Category: Àṣà Oòduà
Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.
-
Aworan Yii Kiise Aroso Rara !
Bi Mi O Tie Mo Iyawo, Sugbon Mo Mo Oko Pelu Ise-owo Re, Isele Aburu Yi Waye Ni Ilu Ilogbo Ota, Ni Ipinle Ogun. Oko (Morufu Olasoji) Nfi Esun Agbere Kan Iyawo Re Kehinde Olasoji, Pelu Igbonara, Oko Lu Iyawo Re Pa. Ti A Ba Ba Alara Wi, Ki A Ba Alero Wi, Boya Iro Ni Oko Pamo Iyawo Tabi Otito, O Ye Olorun Oba, Iwo Oko Tabi Iyawo Ile, Ti O Si Tun Nwo Ita, Lo Jawo, Nitoripe Kosi Ere Nidi Ise Agbere, Bikose Iku, Besini Iwo Okunrin Alara Gbigbana, Mu Suuru, Ti O Bati Ka Iyawo Re Fun Ra Re Nidi Agbere, Fun Ni Iwo Ikosile Gegebi Bibeli Tiwi. Sebi Eri Ise Esu, Boya Lati Igbati Wonti Dele Aye, Won Ko Jade Ninu Iwe-iroyin Ri, O Wa Je Igbati Won Fi Aye Sile Fesu. Eledumare Ti O Nba Eda Gberu, Yio Bawon Toju Awon Omo Won Meteta, Ogun kogun Koni Tule Wa ka Tabi Dale Wa Ru , Awon Omo Wa Koni Di Omo Orukan Ojiji
Ase!
-
Odu Ifa: Obara eguntan
Obara eguntan
I I
I II
I II
II IIIfa so wipe ki alaniyan yi ni aforiti gidigidi lori ohun ti o difa si yi.
Obara eguntan, egun kun, ajapa-nlele
A difa fun agunfon-abi-osulolo
Nijo ti I nbe l’oko egba gun
Nijo ti I n be l’oko egba gbon
Ebo na pe ko ma se
Riru ebo
Titu ope
Aseyinwa, aseyinbo
Agunfon-abi-osulolo wa do-olokun
O wa donide
O wa da-alala ile agunfon-abi-osulolo
Iwure
Ire gbogbo ni Tomini…
Owo alakedun ki se ‘gi.. -
Odu Ifa: Obara gbedipon
Obara gbedipon
I I
II II
II II
I II
Eni odu ifa yi ba wa fun ifa kilo pe ko kiyesi awon iwa owo re gidigidiM’omode ole, maa m’agba ole, agba ole soro mu l’oko
Adifa fun obara abufun idi
Nijo ti won sawo lo sile olofin
Ebo na pe kan ma se
Riru ebo
Titu oope
Nita ile olofin niyewu igboje pamo si wa
Awon isu wo obara ati idi loju
Niwon ba ji nibe
Nigbati won se awon kan won yin okan ninu eru olofin ri won
Eru wi fun olofin
Olofin ni ayafi kiwon bura nigbati won ni iro ni eru pamo awon
Obara lo ko bo ode
Oni ti o je pe owo owun mejeji lowun fi gbe isu ti olofin wa niki ogun pa wun.
Idi: idi ni ti o ba je pe ese owun mejeji te iyewu ti onje wa niki ogun pa wun.
Ogun o pa kankan ninu won toripe
Obara lo gbe idi pon
Ese idi o kan ile iyewu ibi ti onje wa.
Obara siko logbe isu laka
Iwure
Airidi Okun
Airidi Osa
Eledumare konije ki asiri temi ti re tu nigbakookan Aase
Ire o!~Ifalana Awogbemi
-
Check out Oriki and songs book on Osun, Olokun
Oriki and songs book on Osun,Olokun,Egbe,Oya and Sango on songs and chant by Iyalorisa Oyelola Elebuibon Package by Ifayemisi Elebuibon. The book is in Yoruba with English translations. Each purchase qualify for one person 1hr free tutor class with Ifayemisi Elebuibon.

-
Nje Iwo Tiri Iru Igbeyawo Eleyi Ri ?
Ni ile aye tabi kani ni Nigeria wa yi orisirisi lama ma ri. Ni Nigeria wa yi na loti sele, O’ku osu meji ti awon toko taya yi dajo Igbeyawo won ni Oko Iyawo wan ni atimole awon olopa ni ilu Oyinbo, ni iyawo bani awon ti dajo Igbeyawo awon o si leyi ojo na pada, pe sis niohun ma se Igbeyawo ohun,won si se Igbeyawo na osi larinrin pelo (pic) oko iyawo,Hunnnnmm orisirisi lohun sele laye.


