Aimoye dukia lo ti sofo bayii latari iji nla pelu agbara ojo ti n wo odindi moto sare ni ilu England bayii. Isele buruku yii lo waye latari ojo alagbara kan to si lule to si bere si ni se ijamba lorisiirisii. Gege bi alaye to te Olayemi Oniroyin lowo, apa ariwa ilu UK ni ijamba naa ti wopo julo nibi ti won ti ro gbogbo olugbe agbegbe naa lati sa asala fun emi won bayii.






































Category: Àṣà Oòduà
Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.
-
Omiyale-agbara ya soobu ti se ijamba niluu Oba Biritiko
-
E wo ohun ti enikan so nipa ile epo Bovas to wa niluu Ibadan
Awon arije ni madaru, ika, odaju, ole, wobia, wonbiliki le po ni Naijiria loooto, sugbon awon eniyan rere ko ti tan lawujo wa. Okan ninu won ni alase ile epo Bovas to kale silu Ibadan. Bakan naa ni awon eniyan jeri si wi pe, won ko fi owo kun owo epo won ni awon eka ile ise won to wa kaakiri ile Naijiria.
-
Ijamba oko niluu Eko lojo odun keresimesi
Ti e ba muti, e ma wako; ti e ba wako, e ma muti. Okunrin kan lo koja lo sorun lojo odun keresimesi to koja yii ni akoko ti gbogbo eniyan n yo ayo iwasaye Jesu olugbala araye. Ijamba oko yii lo waye ni oju ona Mobolaji Bank Anthony to wa ni Ikeja ni ipinle Eko.
Gege bi awon eso oju-ona FRSC se so, won ni ere asapajude ni okunrin naa n saa bo lai se wi pe enikeni n le ko to di wi pe oko re takiti laimoye igba. Oju-ese naa ni emi jade lara okunrin naa, eni ti enikeni ko ti mo ohunkohun nipa re titi di akoko ti a n fi ko iroyin yii.
Sugbon iwadii inu awon eso oju-ona fi ye wa wi pe, ogidi oti amupara ni okunrin naa mu yo saaju ko to se agbako iku ojiji naa. Won ti gbe oku okunrin naa lo si ile igboku si nigba ti won si n se iwadii nipa awon ebi re.




-
Owo ti te Jaguda, Mohammed Isah to lu komisanna olopaa meji ni jibiti
Sebi ojo gbogbo ni tole, ojo kan pere ni tolohun. Owo awon olopaa ilu Eko ti te omo gambari onijibiti kan ti oruko re n je Mohammed Isah, to lu komisanna ipinle Ondo ati Anambra ni jibiti.
Omokunrin onijibiti naa ti iwadii fi han wi pe omo ipinle Katsina nii se, logba ile ise olopaa ipinle Eko lo to wa ni Ikeja lati lo fi ejo awon olopaa Rapid Response Squad sun wi pe won fi ipa gba owo to din die ni egberun lona igba naira lowo oun.
Okan ninu awon olopaa to ba nikale, ACP Edward Ajogun, eni to ti fi igba kan wa ni Ondo Police Command ko to di wi pe won gbe wa si ipinle Eko ninu osu kesan-an odun yii fura wi pe, oun ti salabapade odaran naa ri pelu esun kan naa to gbe wa.

Leyinoreyin ni asiri Isah tu wi pe, oun kan naa lo puro mo awon olopaa kan ni ipinle Ondo wi pe won gba owo tabua lowo oun eleyii ti komisanna pada da die pada fun lara owo naa ti won si le awon olopaa ti isele naa sesilowo kuro lenu ise.
Leyin ti won so Isah sinu atimole, awon olopaa si tun tesiwaju lati ma se iwadii nipa re. Iwadii won tun fi ye won wi pe, o ti wu iru wa kan naa ni ipinle Anambra. Won ni nipinle Anambra, oun to se ni wi pe, o mu nomba oko awon olopaa kan lo si olu ile ise olopaa. O si wi fun won wi pe, awon olopaa ti won wa ninu oko to ni nomba naa gba owo to din die ni egberun lona oodurun naira lowo oun.
Eleyii ti komisanna si ko egberun lona aadojo (N150k) fun gege bi owo gba-ma-binu.
“Omokunrin yii kan naa lo wa fi ejo sun ni ileese olopaa ipinle Ondo wi pe awon olopaa ti n yide kiri gba egberun lona ogoje owo naira (N140k) lowo oun. Oruko to ni oun je nigba naa ni Musa Mulamba. Awon olopaa bi mefa to paro mo si ni komisanna da duro lenu ise leyin ti won san die pada fun ninu owo to ni won gba lowo oun naa,” Ajogun se lalaye bee.
-
Ikini odun lati owo Olayemi Olatilewa Oniroyin Agbaye
Olayemi, odun to n bo yii, odun emi ati iwo ni. Eyin e fota sile ki won ma gbogun. E fika eniyan sile ki won ma soogun. Mo tile tun gbo wi pe awon kan tun lo n bogun onire. Sugbon igbagbo mi mbe ni Akogun ode orun.
Jagunjagun ti kii roju ogun ko to segun. Oba mi erujeje ti n lo niwaju to tun un bo leyin.
Iba ni i ma se lojo gbogbo.
Mo wa dupe lowo awon eniyan ti won ka iroyin wa losan-an loru, awon onibara wa ati awon eniyan ti won fe wa kari aye.
Olayemi Olatilewa Oniroyin dupe. Odun ayo ni gbogbo yoo se.
Alekun owo, omo, ayo, alaafia ati igbega. Ase
E ku odun!
-
“Oju Mimiko ni PDP yoo fi poora nipinle Ondo” – Oloye egbe APC
Okan pataki ninu awon oloye egbe APC nipinle Ondo, Niran Sule-Akinsuyi, ti so yanya wi pe niseju Gomina Olusegun Mimiko ni egbe oselu PDP ipinle naa yoo fi di ohun a-fi-seyin teegun fiso.Oro yii lo n so nigba to fi n da awon eniyan loju nipa aseyori ti yoo deba egbe APC ninu eto idibo gomina ipinle naa ti yoo waye lodun ti n bo.“Ki i se ero awon oloselu tabi egbe oselu APC nikan ni lati ni iyipada rere, awon ara ilu gan-an fe iyipada ti yoo so igbe aye won di otun. Eleyii si foju han ninu eto idibo aare to waye nibi ti egbe APC ti feyin PDP janle loju gbogbo aye,” Ogbeni Sule-Akinsuyi fi kun oro re bee.Yato si eleyii, ojo Monde to koja yii ni awon omo egbe PDP meji kan tun kowe fi ipo won sile gege bi omo egbe, ti won si ko gbogbo awon ololufe won pata wonu egbe APC.Awon oloselu meji naa ni ogbeni Ayo Patrick Akinyelure, eni to ti soju ekun aarin gbungbun Ondo gege bi senato nigba kan ri. Eni keji ni Pius Olakunle Osunyikanmi to je oludari Technical Aid Corps (TAC).Awon oloselu nla mejeeji ti won jijo fi ipo won sile gege bi omo egbe PDP ni won salaye itesiwaju won sinu egbe APC gege bi iyipada otun fun Ipinle Ondo lapapo.“Ka to to gbe igbese ti agbe yii, awon eniyan ti a n soju fun pata ni awon agbegbe wa ni won fowo si aba naa. Awon agbalagba egbe naa ko gbeyin, gbogbo won ni won fowo si igbese wa eleyii ti a lero wi pe yoo so eso rere,” Akinyelure fi kun oro re bee. -
Faleke n mura ija nipinle Kogi *Omo oloogbe Abubakar Audu n be leyin re.
*Omo oloogbe Abubakar Audu n be leyin re.
*Kilode ti Tinubu ko da soro naa?Lati Ọwọ Olayemi Olatilewa
Lojo Aje to koja yii ni rugudu ti n lo lagbo oselu nipinle Kogi tun bureke si i nigba ti Ogbeni James Abiodun Faleke mu iwe ipejo re lo siwaju ile ejo ti n gbo awuyewuye to suyo leyin idibo ti a mo si tiribuna nipinle naa.
Aimoye awon eniyan ti won je alatileyin, ore ati ololufe Faleke ni won tele lo si ile ejo naa lati fi iwe ipejo naa sile fun akowe kootu.
Lara awon eniyan ti won tele Faleke ni Mohammed Audu to je omo oloogbe Abubakar Audu ati agbejoro Faleke to siwaju gege bi Balogun.
Esun pataki ti Faleke te siwaju ile ejo naa ni wi pe, ona aito lo je gege bi ajo INEC se kede eto idibo ojo kokanlelogun osu kokanla odun yii (21/11/15) gege bi eto idibo to ku sibi kan leyin ti egbe to bori ti foju han gbangba.
Bakan naa, Faleke fi kun oro re wi pe, oun lo ye fun ajo INEC lati kede gege bi gomina tiluu dibo yan ki i se Yahaya Bello.
Nibayii, awon agba egbe APC lati ekun Iwo-oorun ipinle Kogi ti n mura lati se ipade po pelu Faleke nibi ti won yoo ti ma petu si i ninu lati faramo ipinnu egbe lori oro to wa nile naa.
“Gbogbo ohun to ba ye ka se pata ni a gbodo muse lati ri wi pe oro to wa nile yii ko baje koja atunse. A fi n da awon ololufe egbe wa loju wi pe a o bu omi tutu si oro naa. To fi je wi pe Faleke yoo lo fa iwe ipejo naa ya, titi gbogbo re yoo si yanju patapata. Ipinnu egbe se pataki, sebi ti omode ba n gegi nigbo, agba ni i mobi ti o wosi. Agba ki i si wa loja, ki ori omo tuntun o wo,” Oloye Richard Asaje lo se lalaye bee.
Wayio, amofin to tun je ajafeto omoniyan, Ogbeni Emmanuel Owotunse ni awon igbese ti Faleke n gbe dabi igba ti eniyan ba n towo bo inu eeru gbigbona, kosi igba ti ko ni fika jona.
“Bi Faleke se gba ile ejo lo dabi igba to n te egbe loju mole, eleyii ti abamo le kangun oro re ti ko ba se suuru. Egbe mo ohun ti won se, ti Faleke ko ba si fi owo re sibi to ye, afaimo ko ma towo bo eeru gbigbona ti yoo jo nika. Eniyan ti ko kopa ninu eto idibo abele egbe ko le di gomina. Eewo ni. Faleke ko kopa ninu eto idibo abele egbe APC, ti won ba fa kale, owo kan ni egbe PDP yoo gba danu ni kootu leyin to ba di gomina,” Ogbeni Owotunse se lalaye bee.
Ninu oro Owotunse eleyii to se ni Lokoja to je olu ilu Kogi lo tun fi kun wi pe, oun ti n ki Faleke laye ko ju nipa ajosepo re pelu Bola Tinubu lo.
“Awon agbejoro ti won gba Faleke lamoran ni won yoo pada se akoba fun un. Igbakeji gomina nipo Faleke lati ibere pepe, kilode ti ojukokoro ipo gomina wa n feju mo o losan gangan? Bo tile ni ajosepo to danmoran pelu Tinubu, o gbodo gba kadara ko ma ba gba kodoro,” Owotunse fi kun oro re bee.
Bakan naa, Mohammed Audu to je omo oloogbe Abubakar Audu kede atileyin re fun Falake gege bi ife okan awon agba idile baba re. Eleyii ti aba naa jade leyin ipade molebi to waye ninu idile oloogbe naa.
” Mi o ro wi pe awon agba idile wa nikan ni won fe lati ri Faleke gege bi eni to ye nipo gomina, inu baba mi ti n be lorun gan-an ko le dun pelu bi awon kan se gbimopo lati yan igbakeji re je. E je ka maa se ohun gbogbo pelu iberu Olorun oba Allah. O ni lasan la ri, kosi eni to mo ile ti o mola,” Mohammed fi kun oro re bee.Pelu bi nnkan se n lo yii, awon onwoye nipa oro oselu gba wi pe ina Faleke ti n jo lori omi, onilu re mbe nisale odo ni. Won ni okan ninu awon omo ti Tinubu to dagba ninu oselu ni Faleke je, to fi je wi pe kosi ohun ti Tinubu ni ko se ti ko ni se. Bi nnkan se wa ri yii, ti a ko gbo ohunkohun ni gbangba nipa Tinubu lori oro naa, o ni lati je wi pe nikoro ni Tinubu ti n ba Faleke soro. Eleyii ti oro naa si je awon oro iwuri ti n mu Faleke maa saya gbangban to si ko lati gba si egbe lenu.
Pada sori oro ti amofin Owotunse so, se kadara ni o pada keyin oro Faleke ni abi kodoro?





