Category: Àṣà Oòduà

Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.

  • Awon tisa ipinle Kwara taku sori idasesile ti n lo lowo

    http://www.olayemioniroyin.com/
    Idasesile awon oluko alakobere to ti bere lati ojo Aje to koja yii nipinle Kwara ni awon egbe oluko ti temu mo o wi pe yoo si ma tesiwaju ayafi ti ijoba ba san gbese owo osu meta ti won je seyin. Ninu oro agbenuso fun Gomina Abdulfatah Ahmed ti ipinle Kwara, Ogbeni Femi Akorede, so wi pe awon ijoba ibile gan-an ni won ru ebi oro naa sori sugbon ipalara idasesile naa ti wa bo sori ipinle Kwara lapapo bayii.

    “Ijoba ibile lo je owo ti awon oluko alakobere n beere fun yii. Ijoba ipinle si ti setan lati dide iranlowo sugbon owo ti ijoba apapo n san fun wa lo ha si banki. Eyi lo sokunfa bi oda owo se n da ijoba ipinle lati se awon ohun to ye. A be awon tisa wa wi pe ki won pada senu ise,” Ogbeni Akorede se alaye naa bee.

    Okan ninu awon tisa to gba lati ba Olayemi Oniroyin soro lai daruko ara re salaye wi pe, “Mo fi dayin loju wi pe inu ebi la ti n sun la ti n ji ni joojumo aye. Aimoye gbese lati je latari ki ebi ma pawa sile lasan. Owo osu awon oloselu wa ko duro, awon je igbaladun ni joojumo nigba ti awa n jeya lenu bi isu egbodo.”

    Alaga egbe awon ijoba ibile, Association of Local Government Councils of Nigeria (ALGON), eka ti ipinle Kwara, Alhaji Lateef Okandeji, naa ti rawo ebe si awon tisa lati pada si enu ise won. Ninu oro re, o ni ti eniyan o ba tori epo jesu, o ye ko le tori isu jepo.
    “Gbogbo agbara ni ijoba n sa lati ri wi pe gbese osu meta naa di sisan. Gbogbo bi nnkan si se n lo ni awon oloye egbe oluko (NUT) naa mo. Kosi bojuboju ninu awon nnkan to n sele yii. Ko ba si dara ti a ba le jo fi owowewo fun itesiwaju ipinle Kwara,” Alhaji Okandeji se e lalaye bee.

    Ninu oro akowe egbe awon oluko, Ola Idris, o ni ohun to daju ni wi pe aja ti ko yo ko le ba eyi to ti yo sere laelae.
    “Awon ileri ti ko ni ododo ninu ti awon ijoba n fu wa ti su wa. Awon omo egbe wa ko si le maa fi ebi ko awon omo ni kilaasi. Ko posibu, Ogbeni Ola se lalaye bee.

  • Ohun to pada sele si maanu to lo gbadun ara re nile asewo buru jai

    Maanu yii lo lo gbadun ara re nile asewo kan niluu Benin. Aisanwo leyin igbadun lo di ohun ti won da igbati jo fun un.

  • Senato ipinle Ekiti pin iresi fun awon eniyan bi Fayos

    Awon eniyan ti won gbe ni agbegbe ekun Guusu Ekiti gbajo tilu tifon nigba ti arabirin Biodun Olujimi ti n soju won nile igbimo asofin agba Abuja si obitibiti ounje wolu l’Ojobo ose to koja yii.

    Apo iresi, ororo ati aimoye awon nnkan ti enu n je ni Senato Olujimi ko wa lati da awon eniyan lola gege bi ebun odun. Lara awon ebun ti Senato Olujimi ko wa ni awon oko tokunbo bi tuntun mefa eleyii ti okookan re yoo ma lo si ijoba ibile mefa to gbe ekun naa duro.

    Gege bi oro Senato Olujimi, o ni awon kii se oloselu to je wi pe, akoko idibo lasan ni won yoju si awon eniyan won nigberiko. Bakan naa lo tun so siwaju ninu abewo re wi pe, ki awon eniyan lo mokan bale, gbogbo ileri ti awon se pata ni awon yoo mu wa si imuse.

    Sugbon sa, gege bi ero Ogbeni Ayo Oluwaseesin to je omobibi ipinle Ekiti sugbon to fi ilu Eko se ibujoko salaye wi pe, ko ba dara ti awon oloselu wa ba le ronu idasile ileese alabode ti awon eniyan ti le sise. Eleyii ti yoo mu won kuro ninu iponju yato si ounje pinpin nigbogbo igba. O ni owo ti awon oloselu bi senato n gba lati se itoju ekun ti won soju koja owo ti won fi n ra iresi ti won pin. O si tun fi kun-un wi pe, yoo dara ti ero yii ba le ye awon eniyan ki won si jigiri lati beere ojulowo eto won lowo awon oloselu.

  • “Ayojuran ni Mimiko lo se niluu Bayelsa”- Egbe APC

    Awon omo egbe oselu APC eka ti ipinle Ondo ti bu enu-ate lu Gomina Olusegun Mimiko ti awon kan tun pe ni Iroko gege bi asaaju ti ko mo eyi to kan lati muse. Atejade yii lo jade nigba ti won gburo gomina naa nipinle Bayelsa nibi to ti n lewaju ipolongo ibo fun gomina Henry Seriake Dickson tipinle naa to je omo egbe PDP.

    Gege bi adari ipolongo ati iroyin fun egbe APC ti ipinle Ondo, Ogbeni Steve Otaloro, so wi pe, ijoloju lo je wi pe gomina le raaye ma ru eru eleru lori nigba to n wo eru ti e nile geerege.

    “Pelu gbogbo laasigbo ti ipinle Ondo wa, to je wi pe ilaji ipinle naa lo wa ninu okunkun birimubirimu, ti eto oro aje si ti di akurete patapata, o je kayeefi wi pe gomina tun le roju-raaye gbe eru eleru lori nigba ti tie si n wole geerege bi igba ti omin wo yanrin. Awon igba ati akoko ti gomina n lo loke okun lati gbajumo awon oro ara re nikan ati idile re ju eyi to n lo lati mu igba derun fun awon ara ilu ti won gbe depo agbara lo.”

    Ogbeni Otaloro tun salaye siwaju, ” Bi mo se n ba yin soro yii, iye ti awon ileepo n ta epo pentiro ju iye owo ti ijoba apapo ni ki won maa ta a lo ni ipinle Ondo. Gbogbo eleyii si ni asiri re ti tu si wa lowo. Mimiko lo se ipade pelu awon alagbata epo lati se eleyii ni ona  a ti tabuku ijoba apapo nipinle Ondo,” Ogbeni Otaloro fi kun oro re bee.
    http://www.olayemioniroyin.com/

  • Laasigbo to be laaarin Olubadan ati Gomina Ajimobi

    Awon agba ti yanju laasigbo to be sile laaarin Olubadan ati Gomina Ajimobi

    *Wahala naa sele leyin ti Olubadan fi Ladoja je Osi Olubadan

    Gomina Abiola Ajimobi
    Ikunsinu lo bere laaarin Olubadan tile Ibadan, Oba Samuel Odulana Odugade ati gomina ipinle Oyo, Abiola Ajimobi nikete ti Olubadan mu igbega ba awon omo oye eleyii ti Senato Rasidi Adewolu Ladoja je okan lara won. Ninu atejade tuntun ti eka ile ise ijoba to n risi ijoba ibile ati oye jije fi sita ni won ti pase fun awon omo oye lati se afihan iwe eri ilera won saaju ki won to gba igbega ninu ilana oye jije naa. Sugbon eyikeyi ninu awon omo ye naa ko se eleyii, oro naa si dun Ajimobi bi Olubadan se tesiwaju ninu iwuye tuntun to waye naa.

    Igbega yii lo waye ni akoko poposinsin odun tuntun to wole yii nigba ti won fi Ladoja je Osi Olubadan. Ladoja to ti n je oye Asipa Olubadan tele ni won ja ewe akoko le lori laafin Olubadan nigba ti wo fi n je Osi Olubadan.

    Igbega awon oloye, eleyii to n mu won sun mo ipo oba jije lo waye leyin iku awon oloye nla meji kan, Sulaimon Adegboyega Alao Omiyale JP to je Balogun ati Omowale Kuye to je Otun Olubadan. Awon agba oloye meji yii ni won terigbaso laaarin ose meta si ara won ninu osu kokanla odun to koja yii.

    Iku won lo si mu ki awon aye kan sofo loke eleyii to si gba ki awon omo oye to kangun si ipo naa je awon oye to ba ye. Eleyii gan-an lo sokunfa igbega awon omo oye to waye naa.

    Ninu iwuye tuntun to waye ni won ti fi Oloye Saliu A.O. Adetunji to je Otun Balogun tele je Balogun ile Ibadan; Oloye Lekan Balogun ti gbogbo ilu mo si Osi Olubadan tele gba igbega bo si ipo Otun Olubadan; Oloye Akinloye Owolabi Olakulehin to ti je Osi Balogun tele ni wo fi je Otun Balogun bayii.

    Lara awon oloye to tun gun akaba oye soke ni Oloye Olasogade Olufemi Olaifa, eni to ti n je oye Asipa Balogun tele. Sugbon bayii, o ti bo si ipo oye Osi Balogun ninu igbega awon omo oye to waye naa.

    Awon yoku ni Sir Eddy Oduoye Oyewole to je Ekerin Olubadan tele lo ti di Asipa Olubadan bayii. Oloye Tajudeen Abimbola ti wo fi je Ekerin Balogun tele ni won ti fi je Asipa Balogun bayii. Nigba ti Biodun Kola Daisi to je Ekarun-un Olubadan tele tesiwaju nigba ti won jawe Ekerin Olubadan le e lori.

    Ninu awon omo oye ti wo duro niwaju Olubadan naa ni Solomom A. Adabale to je Ekarun-un Balogun tele lo ti di Ekerin Balogun leyin ayeye iwuye alarinrin naa.

    Ayeye ifinijoye to waye naa lo bi awuyeye to saaju ki eto ifinijoye naa to waye nigba ti ijoba Ipinle Oyo labe oludari eka ile ise ijoba ti n risi awon ijoba ibile ati oye jije, Ogbeni Z. O Jayeola fi sita wi pe ki awon omo oye maa fi iwe eri ilera won sile saaju ki won to jaye oye tuntun le won lori. Ikede tuntun yii ni awon omo oye tako, won ni igbese yii ko si lara ilana ifinijoye ilu Ibadan rara.

    “Ti e ba mo itan Ibadan daada, e ri wi pe iru aba yii sajoji. Emi tile ka iru oro bee si aheso lasan nitori wi pe leta kankan ko de odo mi wi pe mo gbodo fi iwe eri ilera mi han ki n to joye,” Oloye Olufemi Olaifa se alaye naa bee.

    Ninu oro Ladoja naa, eleyii to se fun awon oniroyin leyin ayeye naa ninu ile re to wa ni Bodija, o ni oun naa gba wi pe gboyisoyi lasan ni oro naa, ko gbodo je otito.

    Sugbon ninu atejade eni ti n se kokari fun Accord Youth Volunteer Network, Asiwaju Adekola Adeoye, so wi pe, edun okan nla ni wi pe gomina Ajimobi le raye lati ma tojubo oro awon omo oye pelu hilahilo ti ijoba re ti da sile ni ipinle Oyo.
    “Aimoye awon osise ijoba ati agbasese ni Ajimobi je lowo ti ko ti i san. Kaka ki gomina kojumo awon nnkan wonyii to se koko, isese atodunmodun ni gomina n gbiyanju lati yipada nipase eta inu. To ba je wi pe Ladoja to goke gege bi omo oye lo n ta a lara, ko ba dara ki gomina fi ye gbogbo aye,” Adekola se lalaye bee.

    Ifinijoye to waye yii lai tele ase ijoba ipinle Oyo lo da ikunsinu sile laaarin Olubadan ati Ajimobi eleyii to pada sokunfa bi gomina se pase lojo Monde to koja yii wi pe ki won da awon oloye naa pada seyin ninu igbega oye won to waye. Ase yii ni gomina pa nigba to n fun won ni wakati mejidinlaadota (48hr) lati se bee. Rugudu to waye yii lo mu awon agba-ma-je-o-baje ti ile Ibadan ti a mo si Ibadan Elders Forum dide lati pana wahala naa ni kiakia. Sebi won ni agba kii wa loja, ki ori omo tuntun o wo.

    Ipade lati petu si aawo naa lo waye nile alaga egbe naa, Ambassador Olusola Saanu. Lara awon to peju-pese sibi ipade naa ni Dr. Lekan Are, Oloye Adebayo Akande, Oloye Eddy Oyewole, Ojogbon Femi Lana to je omo Olubadan, Lekan Balogun to je Otun Olubadan ati Gomina Abiola Ajimobi .

    Leyin ipade to waye yii ni gomina kede wi pe aawo naa ti pari ati wi pe awon agba ti yanju oro naa patapata. Bakan naa lo tun fi kun un wi pe, awon oloye ti won gbega naa le maa je oye won lo.

    “E je ka dupe lowo Olorun wi pe o fi awon agba onilaakaye jininki wa nile Ibadan. Oba wa naa si ti fi apere rere lele gege bi asiwaju rere. Olubadan wa lara awon to ran mi lowo lati de ipo gomina ti mo wa yii. Ninu isele yii, omo iya meji lo n ja, awon agba si ti dasi. Wahala naa si ti tan sibe patapata. Awon iwe eri oye to ye kan ti fi le won lowo naa ni ijoba yoo pada seto re pata fun awon omo oye ti won gbega,” Ajimobi se alaye bayii fun awon oniroyin nikete to jade nibi ipade naa.

    http://www.olayemioniroyin.com/

  • “Awon irinse ti a n lo ti darugbo”- Oga panapana ilu Eko

    Oga agba ileese panapana ti ijoba apapo, Federal Fire Service, eka ti ipinle Eko, Ogbeni Aderemi Olusola Theophilus ti sapejuwe ikiyesara gege bi ogun-ajisa lati dena ijamba ina abaadi. Ninu oro re, eleyii to so lori telifisan ipinle Eko, o ni ona to ya ju lati yago fun ijamba ina ni ki awon eniyan sora fun awon eroja to le tete gbanaje.

    Ogbeni Aderemi tun so siwaju wi pe, ona lati dena ijamba ina ko yo awon obirin ile sile nipa akiyesi to peye nigba ti won ba n dana ninu ile. Bakan naa lo tun fi kun un wi pe, ki awon eniyan maa ri daju wi pe gbogbo ohun elo ile ti n lo monamona ni won pa nigba ti won ba fe jade. Ko sai gba awon awako oju popona lamoran lati yago fun iwa gbigbe epo sinu keegi ninu oko. O ni awon nnkan wonyii le sokunfa ijamba ina ojiji.

    Bakan naa, Ogbeni Aderemi ko sai menu ba ipo ti awon irinse ile ise panapana ijoba apapo tilu Eko wa.

    “Ohun to daju ni wi pe, ise wa ko le rorun lai ni awon irinse igbalode to je ojulowo. Pupo ninu awon irinse wa ti a n lo ni won ti dogbo; gbogbo igba ni won baje nitori igba ti lo lori won. Ko ba dara ti ijoba apapo ba le se iranwo nipase rira awon irinse ati oko tuntun eleyii ti yoo ran wa lowo lati daabo bo dukia ati emi awon ara ilu lapapo,” Ogbeni Aderemi fi kun oro re bee.

  • Aye awon asewo nile awon omo yahoo-yahoo

    Bi yahoo-yahoo ni won ni abi ogun oloro ni won gbe, ta lo mo. Sugbon o daju wi pe, eni to n sise gege bi omoluabi ko ni da iru eleyii lasa wo laelae. Ori ayelujara ni aworan yii ti bere si ni fonkiri, eleyii to n se afihan awon asewo ti won jo mojumo, ti won si moti yo keri nile onibara won. E wo bi awon omo ti baba ati iya bi se pate ara awon sile nihoho.

    E gbe ayewo foto na nibi

  • Obirin kan bi omo sinu Keke Maruwa

    Onise ara ni Olorun oba. Omobirin alaboyun kan lo bere si ni robi ninu Keke Maruwa ni akoko ti won gbe lo si ile iwosan lati lo bimo niluu Enugun.  Eyi to ju ibe ni wi pe, ojo odun lo tun wa bosi(1/1/16))nirole patapata. Awon osise ile iwosan alabode ti won fe gbe lo gan-an ti lo sile odun. Sugbon lona ara ati iyanu, obirin adelebo kan ti n koja lo sun mo alaboyun naa nigba ti oko re n keboosi “E gba mi o. Taani yoo ran mi lowo” bonu.

    Omobirin adelebo naa tu eru omo ti alaboyun naa gbe dani, o mu awon nnkan eroja jade, o si gbebi omo naa ninu Keke Maruwa ti won fi n gbe lo si osibitu. Olorun fun obirin adelebo naa se to bee gee to je wi pe irorun ni gbogbo re jasi.  Omo wa laye, iya wa laye gbogbo won pata ni won sodun idunnu nidile won.
    Keke Maruwa

  • Won ti fi Ladoja je Osi Olubadan

    Won ti fi Senator Rashidi Adewolu Ladoja je Osi Olubadan lonii (01/01/16) ni aafin Oba Samuel Odulana Odugade, Olubadan tile Ibadan.