Category: Àṣà Oòduà

Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.

  • “Oserekurin Ti Mo Fe Lati Je Ete Re Ni…”: Tani Okunrin Ti Bimbo Thomas Feran Lati Kiisi?


    Ti a ba n so nipa ise tiata ile Naijeria, Bimbo Thomas ti kuro ni ojewewe ti won nawo juwe re. Lara awon fiimu to ti kopa ribiribi ni eleyii ti Funke Akindele gbe jade ti won pe akole re ni OMO GHETTO, nibi to ti kopa Nikky

     

    Gege bi alaye ti Bimbo se fun awon oniroyin iwe iroyin Vanguard ti ile Nigeria, o ni fiimu OMO GHETTO fe e je fiimu to gbo oun ju lo nitori eda-itan ti oun kopa re jina si iru igbe aye ti oun gbe loju aye.
    Ninu fiimu yii lati ri Nikky nibi to ti n faraki, to si n je ko maa ye won pe oun ni Iyanlaya awon omo ghetto. Yato si eyi, omobirin naa n pago mole, won si fa surutu kiri igboro pelu awon akegbe re ninu ere naa.
    Lara ohun to tun jeyo ninu iforowero Bimbo Thomas ati awon oniroyin ni ile itaja re, Bimbally, nibi to ti n ta awon orisirisi oti waini to gbamuse. Ninu ero omobirin naa ni lati ni eka kaakiri; o si tun se afikun ife re lati maa ta awon aso oge pelu.
      
    Omobirin to kawe gboye ni Ifafiti ijoba apapo to wa niluu Eko ko sai menu ba bo se bere ise tiata.
    O se lalaye wi pe Tayo Odueke ti gbogbo eniyan mo si Sikiratu Sindodo, eni to ti bere ise tiata saaju re, lo gba a niyanju lati dara po mo ise tiata nigba to ri ipa re nidi ise akanse ti won se ni ile iwe. ( Ise ona alatinuda, Creative Art, ni Bimbo Thomas ka gboye akoko ni Ile iwe Unilag).
    Ohun ti Bimbo so nipa Sikiratu Sindodo ni yii:
    “O gba mi nimoran wi pe ki n maa bo ninu ise fiimu niwon igba to je wi pe mo ni gbogbo amuye bi karisima ati awon nnkan mi-in”
    Ohun to dun mi ju ti oniroyin Vanguard ko beere lowo Bimbo ni nnkan ti osere naa ni lokan pelu gbolohun to so gbeyin: “… awon nnkan mi-in“.
    Niwon igba ti eleyii ko ti jeyo ninu iforowero won, ninu ero mi, o ni lati je ewa ti omobirin naa ni lohun to o n soro o ba. Awon Yoruba ni funfun niyi ehin, Sunny Ade si fi tie kun wi pe: “Omu sikisiki niyi obirin”. Atiwaju ateyin Bimbo ko ja kereemi ti eniyan le foju pare.
     
    Bimbo dudu, dudu ohun o jona, didan nii dan bi korosin.
    Lopin ohun gbogbo, Bimbo Thomas ko sai menu ba oserekunrin to je dodo re julo lagbo amuludun. John Dumelo omo ilu Ghana ni Bimbo ni oun gba dun swaga re ju lo. O ni didun inu oun ni yoo si je ti ise ba jo pa awon po lori itage, ti awon si ni anfaani lati jete,kiisi tabi ki won jijo pon enu ara won la.
  • Milionu Mefa Ti Gbe Omo Naijeria Wonu Ese-Mefa: Ojukokoro Ti Pa Chukwudi!


    Chukwudi, omo odun mejidinlogbon (28)ti padanu emi re leyin igba to ta kidinrin re ni milionu mefa owo naira (N6million)niluu Malaysia

    Chukwudi la gbo wi pe o tirafu lati ilu re, Owerri, ipinle Imo lati lo siluu Malaysia nibi to ti lo ta kidirin re fun okan lara awon olowo ilu naa ti won niilo re fun ilera ti won.

    Gege bi iwadii awon oniroyin lati owo awon omo Naijeria to wa niluu Malaysia. Won ni Chukwudi ko ni eni akoko ti yoo wa si ilu Malaysia lati wa ta kidinrin re, aimoye awon omo Naija ni won se e.

    O ni pupo awon omo Naijeria feran lati wa si Malaysia lati wa ta kidinrin won latari owo goboi ti won maa san fun won eleyii ti o mu won di olowo ojiji leyin ti won ba fi kidirin won sile tan.

    Chukwudi ti ku bayii, milionu mefa ko si ni ba wonu ese-mefa lo. Ta a wa ni yoo na milionu mefa leyin ti Chukwudi ti wonu ese-mefa lo?

     

    Iroyin èdè oyinbo (English Version)

  • Iyalenu: Foto Ohun To N Sele Ni Ibudo Awon Ti B’Haram So Di Alailara, Alaini Nnkankan Niyii


    Ibudo awon eniyan ti Boko Haram So di alailara ati alainile lori latari ijamba ati ikolu Boko Haram ni yii ni Maiduguri to wa ni Ipinle Borno.

    E le biliifu wi pe sobiri ti won fi n re ile ni won fi n bu ounje fun awon omo eniyan.

    Ki Edumare ba wa mu fitinati kuro lorileede Naijeria.
    Ase

  • Abiyamo Fi Omije Gbe Omo Re Sinu Koto


    Ipokipo ti eda ba wa laye, e pe ko maa dupe. Ibikibi ti ori ba da ni si ka fi ope fun Oluwa oba nitori awon kan ko tile ni ida kan ninu ogorun anfaani ti a ni.  Ebi n pa awon kan, kosi si ounje fun won rara. Ogun, wahala, rukerudo ati aibale okan ti so awon ilu kan sinu adawon ayeraye.   Foto yii lo lalewu lori ikanni Facebook, eleyii to n se afihan omobirin alaini, alailenikan, eni ti ko ri ounje je rara, nibi to ti n sin omo re sinu koto.

    Orisun

  • Won Fi Leta Pe Pasuma Pe Ko Wa Korin Ni Soosi Baba G.O Adegboye

    Abi foto Buroda Alabi Pasuma ko ni mo n wo yii ni? Ko ma si eni ti Olorun ko le fi owo to lokan sa o. Burudo Pasuma, Orobokibo Creator, Oga Nla 1, Ijaya of Fuji, Oluwa yoo ma so agbara yin dotun oo.

  • Sayewo Omo Ita, Jaguda Ti Buhari Fi Se Oludamora Nipa Oro To N Lo Nile Igbimo Asofin


    Honorebu Suleiman A. Kawu ni yii, okan ninu awon omo ile igbimo asofin ti n fo iganna nigba rogbodiyan to waye nile igbimo asofin ni akoko ti Goodluck Jonathan wa lori oye gege bi Aare ile Nigeria olominira.

    Maanu yii kan naa wa lara awon ti Aare Muhammadu Buhari ti yan bayii gege bi oludamoran nipa awon oro to n lo nile igbimo asoju sofin ile Nigeria.

    Pelu bi oko Aisha se n pariwo wi pe awon eniyan gidi, omoluabi oloselu ati olooto ni awon eniyan ti oun fe ninu isejoba oun, nje awa le pe eniyan ti n fo iganna gege bi omoluabi alaponle bi?

     

    Orisun

  • Oko Toyin Aimakhu, Adeniyi Johnson Ti Dale Ife

    Laipe yii ni omobirin naa yo oruko oko re kuro ninu oruko re. Bakan naa ni awon eniyan tun kiyesi wi pe awon foto oko re to wa lori ikanni instagram re lo ti fe e gbonyo tan.

    Adeniyi Johnson ti n be iyawo re bayii, o ni oun loun jebi ohun to n fa wahala laaarin awon mejeeji. E le ka alaye re nibi: http://www.facebook.com/photo.php?fbid=881199908632560&set=gm.1037407549643887&type=1

    Awon kan ni oko re se asemase kan ni, isele naa si bi Alakada ninu pupo ju.

    Awon eniyan kan ti n be Toyin wi pe ko maa binu, nigba ti awon kan n naka abuko si oko re ati gbogbo okunrin gege bi olojukokoro, to je wi pe gbogbo ejo ni jije lodo won.

    E tun le ka ohun ti awon ololufe Toyin n so nibi: http://www.facebook.com/photo.php?fbid=881200005299217&set=gm.1037407549643887&type=1

  • “Kini Idi Ti Fasola Fi Wu Ewu Funfun Lori Ko To Kuro Nijoba?” Ninu Iwe Iroyin Owuro Ni Idahun Naa Wa


    Akole gbagada to jade lati inu iwe Iroyin Owuro ti ose yii lo n so nipa ohun to faa ti Fasola fi wu ewu lori ko to pari ijoba re nigba ti awon akegbe re bi Mimiko ati Ajimobi n dan gbirin.

    Awon akole mii to tun wa loju ewe akoko iwe Iroyin Owuro niyii:

    *Omoge Mejilelaadota ti ko mokunrin ri se idije lEkoo

    * Idi ti emi ati Tinubu fi daru- Gbenga Daniel

    *Ni Akure, awon Omoota seruba Odunlade Adekola.

    Ati awon iroyin mii to gbamuse.

    E gbiyanju kee ra Iroyin Owuro, ogorun naira pere ni.

     

    olayemioniroyin

  • Awon Omo Ologun Ile Nigeria Fi Emi Awon Omo Boko Haram Ti Won Woso Ologun Sorun Sofo Bi Omi Efo


    Asiri awon omo Boko Haram kan ti won wo aso ologun sorun sise buburu owo won ti tu ni apa ila oorun-arewa ile Nigeria.  Awon omo Ologun Nigeria yosi won ni ibuba won ti won go si, won si se won sibalasibolo. Oku awon omo Boko Haram si lefo sori ile bi oku aja.

    Olayemioniroyin

  • Adajo Ti Dajo Iku Fun Omobirin To Gbe Ogun-Oloro Pamo Si Oju-Ara Re Ni Ilu Thailand


    Ile ejo ti dajo iku fun Chonmanee Laphathanawat, eni ogbon (30) odun ni ilu Thailand pelu esun gbigbe ogun oloro cocaine ni orileede Thailand.

    Omobirin yii ni won mu pelu bo se sin ogun-oloro ti won ti ro sinu kapusu (capsules) bi aadorin (70) si oju-ara ati inu iho idi re.

    Ana, 27-08-2015, ni won da ejo omobirin naa.

    Ki Oluwa oba dari gbogbo ese re jin-in.

    E sora fun ogun-oloro. Ko Dara!