorun, e je ki o mo pato iye owo osu yin, koda ti o ba seese ki e maa lo apo ifowopamo kan na, eyi ni yoo mu ife ati isokan ebi yin rinle si, ju gbogbo re lo e mase rewesi ninu adura ti iyawo yin ba se yin e fi ejo re sun fun awn iranse Olorun dipo ti e o ma rojo ebi yin fun awon alaigbagbo, Olorun yoo wa pelu yin o, laipe a o ba yin yo ayo omo ni oruko Jesu Amin.”
Hmmmm bi mo ti dele ni ojo yi ni mo wa n ro awon oro yi si ara won, pasito wipe ti a ba fe se aseyori a nilo ISOKAN ki a maa se ohun gbogbo papo, a gbudo finu tan ara wa, beeni baami wipe obinrin o se finu han, won ni n o gbudo je ki obinrin mo gbogbo asiri mi, awon oro meji wonyi wa n se mi ni kayefi, Se oro pasito ni ki n tele bayi ni abi ti baami, iyen ni mo se ni ki n fi lo eyin ojogbon, paapa julo eyin baami nile ti e ti ngbe pelu obinrin fun odun bi melo kan, ki e jowo la mi loye lori awon oro wonyi, e jowo se gbogbo obinrin ni ko se finu han ni? Se looto ni ko bojumu ki obinrin mo asiri oko re ni? Se looto ni wipe laisi Isokan ebi ko le toro ni? E jowo e la mi loye o”
Hmmmm Oro ree o, Eyin Oloye eniyan, ewo ni ki ogbeni Kayode tele bayi, se oro iranse Olorun ni abi ti oloogbe baba won? Se looto ni wipe obinrin o se finu han ni? Nje ese wa ninu ki iyawo mo bi oko re ti to laye lorun? Nje iyawo tiyin tile month iye owo osu ti e ngba? Se lara ife ni ki oko ati aya maa lo apo ifowopamo kan na bi alagba yi ti so? Ju gbogbo re lo, ti gbonmisi omi o to ba waye laarin lokolaya, se alagba ijo ni o to lati fi ejo sun ni abi ebi enÎ?? -
Eeto Owe L’esin Oro
YAKUB BUKKY –
Nje a tun ti de loni gegebi ise wa ni gbogbo ojoru. Oro enikokan wa koni dojuru oo (amin), a ki gbogbo kaabo si akootun eeto yin, eeto wa owe l’esin oro, oro l’esin owe, ti oro ba sonu, owe la fi n wa. N o ni salai se iba fun Olorun ti o funwa ni oore ofe nla lati tun fi pade ni ose yii, moki kabiyesi olumoye ti ilumoye akoko, moki yeyeoba, gbogbo ogbimo aafin, awon oloye, mio gbagbe awon oloori laafin naa ati gbogbo omoba l’okunrin ati l’obinrin wipe a tun kaabo si ori eeto loni.
Gegebi isee wa, lori eeto yii ni a o ti maa yannana awon owe ile wa lolokanojokan ati lilo won ninu oro, e wa nkan fidile, ki e maa bawa kalo.Owe akoko ti a o maa gbe yewo lo bayii: IMADO IBA SEBI ELEDE A BA ILU JE, ERU I BA J’OBA, EYAN I BA TI KU IKAN.
ITUMO/ LILO; imado je elede igbo, ti o le ju aja lo, o buru ju elede ile lo, koni suuru bi elede ile. Meji meji ni Olorun n da nnkan, o fi eyi ti o dara sinu ile, o fi eyi ti o lewu sinu igbo. Fun apeere: aja- aja’ko, obo-inaki, ekolo-ejo, elede-imado.
Gegebi mo se so siwaju, iwa ipata, ipanle po lowo imado, ti o ba wa ni anfaani lati de ipo ola, yio s’aye je, boya ki a so wipe, a fe muwa sinu ile gegebi elede, yio ba nkan ti o dara jee. Bi elede yio ba jeun, enu ni o fi n tu ilee, je igbe ni akitan, ti a ba wo imado-elede igbo, ni bi o ba wa ni aarin eyan, eyin ni o fii n ja. Beenani, ti a ba fi eru j’oba, yio si ipo naa lo, nitoriwipe, gbogbo iya to tije nigba tio wa nipo eru, ni yio fe fi je awon eeyan pada.
A maa nlo owe yii, ti a ba ri onijagidijagan tabi onijiibiti eda, ti o n wa gbero tabi ti o n sapa lati maa dari awon eniyan, tabi lati maa se akooso nkankan.Owe keji ti a o maa gbeyewo fun toni lo bayii: OROMADIE O MON AWODI, IYA E LO MON AASA.
Itumo/lilo; oromadie je omo adire keekeeke, ti iya won sese paa, won o gbon lati le mon ise ibi ti awodi,/aasa, eye buruku to n gbe loju orun le se, sugbon iya re mo itu ti aasa le pa, awodi ko nise meji ju ko gbe adire lo. Ti aasa ba ti yo lookan ni adire a ti maa raaga bo omo re. Awofin yii lawon eyan ri bi aasa yio se maa ja sooro bo, ti oromadie yio maa sere ni tire,. Pelu agbara, ti iya oromadie yio si maa rababa nile lati daabo nla bo awon omo re oromadie.A maa nlo owe yii, ti a ba sakiyesi wipe eni ti ko nimo nipa nkankan n rin ni bebe nkan ti o le se akoba nla tabi eewu nla fun. Tabi ti maajesin kan koba mon iru eda ati iru itu ti a le pa fun oun, ti o n fi oju tembelu wa, a le pa owe yii na fun bakanna. Toooo, nibi ni a o ti sewele fun ti ooni, eyin ojogbon inu aba yii, gegebi e se mon wipe a n korawa l’eko laafin ilumoye nii, a n reti afikun, akiyesi tabi ayokuro ki o le ba je anfaani fun gbogbo wa, nitori ‘ogbon ologbon ni kii je ki a pe agba ni were’. E funwa ni awon owe ti o farape awon owe ti a ju si afefe loni, ki a tun ko imo kun imo.
E seun