Home / Àṣà Oòduà / Odu Ifa: Obara gbedipon

Odu Ifa: Obara gbedipon

Obara gbedipon
I I
II II
II II
I II
Eni odu ifa yi ba wa fun ifa kilo pe ko kiyesi awon iwa owo re gidigidi

M’omode ole, maa m’agba ole, agba ole soro mu l’oko
Adifa fun obara abufun idi
Nijo ti won sawo lo sile olofin
Ebo na pe kan ma se
Riru ebo
Titu oope
Nita ile olofin niyewu igboje pamo si wa
Awon isu wo obara ati idi loju
Niwon ba ji nibe
Nigbati won se awon kan won yin okan ninu eru olofin ri won
Eru wi fun olofin
Olofin ni ayafi kiwon bura nigbati won ni iro ni eru pamo awon
Obara lo ko bo ode
Oni ti o je pe owo owun mejeji lowun fi gbe isu ti olofin wa niki ogun pa wun.
Idi: idi ni ti o ba je pe ese owun mejeji te iyewu ti onje wa niki ogun pa wun.
Ogun o pa kankan ninu won toripe
Obara lo gbe idi pon
Ese idi o kan ile iyewu ibi ti onje wa.
Obara siko logbe isu laka
Iwure
Airidi Okun
Airidi Osa
Eledumare konije ki asiri temi ti re tu nigbakookan Aase
Ire o!

 

~Ifalana Awogbemi

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Todo sobre casino en vivo

Casino en vivo: La experiencia de juego en tiempo real ¿Qué es un casino en vivo? El concepto de casino en vivo ha revolucionado la manera en que interactuamos con los juegos de azar en línea. A diferencia de los casinos tradicionales, donde la experiencia se desarrolla en un lugar físico, los casinos en vivo permiten a los jugadores disfrutar de su juego favorito desde la comodidad de su hogar mientras interactúan con dealers reales a través de streaming en ...