Category: Àṣà Oòduà

Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.

  • Ilé ejó gíga jù dá asòfin ìpínlè Taraba dúró, tí orúko rè ńjé Sani Danladi

    Won pàse fun kí ó dá owó osù àti àláwánsì tí ó gbà.

    Ilé ejó gíga jù ti pàse fún asòfin tí ó ń sojú ilé asòfin àgbà àríwá ti ìpínlè Taraba sani Abubakar Danladi láti fi ipò náà sílè ní kíákíá kí ò sì dá gbogbo owó àláwánsì tí ó gbà fún Àádòrún  ojó padà.

    Nígbà tí ó sì wà ní ipò, ilé ejó gíga ti kéde Shuaibu Lau gégé bí asòfin tí ó ń sojú ilé asòfin àgbà ti àríwá Taraba. Àse náà kún fún ìdájó tí ó wà nínú fáìlì ilé-ejó kò témi lórùn láti owó Shuaibu Lau, ó ta ko ìpinnu ilé-ejó kò té mi lórùn nígbà tí ó jáwé olúborí tí won sì gbe fún elòmíràn ní ònà tí kò tó.

    Ile ejó tún pàse fún ètò ìdìbò (INEC) láti se ìwé-èrí tuntun fún ìpadàbò Lau.

    Ilé-ejó gíga jù tó ri to ìpinnu àwon omo egbé tóronú márùn-ún tí ó wáyé wípé “olugbèjà ara rè ní ètó láti kópa gégé bi àwon tó kùn náà se létòó ní ìbèrè ó rò wípé wón yan òun je ni .ó ní ètó láti lo sí ilé-ejó .

    Eni tí won fi ró pò rè ní ìbèrè pèpè ti ìbò rè se òfò nígbà tí ó jé wípé olugbèjà ara rè ló gbégbá orókè nínú ìdìbò náà. Ohun tí ó kùn ni wípé kí won kéde wípé olugbèjà ara rè ló gbégbá orókè ní ìbèrè pèpè.. …

    Continue after the page break for English translation.

  • Àwon Agbófinró ìpínlè Èkó so ònà tuntun tí àwon gbómogbómo ńgbà jínigbe. 

    Àwon Agbófinró ìpínlè Èkó so ònà tuntun míràn tí àwon gbómogbómo ńgbà jínigbe. Ní ìsàlè ni òrò tí agbenuso àwon Agbófinró ìpínlè Èkó, SP Dolapo Badmos so.
    “E jò ó tí enikéni bá fi káàdì ìpè ráńsé sí yín tí eni na sì pè padà wípé àsìse ni pé kí E fi ráńsé padà sí àwon. Tí o bá fi ráńsé padà, wón sì máa pè yín láti bèèrè sàpéjùwé yín wípé àwon fé dúpé lówó yín fún ohun tí e se àti wípé àwon fé gbàdúrà fún yín E má dá won lóhùn E má sàpéjùwé ara yín ooo. Ònà tuntun tí àwon gbómogbómo ńgbà láti gbé ènìyàn nìkan.
    E jò ó ejé kí á máa fura kí á sì sóra nínú gbogbo ohun tí a ń se lójoómó kí á ma ba bó sòwó….

     

    Continue after the page break for English Translation.

  • Àwon ológun yín ìbon lu omokùnrin odún márùn-ún ní Kaduna nígbà tí won ń ké ìrora won ní rowérosè ..

    Gégé bí omo oòduà rere se so, omokùnrin odún márùn-ún tí orúko rè ńjé Hussein Mustapha ni àwon ológun yin ìbon lu nígbà tí won ń ké ìrora (rally) ní Kaduna láti fi àmì sí Qusday ní àgbáyé láti gba Zakzaky àti Palestine kalè (papàájùlo lówó ìkolù àwon Israel

    English Translation!
    Continue after the page break

  • Àwòrán; Toke Makinwa  jáde ní àrà òtò ní orílè èdè South Africa láti pàdé SA OAP àti àwon t’ókun lórí àjò SA tí ó ń bò lónà. 

    Toke Makinwa sèsè dé sí orílè èdè South Africa láìpé yí gégé bí ó se ń rìn káàkiri àgbáyé láti di gbajúgbajà ònkòwé.  Ìmúra rè yanilénu nígbà tí ó wo aso aláwò   pupa férééfé (pink Gert Johan) àti bàtà tí a mò sí Calvin Klein isé owó Harvellastyles ni, ó wà lójú ònà tí ó ńlo sí TouchHD fún ìfi-òrò-wá ni -lénu -wò lórí redio. Nígbà tí ó jáde pèlú oba ilé-isé redio Tbo Touch.
    Toke ti wà ní ìpele tí ó kéyìn ní ìrìnàjò àgbáyé látàrí dídi ògbó-n-tarìgì ònkòwé tí ó ń tèlé àwon ìpele tó tó ní United State, Ghana àti United Kingdom.
    Yó ò gba tí to wó bo ìwé àti kíka ìwé ní ojó Àbáméta…..

  • Gómìnà Nyesom Wike dá òkan lára àwon Konmisôna rè dúró. 

    Gómìnà ìjoba ìpínlè River, Nyesom Wike ní òwúrò yí dá Konmisôna isé dúró ní ìpínlè rè tí orúko rè ńjé Bathuel Harrison (àwòrán eni tí ó wo jákèètì).  Nínú òrò tí olùrànlówó pàtàkì rè so lórí ìtànná ohun Ìgbéròyìn jáde (Electronic media), Simeon Nwakaudu. Wike so wípé ìdádúró náà esèkesè ni; ó so fún Harrison kí ó gbé ipò fún Akòwé pípé nínú àkóso náà. Kò sí ìdí kan pàtàkì tí won fi lé Konmisônna na níbi isé….

    English Translation
    Continue after the page break

  • Díè nínú ìsesí láti òdò Dino Melaye lórí ìròyìn èrò rè tí a se ìrántí láti ìgbìmò asòfin àgbà. 

    Ní àná, ìgbìmò tí ó ń darí ètò ìdìbò (INEC) gba àpò méfà tí ó kún fún ìbowólù àwon tí ó tó láti dìbò ní agbègbè Eokun ìwò oòrùn ní ilè Kogi, tí ó ń bèèrè fún ìrántí Dino Maleye láti ilé ìgbìmò asòfin àgbà. Nígbà tí ìròyìn náà wá, Dino gbe lo sí orí èro ayélujàra rè (facebook) láti so wípé nkankan kò le se òun àti wípé àwon tí ó gbé ìgbésè náà setán láti s’èwòn .
    Ní òwúrò yí, ó tún gbe lo sí èro ayára-bí-àsá (twitter) láti wo ìsesí míràn lórí rè….

    English Translation
    Continue after te page break

  • Ipò Burúkú Ti Ilé-ìwòsàn Ńlá Ní Warri Ní Ìjoba Ìpínlè  Delta Wà. 

    Èyí ni ìròyìn ipò tí ilé-ìwòsàn ńlá wà ní warri ní ìjoba ìpínlè Delta wà lówólówó . Àwòrán na jé pínpín sí orí èro ayélujàra (facebook)

    English Version
    Continue after the page break
  • Ilé Tí Won Ń Kó Lówó Wó Ní Ilorin. 

    Èrù ti ń ba àwon òpòlopò ènìyàn bóyá àwon ènìyàn kú sí inú ilé tí won ń kó lówó ní òpópónà Stella, Tanke ,Ilorin ,ní ìjoba ìpínlè Kwara tí ó wó ní òsán yí.
    English version
    Continue after the page break bellow.
  • Àwon fúlàní darandaran kolu àwon àgbè oníresì (Rice farmer) ní ìjoba ìpínlè Benue.

      –Tí ó sì dá àpá sí  won l’ára.
    Nígbà tí a wà lénu síse àtakò àláfíà sí ilé ìjoba Makurdi lóòní láti jé kí ìjoba gbárùkù láti jé kí won f’owó sí owó ntanràn jíjeko (Anti grazing bill) sínú òfin àti láti fajúro sí orísirísi  àbùkù /òròìwòye ti àwon Miyetti Allah Cattle Breader’s Association (MACBAN) ,wón tún pa àwon àgbè oníresì tí kò mo nkankan lára ní ìsodá bírìjì ilé-ìfowópamó, Àríwá (north bank).
    Nígbà tí won ń gbin ìresì lówó ni àwon darandaran sí wo inú oko won tí àwon Eran won sì ń je oko won. Èsì ni è ń wò ní ìsàlè yìí bí won se gbé àwon àgbè tí ó se l’ése lo  sí ilé-ìwòsàn ifáfitì ìjoba ìpínlè Benue (Benue state university Teaching Hospital).Àwon ènìyàn wònyí (fúlàní) tún fi ara won hàn bí ó tilè jé wípé òfin ti báwa bu owó lù ú ìwé ntanràn jekojeko Anti grazing bill. Àwon fúlàní darandaran tún ń da àwon ònilè àti àwon tí ó ń fé àláfíà àwon ènìyàn ìjoba ìpínlè Benue láànú….

    Continue after the page break for the English translation.
  • Kcee tú àsírí pé òhun ni olórin àkókò ní ìròlé èdè Nàìjíríà tí ó kókó lo okò bògìnì tí a mò sí Rolls-Royce phantom nínú fídío Orin rè. 

    Gbajúgbajà olórin,  Kcee o ní ìràwò márùn-ùn. Nínú Orin tí ó ti se jé kí á rí àsírí rè gégé bí àsáájú tí ó kókó lo okò bògìnì “Rolls-Royce   ní ilé-isé olórin ní orílè èdè Nàìjíríà. Òun ni ó jé òsèré àkókò tí ó kókó lo irú rè kan ní ibi fídío Orin rè, Shokori Bobo.
    Àrídájú yí wá nígbà tí a  fi òrò wa lénu wò ; ó so wípé; “Èmi ni òsèré àkókò ní orílè èdè Nàìjíríà láti lo Roll-Royce phantom nínú fídío Orin mi.
    E lo wo Shokori Bobo. Ní àkókó yan ni èmi pèlú Phresh se fídío náà. Enikéni kò tí lo Roll-Royce nígbà yan. Ókéré nínú gbogbo èyí tí mo le rántí, òpòlopò ló ti ń wí tenu won nípa rè.Tí àwon kan so wípé D’banj ko Mr. Endowed Remix pèlú oko bògìnì yí nígbà tí ó wà pèlú Mo’Hits.
     
    Kí l’erò, nítòótó? Tani àsáájú tí ó kókó lo okò bògìnì tí a mò sí Rolls-Royce ni ibi fídío Orin rè ní orílè èdè Nàìjíríà? Kcee tí ó gbé Orin rè Shokori Bobo jáde ní 2008 àbi D’banj nínú Orin rè Mr. Endowed remix ni 2011? Ó hàn gàdàgbà lóòtó? Sùgbón Ná.
    Ejé kí á gba èrò yín nípa òrò náà…


    Continue after the page break for English translation.