Category: Àṣà Oòduà

Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.

  • Amosun se ileri ipe ofe ori foonu fun awon osise lodun 2016

    Ijoba ipinle Ogun, labe akoso Senator Ibikunle Amosun, ti se ileri ipe ori foonu ofe fun gbogbo awon osise ipinle naa lodun tuntun 2016 to wole de yii.  Igbese tuntun yii ni olori eka imo ero ati ibanisoro, Ogbeni Olatundun Adekunte fi da awon oniroyin loju lojo Isegun to koja yii.

    Gege bi alaye re, ile ise ijoba to wa ni Oke-Mosan ni won yoo gbe ero ti yoo fun awon osise ni anfaani lati le pe ipe ofe lori foonu si. Awon akoko ti won ba si wa ni enu ise ni kan ni won yoo ni anfaani lati lo ipe ori foonu ofe naa. Eleyii ti ijoba gbagbo wi pe yoo mu won jafafa lenu ise won gbogbo.

    “Bi o tile je wi pe iru eto yii ti wa nile tele ni ile ise ijoba ipinle Ogun, sugbon fun awon kan pato ni. Nibayii, bere lati odun 2016, gbogbo osise pata ni yoo beere si i je afaani ipe ofe naa ni yalayolo,” Adekunte fi kun oro re bee

    Yato si eleyii, o ni ijoba yoo tun se gbogbo akitiyan lati ri wi pe ilo ero ati ayelujara di irorun fun awon eniyan ti won gbe ni igberiko. Eleyii ti yoo fun won ni anfaani lati mo nipa awon eto ijoba ati lati je alabapin ninu isejoba awarawa to wa lode.

    Orisun: olayemioniroyin

  • Davido ti toro aforijin lowo Dele Momodu

    Davido ti toro aforijin lowo Dele Momodu fun awon oro alufansa to so si i lori wahala to wa laaarin re ati afesona re igba kan, Sophie Momodu to je aburo Dele Momodu,

  • E pade awon ore yin nibi

    Orisiirisii ona ati idi pataki ni awon eniyan fi n yan ore tuntun. Awon kan fe alajoso, awon kan fe alabaro, awon kan si n fe eni ti won yoo jo maa takuroso lasan. Eyiowu ko je, ore dun ti a ba fi ife otito ati ododo ba ara wa lopo.
    Die lara awon ti won fi nomba won ranse ni yii lati yan ore tuntun. Eyin naa le kan si won lori WHATSAPP pelu awon nomba isale yii.

    Debby 08163275837

    Motunrayo 08027975867

    Morufat 08060818444

    Topsy 08096603271

    Christy 08133247364

    Bashirat 08162746096

    Kola +27847142511

    Olalekan +353-871418831

    Joseph +22996092869

    Samson +2208020567889

    Abidemi +225 44656976

    Olayide +225 55539999

    Comfort 08094659214

    Yetunde 08062172889

    Folashayo 08133194463

    Abidemi +225 44656976

    Samson +2208020567889

    Olabisi 08023994620

    Olaitan 08036567503,08187631230

    Bisola 08136642246

    Dasola 07064899468

    Olayemi Oniroyin, emi naa an fe ore tuntun. Sugbon ore bi Dasuki lemi n fe, ore ti o gbe owo tabua fun mi ki n ma fi ba ise Oluwa lo. Ti o ba je wi pe eyin ni Dasuki ti mo n wa, Nomba temi naa ni yii : 0803 239 4964

  • Won ti se idajo Sharia fun alagbere obirin

    Obirin yii ni won ti se idajo Sharia fun ni orileede Indonesia latari wi pe, gbogbo igba lo n tele okunrin kan eleyii ti kii se oko re.
    Awon kan tile tun jeri wi pe, oseese ki maanu naa ti maa “kerewa” arabirin naa ni koro eleyii to tako ofin orileede Indonesia. Olayemi Oniroyin tun rigbo wi pe, oko arabirin naa kii fi gbogbo igba gbele eleyii lo fun obirin naa ni anfaani lati ma tele ale re kiri igboro nigbogbo igba. Oun ati okunrin, ale naa ni won jo dana iya fun niwaju mosalaasi Baiturrahim to wa Banda Aceh ni orileede Indonesia.


  • Kini ero yin nipa awon obirin to ga fiofio?

    Mo mo wi pe awon obirin maa n fe lati fe awon okunrin to ba ga. Sugbon mi o mo boya bakan naa lori pelu awon okunrin nipa fiferan awon obirin to ga fiofio. Se kii se wi pe giga obirin le mu awon okunrin maa sa fun?

  • Aregbesola sedaro Hon. Makinde to doloogbe

    Gomina ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola ti ranse ibanikedun si idile Hon Makinde Oladejo Samson to doloogbe lojo Aiku to koja yii, 27/12/15. Hon Makinde, omo egbe PDP, to je okan lara awon omo ile igbimo asofin ipinle Osun lo jade laye leni odun mejidinlaadota (48) leyin aisan ranpe.

    Iku Hon Makinde, eni ti n soju Aarin-gbungbun Ife nile igbimo asofin, ni gomina Aregbe se alaye re gege bi ajalu nla eleyii ti enikeni ko reti rara ni asiko yii. Ogbeni Aregbe ko sai tun ranse ibanikedun si egbe PDP ati awon eniyan ti Makinde n soju.

    “Bi o tile je wi pe ibanuje ni lati padanu odo bi Onarebu Makinde, sugbon ohun to daju niku; gbogbo wa la dagbada iku. Ki Olorun Oba mimo ba wa te si afefe rere,” Ogbeni Aregbe fi kun leta ibanikedun re bee.

  • Odun Iwude Ijesa: Gbogbo aye pejo saafin Owa Obokun

    Ese ko gbero lojo Satide to koja yii niluu Ilesa nibi ti tonile talejo ti gbe pejo lati sodun Iwude Ijesa laafin Owa Obokun Adimula ti ile Ijesa, Oba Gabriel Adekunle Aromolaran. Gege bi a se gbo, ayeye odun Iwude Ijesa yii lo maa n fun awon omo Ijesa lanfaani lati foju kan oba won laafin fun ikini odun eleyii ti ori ade naa yoo si ma sure fun gbogbo omilegbe ero ti won ba wa yo ayo odun naa.

    Eyi nikan ko, oba naa yoo tun ni anfaani lati se abewo si awon ibudo isembaye kaakiri tibu-toro ilu ilesa gege bi asiwaju asa ati ise ilu naa. Bakan naa ni awon oba to wa ni gbogbo igberiko pata ni Owa Obokun yoo yoju si eleyii to je okan pataki lara ayeye Iwude Ijesa.

    Ayeye to ti bere lati ojo Eti ni won fenu re kole lojo Abameta pelu orisiirisii ere idaraya bi ayo tita, ijo ati orin ibile, afihan awon ohun isembaye ati ojulowo aso ile Yoruba. Lara awon alejo pataki ti won pejo saafin Owa Obokun ni gomina ipinle Osun, ogbeni Aregbesola, ati oga olopaa ile Naijiria nigba kan ri, Ogbeni Mike Okiro.


    Orisu

  • Odun 2016 yoo dun bi oyin: E ku odun tuntun

    E ku odun tuntun. Odun ayo ati igbega ni yoo je fun gbogbo wa.  Ase.
    Odun 2016 yoo dun bi oyin. Bee ni. E je ki eleyii je ero yin. Kosi tun maa jeyo ninu awon oro enu yin nigba gbogbo. E ma je ki iriri ijakule ateyinwa je oun ti yoo maa wa lenu yin nigbogbo igba ti e ba n ro nipa ojo ola. Ohun to ti sele si yin tele tabi ohun ti n sele lowolowo ko ni ohunkohun se pelu ohun ti yoo pada sele. Sugbon ewu to wa nibe ni wi pe, e le se akoba fun igbe aye yin, nigba ti awon oro to n jade lenu yin ba lodi si aye yin.

    Oro enu lagbara, e je ka sora nipa bi a se n lo. Ki a ma ba lo oro enu lodi si igbe aye wa . Emi nigbagbo wi pe odun 2016 yoo dun fun mi ju 2015 lo. Ire ayo mi yoo de, awon eniyan yoo si ba mi yo.
    Ise mi ati okoowo mi yoo tun goke agba lodun 2016. Ati emi ati awon ololufe mi kari aye, iwaju la a ma lo. Oke oke si ni owo wa yoo maa wa nigba gbogbo. Ami

    E ku odun tuntun.

  • Ile itura alaja metalelogota (63) n jona bayii niluu Dubai

    Bi a se n mura lati wo inu odun tuntun lo, ni aisun odun taa wayii, ile itura alaja metalelogota (63) kan an jona lo lowolowo bayii ni ilu Dubai eleyii ti won ko ti kapa ina naa. Bi a se n ko iroyin yii lowolowo, aja bi ogun ti jo kanle. Bakan naa ni ina naa n tesiwaju si i.



  • Igbeyawo omo Adewale Ayuba fakiki

    Idunnu obi ni ki omo o yan ko si yanju. Omo taa to, to si duro gbeko ni i pada di omo gidi lowo awon obi re. Eyi  ni a le pe ni itan Tiwalade Ayuba lowo baba re.

    Ayo ohun idunnu nla lo je fun idile gbajugbaja olorin fuji, Adewale Ayuba, lojo Monde to koja yii, 28/12/15, nigba ti gbogbo won on sin omo won lo si ile oko pelu ariya to fakiki eleyii to sele ni agbegbe Lekki ni ilu Eko.

    Aimoye awon eniyan jankanjakan, awon olola ati gbajumo ni won pejo sibi ariya naa. Lara won ni Gbenga Adeyinka, eni to dari ayeye naa, Sule Alao Malaika, olorin to dana ijo fun awon alejo ojo naa. Lara awon gbajumo ojo naa tun ni Queen Salawa Abeni, Laide Bakare, KSB, Dayo Adeneye, Lepa Shandy, Tayo Odueke ati bee bee lo.